Ìtẹ́ Aláàfin kò wà fún títà, màá bá Oyomesi tó bá gba rìbá lórí iyansipo Alaafin ṣe ẹjọ́ – Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde
Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti sọ pe itẹ Alaafin ilu Oyo kii ṣe fun tita, nitori naa gbogbo awọn Oyomesi to ba lọwọ ninu gbigba riba lati yan ọmọ oye ko ni lọ lai foju wina ofin.
Makinde lo sọ ọrọ yii lọjọ Aje lasiko to n gbe ọpa aṣẹ fun Alaafin tuntun, Oba Abimbola Akeem Owoade nile ijọba to wa niluu Ibadan.
O ni ọjọ Aiku ni igba akọkọ ti oun kọkọ pade ọmọ oye naa, bẹẹ ni awọn mejeji ko ri ara wọn tabi sọrọ.
Gomina naa sọ pe oun ṣe eyii lọna ati maṣe fi si ẹgbẹ kan tabi ṣatilẹyin fun eyikeyi ninu awọn ọmọ oye to n du ipo Alaafin.
Bo tilẹ jẹ pe o ni ijọba oun koju iṣoro diẹ pẹlu awọn oriade, papaa niluu Ibadan, ọrọ naa ti yanju bayii.
O ni "Ọdun 2022 ni ipo Alaafin ṣofo, a si n mura eto idibo nigba naa, awọn eeyan wa sọ fun mi pe mo gbọdọ buwọlu ẹni ti yoo di Alaafin, bi bẹẹ kọ, awọn eeyan ilu Oyo ko ni dibo fun mi.
"Mo wa da wọn lohun pe, mi o bikita nipa ibo awọn eeyan fun mi bi ko ṣe nipa ṣiṣe ohun to tọ fun ilu Oyo, awọn eeyan Oyo si dibo fun mi daadaa, mo si gbagbọ pe wọn ko ni jawọ atilẹyin wọn fun mi.
"Ẹ jẹ ki n sare sọ ni ṣoki nipa awọn to fẹ doju aṣa wa bolẹ ni Oyo, ijọba ko ni sinmi.
A o pe wọn lẹjọ.
"Wọn yoo foju wina ofin lori owo ti won ti gba ayafi ti wọn ba pada lọ ba kabiesi fun idariji.
"Ti Kabiesi ba forijin wọn, emi naa yoo darijin wọn."
Makinde sọ siwaju si pe ọsẹ mẹrin si asiko yii ni ayẹyẹ iwuye Alaafin yoo waye niluu Oyo, ayẹyẹ naa yoo si larinrin, aye a gbọ, ọrun yoo si mọ.
Nigba to n fesi, Oba Owoade ṣeleri lati fọwọsowọpọ pẹlu ijọba ipinlẹ Oyo fun ilọsiwaju ipinlẹ naa.
Ohun tó wu Gómìnà ló ń ṣe lórí ìyánsípò Aláàfin, ọ̀rọ̀ ti wà n'ílé ẹjọ́ - Basorun Oyo

Oríṣun àwòrán, Others
Basorun ilu Oyo, Oloye Yusuf Akinade Ayoola ti sọrọ lori igbesẹ Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde, to kede Ọmọọba Akeem Abimbola Owoade gẹgẹ bii Alaafin tuntun.
Bakan naa, ni owurọ ọjọ Aje, Gomina Makinde gbe ọpa asẹ ati iwe ẹri fun Alaafin tuntun naa.
Igbesẹ yii lo waye ni ọọfisi Gomina ipinlẹ Oyo ni ọjọ Aje, ọjọ kẹtala oṣu kinni ọdun 2025.
Bẹẹ ba gbagbe, ọsẹ to kọja ni Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde kede Ọmọọba Akeem Abimbola Owoade gẹgẹ bii alaafin tuntun fun ilu Oyo.
