Ìgbé ayé Andrée Blouin - akọni òmìnira ilẹ̀ Afrika tí wọ́n fojú fò

Aworan Andrée Blouin pẹlu fila lori

Oríṣun àwòrán, Eve Blouin

Àkọlé àwòrán, Orilẹede France ni wọn bi Andrée Blouin si, amọ, ọmọbibi orilẹede Central African Republic ni baba ati iya rẹ
    • Author, Wedaeli Chibelushi
    • Role, BBC News
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9

"Mo mọ pe o le ku lẹẹkan ṣoṣo. Iku ara ni akọkọ...lati gbagbe eeyan ni iku keji," Eve Blouin to jẹ onkọtan lo kọ eyi ninu apilẹkọ iwe to kọ jade nipa itan igbesi aye iya rẹ.

Ọrọ ẹlẹyamẹya yii ye Eve yekeyeke julọ.

Lọdun 1950s si 60s, iya rẹ, Oloogbe Andrée Blouin, fi ara rẹ silẹ fun ija ominira ilẹ Afrika, nigba to lewaju awọn obinrin ilẹ DR Congo lati koju awọn ijọba amunilẹru, to si ṣe bẹẹ dide lati di oludamọran pataki fun Patrice Lumumba, Olootu ijọba akọkọ ni DR Congo, ẹni to tun jẹ akọni ominira.

O ba awọn gbajugbaja ajijangbara bii Kwame Nkrumah ti orileede Ghana; Sékou Touré ti orileede Guinea, ati Ahmed Ben Bella ti orileede Algeria da imọ papọ, ti wọn si gbe ọgbọn kalẹ, sibẹ, ko sẹni to fi bẹẹ mọ ọn.

Ninu erongba lati wa ọna abayọ si eyi, akọsilẹ Blouin, to pe ni 'My Country, Africa: Autobiography of the Black Pasionaria', ni wọn tun n tun gbe jade sita, lẹyin ọpọlọpọ ọdun ti eyi ti wọn ṣe jade sita ti tan.

Ninu iwe naa, Blouin ṣalaye nipa erongba ati ipinnu rẹ lati fopin si imunilẹru, to si lo waye nipa iṣẹlẹ buruku kan toun ba pade.

Aarin agbegbe Central African Republic (CAR) ati Congo-Brazzaville, to jẹ pe nigba naa, awọn alakoso ilẹ Faranse sọ ni Ubangi-Shari ati French Congo lo dagba si.

Lọdun 1940s, ọmọkunrin rẹ, ọmọ ọdun meji, René, ni wọn n tọju fun aisan Iba nileewosan ni CAR.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹya meji ni René jẹ, gẹgẹ bi iya rẹ naa ṣe jẹ ẹya meji, ati pe nitori bo ṣe jẹ apa kan ilẹ Afrika, wọn ko fun laaye itọju. Lẹyin ọsẹ diẹ, René jade laye.

"Iku ọmọ mi lo sọ mi di oloṣelu nitori pe ko sohun miran to tun le mu mi ṣe bẹẹ," Blouin kọ ọ ninu apilẹkọ itan ara rẹ naa.

O fi kun un wi pe awọn amunilẹru "kii wa a ṣe nipa igbagbọ ti ara rẹ mọ, bi ko ṣe pe o ti wa di ilana ibi to ti n tan kaakiri igbesi aye gbogbo ilẹ Afrika".

Ọdun 1921 ni wọn bi Blouin, ọmọ ogoji ọdun ni baba rẹ to jẹ ọmọ ilẹ Faranse, ti iya rẹ si jẹ ọmọ ọdun mẹrinla lati ilẹ CAR.

Awọn mejeeji ni wọn ṣalabapade ara wọn nigba ti baba Blouin n kọja ni abule mama rẹ, nibi to ti lọ ta awọn ọja rẹ.

"Koda lonii, itan igbesi aye baba ati iya mi, nigba to n fun mi ni ọpọlọpọ ibanujẹ, o ṣi n ya mi lẹnu," Blouin sọ bẹẹ.

Nigba to ṣi wa lọmọ ọdun mẹta, baba Blouin gbe e saarin agbo awọn ọmọbinrin ti wọn jẹ ẹya meji, eyi ti awọn Faranse n ṣakoso rẹ ni ilu keji to sunmọ wọn, iyẹn Congo-Brazzaville.

