Ilé ẹjọ́ fi àwọn tó ń gbèrò láti gbé ọgbà ẹ̀wọ̀n Boko Haram/ISWAP kalẹ̀ l'Osun sí àhámọ́

Oríṣun àwòrán, Others
Ile ẹjọ gíga to n jokoo niluu Abuja ti pàṣẹ fun àjọ DSS lati fi awọn afurasi mẹwaa ti wọn n gbero lati da ọgba ẹwọn Boko Haram/ISWAP silẹ nipinlẹ Osun si ahamọ fun ọgọta ọjọ titi iwadii yoo fi pari.
Adajọ Emeka Nwite, gbe idajọ naa kalẹ lẹyin ti agbẹjọro àjọ DSS, Y.I. Umar pe fun idajọ ọhun.
DSS lo pe ẹjọ tako afurasi mẹwaa pẹlu iwe ẹjọ FHC/ABJ/CS/1942/V/2024, eyi to pe Adamu Abubakar (ẹni ti ọpọ mọ si Abu Aisha), Babagana Bashuli, Muhammed Adam, Mustapha Abacha, Katuru Muhammed, Babakura Mallam Abacha, Muhammed Ciroma, Ali Gambo, Muhammed Umoru ati Muhammed Bundi, ẹni to jẹ olujẹjọ kinni.
Ogunjọ oṣu kejila ọdun 2024 ni àjọ DSS gbe ẹjọ naa lọ ile ẹjọ.
Ọwọ tẹ awọn afurasi mẹwaa naa ni ìjọba ìbílẹ Ilesa nipinlẹ Osun lọjọ Kẹrindinlogun oṣu Kejìlá ọdun 2024 fun ẹsun ọdaran.
Ajọ DSS sọ fun ile ẹjọ pe iwadii fihan awọn afurasi naa jẹ ọmọ ẹgbẹ Boko Haram/ISWAP.
"Iwadii fihan pe awọn afurasi yii n gbero lati da ọgba ẹwọn Boko Haram/ISWAP silẹ nipinlẹ Osun.
"Lasiko ti afurasi yii n kọ nípa ado oloro ni ọwọ tẹ wọn."
DSS tun sọ fun ile ẹjọ pe awọn afurasi naa jẹ ọmọ ẹgbẹ Abubakar Shekau to di oloogbe ti wọn saa kuro ni inu igbo Sambisa wa si ipinlẹ Osun nitori bi ikọ ologun Naijiria se n pawọn.
Ile ẹjọ tí wa sun igbẹjọ sì ọjọ kẹta oṣu kẹta ọdun 2025
Bakan naa ni Adajọ Nwite tun pasẹ pe ki wọn fi Ayomide Akintunde ati Nurudeen si ahamọ fun ọgọta ọjọ.