Oniruuru awuyewuye si lo ti suyọ lati igba ti ikede Alaafin tuntun naa ti waye, ti ọpọ iroyin si gbalẹ lori ayelujara pe awọn afọbajẹ nilu Oyo lo n fapa janu lori iyansipo Alaafin naa.
Saaju ni awọn afọbajẹ ilu Oyo ti pe ijọba ipinlẹ lẹjọ lati tako yiyan Ọmọọba Akeem Abimbola Owoade gẹgé bii alaafin tuntun.
Eyi lo mu ki BBC Yoruba kan si Basọrun Ayoola lati mọ iha ti Oyomesi kọ si iyansipo Alaafin naa, ti aga rẹ ti sofo lati ọdun meji ati aabọ sẹyin.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Oloye Ayoola ni ohun to wu Gomina ipinlẹ Oyo lo n se.
Basorun Oyo ni " A kọ mọ nkankan nipa rẹ, wọn fun ni ọpa aṣẹ tabi wọn ko fun ni ọpa aṣẹ.
"Ohun to wu ijọba lo n se.
"Ọrọ kankan ko se sọ lori rẹ bayii nitori ọrọ to jẹ mọ ọrọ lọbalọba yii ti wa ni ile ẹjọ.
"Ile ẹjọ ni yoo se ohun to tọ.
"Emi ko ni nnkan ti mo le ṣe bayii, n ko le ni o dun mọ mi, ko si ba mi ni inu jẹ nigba ti n ko ni jẹ alaafin.
"Ọrọ wa ni ile ẹjọ."
Ta a ni Baṣọrun ilu Oyo?
Lọwọlọwọ, Oloye Yusuf Akinade Ayoola, ni Baṣọrun ilu Oyo.
Oun si ni oludari ni aafin Oyo, titi wọn fi yan Alaafin tuntun.
O ti lo ọdun mẹrinla gẹgẹ bi Baṣọrun, eyi to tumọ si pe Alaafin Adeyemi lo yan an sipo.
Gẹgẹ bi Agbaakin ti ilu Oyo, Oloye Asimiyu Atanda ṣe sọ, Baṣọrun ni igbakeji Alaafin ko to o waja.
Oye naa si jẹ oye idile.
Bakan naa lo sọ pe Baṣọrun lo maa n dari ilana ti wọn yoo fi yan Alaafin tuntun ti akoko ba to.
Ṣugbọn ko le da yan-an lai si idasi awọn ọmọ ẹgbẹ Oyomesi yokù.
Awọn to wa ninu igbimọ Oyomesi ni: Baṣọrun, Agbaakin, Samu, Alapinni, Lagunna, ati Akiniku.
Seyi Makinde gbé ọ̀pá àṣẹ fún Aláàfin tuntun

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti gbe ọpa asẹ fun Alaafin tuntun, Ọmọọba Akeem Abimbola Owoade.
Owurọ ọjọ Aje ni Ọmọọba Abimbola gba ọpa asẹ nile gomina to wa ni Agodi nilu Ibadan eyi to mu ko di Alaafin kẹrindinlogoji ti yoo jẹ nilu Oyo.
Wọọrọwọ ni wọn seto igbọpa asẹ naa nibi ti awọn eekanlu, ọba alaye atawọn agbaagba miran peju si.

"Mo jẹjẹ lati mu idagbasoke ilu ati eto idẹrun araalu lọkunkundun"
Nigba to n gbe ọpa asẹ naa fun Alaafin Owoade, Gomina Seyi Makinde se apejuwe Alaafin tuntun gẹgẹ bii asaaju to mu asa ati itan ajogunba Oyo ni ọkunkun.
Gomina ni ipo Alaafin kii se ipo yẹpẹrẹ, ti o si da oun loju pe Alaafin tuntun naa yoo maa dari ilu naa pẹlu ọgbọn, iwa rere, ti yoo si tun mu irẹpọ ilu Oyo lọkunkundun.
Nigba to n fesi, Alaafin tuntun naa, wa fi ẹmi imoore rẹ si awọn eeyan ilu Oyo, to si jẹjẹ lati mu idagbasoke ilu ati eto idẹrun araalu lọkunkundun.