Eyi lo wọpọ laarin awọn Faranse ati ilẹ Afrika ti awọn Belgium ko lẹru – erongba wọn ni pe ẹgbẹẹgbẹrun awọn ọmọ ti awọn obinrin ilẹ Afrika bi fawọn amunilẹru yii ni wọn gbọdọ wa nile alailobi, ki wọn si ya wọn sọtọ kuro lawujọ yooku.

Blouin kọ ọ pe: "Ile awọn ọmọ alailobi dabi ibi ti wọn n da idọti si fun awọn ti ọmọ ẹya meji, iyẹn awọn ọmọ ati awọn obinrin Afrika bi fawọn oyinbo alawọ funfun: awọn ọmọ ti wọn ni ẹjẹ meji ti wọn ko yẹ nibikankan."

Aworan Andrée Blouin atawọn ẹbi rẹ

Oríṣun àwòrán, Eve Blouin

Lodilodi ni gbogbo iriri ti Blouin ni nile awọn ọmọ alailobi bọ si – o kọ ọ pe ojoojumọ ni awọn ọmọ to wa nibẹ n jiya, ti wọn ko si fun wọn lounjẹ daadaa, bẹẹ ni wọn tun n sọrọ buruku si wọn.

Ṣugbọn o ṣe ori kikun – o si sa kuro nile awọn ọmọ alailobi naa nigba to pe ọdun mẹẹdogun, nigba ti wọn fẹ fipa mu un lati ṣegbeyawo.

Blouin pada ṣegbeyawo to wu u, lẹẹmeji. Lẹyin iku René, oun pẹlu ọkọ rẹ keji jọ kuro lọ si orileede Guinea, ilẹ Afrika miran ti awọn Faranse n ṣakoso rẹ.

Nigba naa, gbogbo ilẹ Guinea lo n gbona jọjọ fun 'oṣelu ipa', o kọ ọ. Awọn Faranse ti ṣeleri ominira fun orileede naa, ṣugbọn to ba awọn ọmọ Guinea lati korajọ, ki wọn si fimọ ṣọkan lati tọwọ bọwe adehun boya orileede naa yoo ṣi maa tẹsiwaju lati maa lo eto ọrọ aje, iṣakoso ati ibaṣepọ ologun kan naa pẹlu Faranse.

Ẹka ilẹ Guinea ti wọn n jijangbara, Rassemblement Démocratique Africain (RDA) lo n fẹ ki orileede dibo pe awọn ko fẹ bẹẹ, ti wọn si n sọ pe awọn n fẹ ominira patapata kuro lọwọ wọn.

Lọdun 1958, Blouin darapọ mọ ipolongo, to si n lọ kaakiri gbogbo orileede naa lati sọrọ ni gbogbo ibi ipolongo ti wọn n ṣe.

Ọdun kan lẹyin rẹ, Guinea ṣe aṣeyọri nipa gbigba ominira wọn patapata, ti wọn si dibo yan adari wọn ni RDA, Sékou Touré, gẹgẹ bi aarẹ akọkọ.

Lasiko yii, bẹrẹ sii ronu nipa bi yoo sẹ gba ipo oṣelu. O kọ eyi lẹyin ti Guinea gba ominira, o si lo ipo rẹ lati gba aarẹ tuntun CAR, Aarẹ Barthélemy Boganda lamọran, to si rọ ọ lati juwọ silẹ lọna to tọ fun adari Congo-Brazzaville, Fulbert Youlou.

Ṣugbọn sibẹ, igbaninimọran naa ko to, Blouin ni lati fi ara rẹ silẹ fun ayipada kiakia fun ilẹ Afrika.

Nile ounjẹ igbalode kan niluu Conakry to jẹ olu-ilu ilẹ Guinea, o ṣalabapade ẹgbẹ ajafẹtọ ti wọn jọ jiroro lori ohun ti DR Congo yoo pada jẹ lọjọ iwaju.

Ẹgbẹ naa lo rọ Blouin lati ba wọn pe gbogbo obinrin ilẹ Congo jọ, lati dide ja lodi si awọn amunilẹru lati orileede Belgium.

Ọna meji ni wọn tọ Blouin si. Lọna kan, o ni ọmọ kekeekee mẹta – to fi mọ Eve – lati tọ. Lọna keji, "o tun ni ọgbọn ibinu lori ibi ti ile aye n doju kọ", Eve, ẹni ọdun mẹtadinlaadọrin sọ fun BBC.

Lọdun 1960, pẹlu ọrọ iyanju lati ọdọ Nkrumah, Andrée Blouin lọ si DR Congo funra rẹ.

