Ìgbà wo ni Donald Trump yóò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi ààrẹ orílẹ́èdè Amẹ́ríkà?

Donald Trump

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Donald Trump ti ẹgbẹ oṣelu Republican ni yoo di aarẹ ilẹ Amẹrika to kan, lẹyin to ti fidi Kamala Harris ti ẹgbẹ oṣelu Democrat janlẹ ninu eto idibo aarẹ oṣu Kọkanla ọdun 2024.

Trump ni aarẹ to kọja nilẹ Amẹrika, to ṣe laarin ọdun 2017 si 2021.

Lasiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, Trump ko tii di aarẹ bi ko ṣe pe aarẹ ti wọn dibo yan ṣi ni, bẹẹ si ni igbakeji rẹ, JD Vance, naa jẹ igbakeji aarẹ ti wọn dibo yan.

Ọjọ Aje, ogunjọ, ọsu Kinni, ọdun 2025 ni wọn yoo ṣe iburawọle fun Trump gẹgẹ bi aarẹ ilẹ Amẹrika tuntun fun igbakeji, igba naa ni yoo bẹrẹ iṣẹ gẹgẹ bi aarẹ.

Igbesẹ wo ni Trump ati Vance ti gbe latigba ti wọn ti jawe olubori?

Trump ti ba Aarẹ Joe Biden ti iṣakoso rẹ fẹẹ kogba wọle ṣepade nile agbara, White House – leyi to fi apẹẹrẹ alaafia nipa iṣopopada agbara.

O ti ba awọn adari lagbaye, to fi mọ Olootu ilẹ Canada, Justin Trudeau; Olootu ilẹ Gẹẹsi, Sir Keir Starmer ati Aarẹ ilẹ Ukrain, Volodymyr Zelensky, sọrọ.

Bakan naa lo tun ti ṣepade papọ pẹlu awọn gbajugbaja olokoowo lagbaye bii oludasilẹ ileeṣẹ Amazon, Jeff Bezos; alakoso ileeṣẹ Meta, Mark Zuckerberg; OpenAI, Sam Altman; TikTok, Shou Zi Chew ati Apple, Tim Cook ṣepade ni ile rẹ to wa ni Mar-a-Lago, Florida.

Ni igbaradi fun ibura, aarẹ ti wọn dibo yan ati ikọ rẹ ti gba oniruuru esi nipa eto aabo apapọ nipa idunkooko ati iṣẹ awọn ologun to n lọ lọwọ

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Trump tun ti yan ọpọ awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ, ti yoo di awọn ipo to ṣe pataki mu ninu iṣakoso rẹ, paapaa awọn ti ẹnu n kun kaakiri.

Lara wọn ni sọrọsọrọ ileeṣẹ iroyin Fox News to tun jẹ agba ologun, Pete Hesgeth ti yoo di ipo akọwe ologun mu. Latigba ti Trump ti kede rẹ ni oriṣiriṣi awuyewuye ati ibeere ti dide nipa boya o kaju oṣuwọn fun ipo naa, ati ẹsun ti wọn fi kan an nigba kan ri. Gbogbo rẹ lo sọ pe ohun ko mọ nnkankan nipa rẹ.

Akọwe agba fun ileeṣẹ eleto ilera, Robert F Kennedy Jr, ti sọ pe ẹsun ti wọn fi kan oun nipa oogun aṣejamba kii ṣe toun, nitori toun ko mọ ohunkohun nipa rẹ.

Trump tun yan ọrẹ atijọ, Pam Bondi lati di adajọ agba. Ẹni to kọkọ yan, Matt Gaetz, lo sọ pe oun ko ṣe mọ, lẹyin to koju oniruuru ifẹsunkan – eyi to loun ko mọ nnkankan nipa rẹ.

Gbogbo awọn ti Trump yan yii ni ile igbimọ aṣofin ilẹ Amẹrika yoo buwọ lu nigba to ba to asiko.

Ogbontarigi olowo agbaye nni, Elon Musk ni yoo jẹ alakoso agba fun ẹka ileeṣẹ ti wọn pe ni Department of Government Efficiency (Doge), oun pẹlu oludije sipo aarẹ nigba kan ri labẹ ẹgbẹ oṣelu Republican, Vivek Ramaswamy, ni wọn yoo jọ ṣiṣẹ papọ, pẹlu erongba lati mu adinku ba iye owo ti wọn yoo maa na, lati ma ba a fowo ṣofo.