Oyomesi, ẹ lọ jọ̀wọ́ ara yín fún ìwádìí EFCC lórí ẹ̀sùn gbígba N15m lọ́wọ́ ọmọ oyè sípò Aláàfin – Iléẹjọ́

Kangun kangun kangun, ọrọ ti kangun sibi kan fun awọn igbimọ afọbajẹ nilu Oyo, taa mọ si Oyomesi.
Idi ni pe ile ẹjọ giga tijọba apapọ to wa nilu Ibadan ti pasẹ pe ki ajọ to n tanna wadi ẹsun iwa ibajẹ nidii owona, EFCC, lọ tanna wadi wọn.
Adajọ Ekerete Akpan lasiko to n gbe idajọ rẹ kalẹ, wa wọgile ẹjọ ti Oloye marun lara awọn Oyomesi naa pe wipe ki ile ẹjọ da ajọ EFCC lẹkun lati maa tanna wadi awọn.
Saaju ni ajọ EFCC ti ransẹ pe awọn Oyomesi naa lati wa sọ tẹnu wọn lori ẹsun ti wọn fi kan wọn pe wọn gba millionu mẹẹdogun Naira lọwọ ọkan lara awọn ọmọ oye to n du ipo Alaafin, Lukman Gbadegesin.
"Atanda ati Oyewale jẹwọ pe awọn afọbajẹ yan Lukman Gbadegesin bii Alaafin ti yoo gori itẹ lẹyin ti awọn gba miliọnu mẹẹdogun Naira lọwọ rẹ"
Nigba to n salaye bi igbesẹ naa se lọ, agbẹjọro fun ajọ EFCC, S.M Galadanchi sọ fun ile ẹjọ giga naa pe meji lara awọn Oloye Oyomesi naa, Lamidi Oyewale ati Asimiyu Atanda ti jẹwọ fun awọn pe Ọmọọba Gbadegesin fun awọn ni miliọnu mẹẹdogun Naira lasiko ti wọn n sepo lati yan Alaafin.
EFCC fikun pe Atanda ati Oyewale jẹwọ pe awọn afọbajẹ yan Lukman Gbadegesin bii Alaafin ti yoo gori itẹ lẹyin ti awọn gba owo naa.
Lẹyin eyi ni awọn Oyomesi gba ile ẹjọ pe ko da ajọ EFCC lẹkun ko dẹkun didun mahuru-mahuru mọ awọn mọ.
Sugbọn adajọ Akpan ni ile ẹjọ ko le da ajọ EFCC lọwọkọ lati se isẹ rẹ ti ofin gbe le lọwọ eyi to ni se pẹlu titan ina wadi awọn ẹsun ajẹbanu nidiii owona.
"Igbesẹ EFCC lati wadi ẹsun gbigba owo ẹyin toto miliọnu mẹẹdogun ti wọn fi kan Oyomesi ko tumọ si pe wọn n dunkoko mọ wọn"
"Igbesẹ ajọ EFCC lati tanna wadi ẹsun gbigba owo ẹyin toto miliọnu mẹẹdogun ti wọn fi kan awọn Oyomesi naa ko tumọ si pe wọn n tabuku tabi dunkoko mọ wọn" – Adajọ Akpan lo sọ bẹẹ
Awọn Oyomesi maraarun ti igbẹjọ naa kan ni Oloye Yusuff Ayoola tii se Basorun ilu Oyo, Lamidi Oyewale - Samu, Asimiyu Atanda – Agbaakin, Hamzat Yusuff – Akiniku ati Wakeel Oyedapo .
Eto igbẹjọ naa si lo bọ si asiko ti ijọ ipinlẹ Oyo, gomina Seyi Makinde kede Ọmọọba Abimbola Akeem Owoade gẹgẹ bii ẹni ti yoo gun ori itẹ Alaafin.