O lọ darapọ mọ awọn ajijangbara olulanilọyẹ bii Pierre Mulele ati Antoine Gizenga, loju ọna, ti wọn si n polongo kaakiri orileede naa bo ṣe tobi to.

Andrée atawọn ẹbi rẹ

Oríṣun àwòrán, Eve Blouin

Ni Kahemba, to wa nitosi Angola, Blouin ati ikọ rẹ da ipolongo duro lati kọ ibudo fun awọn jagunjagun ominira ilẹ Angola, awọn ti wọn sa kuro lati buba awọn amunilẹru ilẹ Portugal.

O ba awọn obinrin sọrọ, o si gba wọn niyanju lati ja fun ẹtọ kan naa laarin ọkunrin ati obinrin, to fi mọ ominira ilẹ Congo. Bakan naa lo tun gbe ọna dide fun ijangbara naa.

Laipẹ, awọn alagbara ilẹ amunilẹrun ati awọn oniroyin agbaye gbọ nipa iṣe takuntakun ti Blouin n ṣe. Wọn si fi oriṣiriṣi ẹsun kan an.

Okiki rẹ tun kan sii, paapaa lẹyin to pade Lumumba.

Ninu iwe rẹ, Blouin ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bii akikanju ọkunrin to jafafa, ẹni ti wọn kọ orukọ rẹ pẹlu goolu soju ofurufu Congo.

Nigba ti orileede naa ti n sunmọ bebe ominira lọdun 1960, Lumumba di olootu akọkọ. Ọdun mẹrinlelọgbọn lo wa nigba naa.

Lumumba yan Blouin gẹgẹ bi alakoso eto rẹ, ati akọwe gbogbo ọrọ rẹ. Awọn mejeeji ṣiṣẹ papọ daadaa, to fi jẹ kawọn eeyan maa pe wọn ni "Lumum-Blouin".

Iwe iroyin ilẹ Amẹrika, Times Magazine ṣapejuwe Blouin gẹgẹ bi "arẹwa, ẹni ọdun mọkanlelogoji" ti "itara ati akikanju rẹ jẹ ko di amugbalẹgbẹ oloṣelu ti ko ṣee foju yẹpẹrẹ".

"Ṣugbọn ṣa, ajalu wọ ikọ Lumum-Blouin – ati iṣakoso tuntun – nigba to ku diẹ si iṣakoso wọn.

Lakọkọ, awọn ologun dide lodi si olori ologun wọn, eyi to da họwuhọwu silẹ kaakiri orileede naa. Nigba naa, Belgium, UK ati US ṣagbatẹru igbajọba Katanga, ile ọlọra ti awọn orileede mẹtẹẹta nifẹ si lati gba.

Ikọ awọn ologun Belgium wọ inu ilu naa lati da eto aabo pada.

Blouin ṣapejuwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bi ogun awọn ọdalẹ, to si lawọn ọdalẹ n ṣiṣẹ kaakiri.

Aworan Andrée nibi to ti n bawọn eeyan sọrọ ni DR Congo

Oríṣun àwòrán, Herbert Weiss

O kọ ọ wi pe Lumumba jẹ "akikanju igbaani tootọ", ṣugbọn to tun gba pe oun ko mọ nnkankan, to si tun maa ni iwa tutu nigba miran.

"Otitọ ni pe awọn to maa n ni ọkan igbagbọ to dara ni wọn maa n tan jẹ julọ," o sọ bẹẹ.

Laarin oṣu meje ti Lumumba gbakoso, olori awọn oṣiṣẹ ologun, Joseph Mobutu gbakoso.

Lọjọ kẹtadinlogun, ọsu Kini, wọn digun yinbọn pa Lumumba, pẹlu atilẹyin orileede Belgium. O ṣee ṣe ki UK naa mọ nipa rẹ, nigba to jẹ pe awọn UK ni wọn kọkọ gbimọ lati pa Lumumba - ṣugbọn ti wọn n bẹru pe o farajin fun Soviet Union lasiko ogun ti wọn pe ni Cold War.

Ninu iwe rẹ, Blouin sọ pe ipaya ati ẹdun ọkan ti iku Lumumba jẹ pa oun lẹnu mọ, toun ko si mọ nnkan toun le sọ.

"Ko tii ṣẹlẹ ri, lati ni iriri ohun ti ko nii le jẹ ki n le sọrọ," o kọ ọ.