Trump tun ti yan awọn ibatan rẹ meji: baba ọkọ Tiffany ọmọ rẹ, Massad Boulos, gẹgẹ bi oludamọran pataki lori ọrọ to nii ṣe pẹlu ilẹ Arab ati Middle Eastern.

Ẹnikeji ni baba ọkọ ọmọ rẹ keji, Ivanka, iyẹn Charles Kushner, toun yoo ṣiṣẹ gẹgẹ bi aṣoju ilẹ Amẹrika si orileede France.

O tun ti kede Warren Stephens gẹgẹ bii aṣoju silẹ Gẹẹgi.

Bẹẹ lo tun yan Mark Burnett to jẹ alakoso agba fun British TV executive Mark Burnett, gẹgẹ bi alabaṣiṣẹpọ pataki silẹ Gẹẹsi.

Ki lo ṣẹlẹ laarin ọjọ idibo ati ọjọ ibura?

Ni kete ti wọn ba ti pari gbogbo eto kika ibo, eto ti wọn pe ni 'electoral college' ni yoo sọ pato abajade esi idibo.

Ni ipinlẹ kọọkan, gbogbo esi ibo ti wọn gba patapata ni wọn yoo gba. Bi oludije ba ti le ṣe aṣeyọri lati gba eyi - ti kii sii ṣe atilẹyin awọn oludibo funra wọn – ni yoo sọ ẹni to jawe olubori idibo aarẹ.

Igbesẹ yii ni yoo jẹ ki wọn gbe ibo fun ẹni to ba jawe olubori nipinlẹ kọọkan.

Eyi ni nigba ti awọn ti wọn dibo yan lawọn ipinlẹ yii kaakiri orileede naa ba ti pade lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kejila, ti esi naa si jọ ara wọn, eyi to ṣafihan pe Trump bori pẹlu ibo 312, lati fidi akẹgbẹ rẹ, Harris toun ni ibo 226, janlẹ.

Igbimọ ti wọn pe ni 'US Congress' yoo jokoo ipade lọjọ kẹfa, oṣu Kinni lati pari gbogbo eto idibo, ki wọn si fidi aarẹ tuntun mulẹ. To si jẹ pe igbakeji aarẹ to fẹẹ kogba wọle, Kamala Harris ni yoo dari gbogbo eto naa.

Ibi ipade yii ni awọn alatilẹyin Trump gbiyanju lati dabaru lọdun 2021, nigba ti wọn kọwọrin lọ si Capitol Amẹrika, lẹyin ti Trump kọ jalẹ lati gba esi idibo naa.

Ogunjọ oṣu Kinni ni wọn yoo bura fun Trump gẹgẹ bi aarẹ. Lẹyin ibura ni yoo bawọn araalu sọrọ fun igba akọkọ gẹgẹ bi aarẹ.

Ẹ ma gbagbe pe Trump ko lọ sibi ibura Biden lọdun 2021. Ṣugbọn ṣa, ileeṣẹ aarẹ, White House ti fidi rẹ mulẹ pe Biden yoo wa nibi eto ibura Trump lọdun to n bọ.

Njẹ Trump yoo di aarẹ ilẹ Amẹrika fun igba kẹt?

Iwe ofin ilẹ Amẹrika ti wọn ṣe atunṣe rẹ fun igba kejilelogun kẹyin si wi pe ki eeyan kan ṣoṣo dipo aarẹ mu fun igba mẹta.

Eyi yoo ṣiṣẹ, koda bi ọrọ ti Trump, pẹlu bi ipo aarẹ rẹ ko ṣe tẹle ara wọn.

Sibẹsibẹ, atunṣe iwe ofin naa ko le da aarẹ tẹlẹ duro lati di igbakeji aarẹ ninu iṣakoso ọjọ iwaju, ṣugbọn awọn onimọ nipa iwe ofin sọ pe yoo ṣoro ki iru rẹ ṣẹlẹ.

Iyẹn ni pe wọn ko lero wi pe ẹni to ti ṣe aarẹ ri, yoo tun gba lati di igbakeji aarẹ.