Tinubu, níbo ni ₦234bn owó ètò ìkànìyàn 2023 wà?

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu
Ẹgbẹ oṣelu Labour ti fẹsun kan ijọba apapọ pe o kuna lati ṣalaye bo ṣe na owo ti iye rẹ to ₦234bn to jẹ lara owo to la kalẹ lati fi ṣeto ikaniyan lọdun 2023.
Labour Party fẹsun kan ijọba pe owo naa lo na fun eto idibo Aarẹ to waye lọdun 2023.
Ẹgbẹ naa sọ pe lasiko ijọba Muhammadu Buhari ni ajọ to n ri si eto ikaniyan bere owo ti iye rẹ to ₦800b lati ṣeto ikaniyan amọ lẹyin ọdun kan ati oṣu marun un lẹyin naa, araalu ko gbọ nnkankan nipa rẹ mọ.
"Ijọba ti ya owo sọtọ fun eto ikaniyan ṣaaju akoko yii, amọ a ko tii gbọ nnkankan nipa rẹ"
Bẹẹ naa ni ijọba Tinubu ko sọ ohunkohun nipa rẹ anbelete pe oun funra rẹ yoo ṣeto ikaniyan ọhun.
LP sọ pe ọrọ ti oun sọ ko ṣẹyin bi ijọba Tinubu ṣe kọ lati gbe igbesẹ kankan tabi sọrọ lori eto ikaniyan naa.
Ọkan lara awọn agbẹnusọ LP, Ọmọwe Yunusa Tanko sọ pe ijọba Tinubu ti kuna lati ṣeto ikaniyan, bẹẹ lo tun kuna lati ṣalaye bo ṣe na owo ti wọn la kalẹ fun eto ọhun.
Yunusa ni "Ohun to dara ni lati ṣeto ikaniyan nitori nipa bẹẹ ni ijọba yoo mọ fi iye ọmọ Naijiria atawọn ohun to yẹ ko ṣe fun wọn.
"Ati pe ijọba ti ya owo sọtọ fun eto ikaniyan ṣaaju akoko yii, amọ a ko tii gbọ nnkankan nipa rẹ ati ohun to n dena eto ikaniyan naa.
"Nitori naa, nibo ni owo ọhun wa?"
Agbẹnusọ Peter Obi naa ni ẹtọ awọn ọmọ Naijiria ni lati mọ ohun to n ṣẹlẹ nipa eto ikaniyan to yẹ ko waye.
O ni eyii ṣe pataki nitori ko tọ lati kawọ gbera lori ọrọ naa.
O fi kun pe "Ẹtọ gbogbo araalu ni lati mọ igba ti eto ikaniyan naa yoo waye."
Amọ ṣa, ẹgbẹ oṣelu APC ti sọ pe ahesọ ọrọ lasan ni ẹsun ti Labour Party fi kan ijọba lori eto ikaniyan naa.