Ilẹ Paris lo n gbe lati ti wọn pa Lumumba, lẹyin ti wọn le e danu sẹyin odi, lẹyin iditẹ gbajọba ogun Mobutu.

Lati le ma jẹ ki Blouin sọrọ sinu iwe iroyin agbaye, awọn alakoso jẹ ki awọn mọlẹbi rẹ - ti wọn ti ko lọ si Congo – maa gbe nibẹ gẹgẹ bi awọn ti wọn "ko mọ ogun".

Iyapa naa jẹ eyi to n ba Blouin lọkan jẹ, eyi ti Eve ṣapejuwe gẹgẹ bii "aabo gidi" ati eyi "so ese rere".

Nigba to n sọrọ nipa iru eeyan ti mama rẹ jẹ, Eve fi kun ọrọ rẹ pe: "Ko sẹni ti yoo fẹẹ lati tako o, bo tilẹ jẹ pe o jẹ ẹnikan to ni ọkan irẹlẹ ati ifẹ, o si tun le ta mọra."

Nigba ti Blouin wa ni ibi aabo to farapamọ si, awọn ologun tun lo ja ile mọlẹbi rẹ lole, ti wọn si lu mama rẹ nilukulu pẹlu ibọn, ti wọn si kan egungun ẹyin rẹ.

Awọn mọlẹbi Blouin wa pada lọ darapọ mọ ọn, lẹyin ọpọlọpọ oṣu ti wọn ti jọ yapa.

Wọn lo asiko diẹ ni Algeria – nibi ti wọn ti aarẹ akọkọ lẹyin ominira, Ahmed Ben Bella ti fun wọn ni iranwọ nla.

Lẹyin naa ni wọn pada lọ maa gbe ni Paris. Sibẹ, Blouin ṣi tun n jẹ ọkan lara awọn ajijangba fun ilẹ Afrika lati ọna jinjin "nipa oriṣiriṣi apilẹkọ, ati ipade lojoojumọ", Eve kọ ọ ninu iwe rẹ.

Aworan Andrée Blouin to duro sita

Oríṣun àwòrán, Herbert Weiss

Nigba ti Blouin bẹrẹ sii kọ itan nipa ara rẹ lọdun 1970s, o ṣi tun n ni ifẹ si irin ajo ominira to fi ara rẹ jin fun.

O gbe oriyin nla fun Sékou Touré, to si jẹ pe nigba naa, o ti gbe ẹgbẹ oṣelu kan ṣoṣo fun orileede naa, to si n pe fun ominira lati le sọrọ.

Blouin ninu igbagbọ rẹ gba pe ilẹ Afrika ko tii bọ kuro.

"Kii ṣe awọn ara ita ni wọn ba ilẹ Afrika jẹ julọ, bi ko ṣe ifẹ ara ẹni awọn eeyan ati iwa imọ-tara-ẹni-nikan to jẹ gaba lọkan awọn olori wa," o kọ ọ.

O banujẹ lori iku afojusun rẹ, debi wi pe o kọ lati maa loogun lori aisan jẹjẹrẹ to n ba finra nigba naa, to si n ba agọ ara rẹ jẹ.

"O jẹ nnkan ibanujẹ to le lati wo o. Nko tiẹ wa lagbara kankan mọ," Eve sọrọ.

Ọjọ kẹsan, oṣu Kẹrin, ọdun 1986 ni Blouin jade laye niluu Paris, lẹni ọdun marundinlaadọrin. Gẹgẹ bi Eve ṣe sọ, o ni ọrọ ti iku ka mọ mama oun lẹnu ni "dreary indifference".

O jẹ aritọkasi ati imisi fun awọn kan. Niluu Kinshasa to jẹ olu-ilu DR Congo, aarin gbungbun ti wọn fi peri Blouin ni wọn ti ṣagbekalẹ oriṣiriṣi eto ẹkọ, ipade nla ati gbọngan aworan fiimu.

Ati fun gbogbo orileede mi, ilẹ Afrika, itan igbesi aye Blouin ti ko wọpọ ni wọn gbe jade fun igba keji, lasiko yii fun ile aye to nilo itan awọn obinrin to ti ko ipa to jọju.

Awọn onkawe yoo kọ nipa ọmọdebinrin to dide lati ori akitan awọn iṣakoso amunilẹru, lati ja fun ominira ẹgbẹlẹgbẹ ọmọ ilẹ alawọ dudu ni Afrika.