Báyìí ni ọmọ ọdún 19 àtàwọn míì tó pa awakọ̀ Uber ṣe kó sí àhámọ́ ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko ní àwọn afurasí méje ló ti wà ní àhámọ́ àeọn fẹ́sùn wí pé wọ́n pawọ́pọ̀ pa awakọ̀ Uber méjì ní Eko.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn afurasí náà lọ́wọ́ nínú ṣíṣekúpa àwọn awakọ̀ Uber ní agbègbè Lekki àti Ajah.
Kọmíṣánnà ọlọ́pàá Eko, Olanrewaju Ishola ló ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ yìí nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní oríkò iléeṣẹ́ ọlọ́pàá lọ́jọ́ Àbámẹ́ta.
Ishola ṣàlàyé ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá tẹ àwọn afurasí mẹ́rin kan àtàwọn ẹgbẹ́ ẹlẹ́ni mẹ́ta mìíràn ní àyè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fẹ́sùn ṣíṣekúpa àwọn awakọ̀ náà ní àyè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí ìròyìn ń gbòde káàkiri Nàìjíríà nípa bí àwọn awakọ̀ ṣe ń pàdánù ẹ̀mí wọn sọ́wọ́ àwọn èrò pàápàá àwọn tó fẹ́ jí ọkọ̀ gbà mọ́ wọn lọ́wọ́.
Ní ti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ti Eko tó wáyé yìí, ọ̀gá ọlọ́pàá ní àwọn afurasí tó ṣiṣẹ́ láabi yìí ni ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mọ́kàndínlógún (19) sí ọdún mọ́kànlélógún (21).
Kọmíṣánnà ọlọ́pàá Eko ní ọjọ́ Kẹsàn-án oṣù Kìíní ọdún 2025 ni àwọn èèyàn bèèrè fún ọkọ̀ lórí áàpù Uber pé àwọn ń lọ sí Obalende láti Chevron tó wà ní agbègbè Lekki.
"Bí wọ́n ṣe dé ibi tó dá díẹ̀ ni wọ́n gún awakọ̀ náà, tí wọ́n sì fẹ́ gba ọkọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ ṣùgbọ́n tí wọn kò rí ọkọ̀ náà gbà nítorí àwọn èèyàn tó ń kọjá nawọ́ gán méjì nínú àwọn afurasí náà.
"Àwọn èèyàn náà ló fa àwọn afurasí méjéèjì lé àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́ fún ìwádìí, èyí ló sì ṣokùnfà bí a ṣe rí àwọn méjì mìíràn mú níbi tí wọ́n sá pamọ́ sí."
Ishola ní àwọn ti gbé òkú awakọ̀ náà lọ sí mọ́ṣúárì ilé ìwòsàn Mainland Hospital Yaba àti pé ọkọ̀ Toyota Camry Big Daddy tó ní nọ́mbà AGL 650 HN àtàwọn ọ̀bẹ tí wọ́n bá lára àwọn afurasí náà wà ní àkàtà àwọn ọlọ́pàá.
Kọmíṣánnà náà tún sọ̀rọ̀ lórí irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí tó wáyé lọ́jọ́ Kejìlá oṣù Kẹsàn-án ọdún 2024.
Ó ní àwọn èèyàn mẹ́ta tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún méjìlélọ́gbọ̀n àti ogójì ọdún ni àwọn fi òfin gbé fẹ́sùn pípa awakọ̀ Uber kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Oluwaseyi Fowler.
Ó sọ pé àwọn afurasí náà jẹ́wọ́ pé Ajah ni àwọn ti jí awakọ̀ náà gbé, táwọn sì gba ọkọ̀ Toyota Camry lọ́wọ́ rẹ̀.
"Wọ́n ní èèyàn táwọn máa ń ta ọkọ̀ táwọn bá jí gbé fún ni àwọn ta ọkọ̀ náà fún."
Ó fi kun pé àwọn afurasí náà ló mú àwọn ọlọ́pàá síbi tí òkú Fowler wà, táwọn sì ba tó ti ń jẹrà nígbà tí àwọn fi máa ṣàwárí òkú náà.
Kọmíṣánnà ọlọ́pàá náà ní àwọn ti gbé àwọn afurasí náà lọ sí ilé ẹjọ́, tó sì ń pàrọwà sáwọn awakọ̀ Uber láti máa wà ní ojú lalákà fi ń ṣọ́rí pẹ̀lú àwọn èrò tí wọ́n ń gbé.
"Irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí kẹta rèé láàárín oṣù mẹ́ta. A ò mọ iye tí wọn kò gbé dé àgọ́ ọlọ́pàá tó ti ṣẹlẹ̀."















