Lẹ́yìn ọdún márùn-ún, ṣé ikọ̀ Àmọ̀tẹ́kùn ṣe ohun ti aráàlú fẹ́?

Oríṣun àwòrán, Facebook/Rotimi Akeredolu
Ọjọbọ, ọjọ kẹsan, oṣu Kinni, ọdun 2020 ni awọn gomina ati alẹnulọrọ nilẹ Yoruba korajọ siluu Ibadan, ipinlẹ Oyo lati ṣe ifilọlẹ ileeṣẹ eleto aabo ilẹ Yoruba ti wọn pe ni Western Nigeria Security Network, ti ọpọ mọ si Amọtẹkun.
Wọn ni awọn eleto aabo Amọtẹkun yii ni yoo maa daabo bo awọn araalu kaakiri ilẹ Yoruba, bo tilẹ jẹ pe ipinlẹ Eko ko tẹwọ gba a.
Lasiko naa, eto aabo orileede Naijiria, paapaa ilẹ Yoruba mẹhẹ kọja afẹnusọ, nitori pe lojoojumọ ni iwa ipaniyan, ijinigbe, idigunjale ati oniruuru iwa ọdaran gbode.
Asiko naa ni wahala awọn Fulani darandaran ati awọn agbẹ dide, ti ipanijaye si n waye loriṣiriṣi, eyi gan-an lo n kọ awọn gomina lominu, paapaa pẹlu bi ileeṣẹ Aarẹ igba naa ko ṣe sọ ohunkohun lori ikọlu naa.
Gomina ipinlẹ Ondo nigba naa, Arakunrin Oluwarotimi Akeredolu to ti doloogbe bayii lo duro gẹgẹ bi olori wọn nigba naa, to si ni eto aabo ilẹ Yoruba ṣe pataki pupọ.
Lara awọn to wa nibi ifilọlẹ ọhun nigba naa ni Rotimi Akeredolu to jẹ alaga igbimọ awọn gomina lẹkun iwọ-oorun; Gomina Seyi Makinde tipinlẹ Oyo; Kayode Fayemi tipinlẹ Ekiti; igbakeji gomina ipinlẹ Ogun, Noimat Salako-Oyedele; ati igbakeji gomina ipinlẹ Osun, Benedict Gboyega Alabi.
Ọọni Ile Ifẹ, Ọba Enitan Adeyeye Ogunwusi, Deji Osinbogun ati Ọjọgbọn Banji Akintoye, atawọn alẹnulọrọ miran lo wa nibẹ.
Awọn gomina mẹfẹẹfa nilẹ Yoruba bii Ondo, Oyo, Osun, Eko, Ogun, ati Ekiti ni wọn fẹnuko lati ṣagbekalẹ Amọtẹkun, pẹlu erongba lati dẹkun iwa ọdaran to n ba wọn finra.
Gbogbo awọn gomina yii ni wọn ti pese ọkọ amuṣẹya ogun fun ipinlẹ kọọkan, to fi mọ ọkada ọgọrun kan ati awọn irinṣẹ miran lati le jẹ ki iṣẹ naa bẹrẹ ni pẹrẹu.
Bo tilẹ jẹ pe igbagbọ ọpọ awọn eeyan nigba naa ni pe Amọtẹkun ko le so eso rere kankan, paapaa nigba ti ileeṣẹ ọlọpaa ati ileeṣẹ ologun ko yọju sibi ifilọlẹ naa.
Bawọn kan ṣe n sọ pe nitori ifẹ-ara-ẹni ni awọn gomina ilẹ Yoruba ṣe fẹnuko lati ṣagbekalẹ Amọtẹkun, bẹẹ lawọn kan n sọ pe opin de ba awọn to n fi iwa ọdaran jaye familete-ki-n-tutọ.
Koda, minisita feto idajọ nigba naa, Abubakar Malami sọ nita gbangba wi pe "Ko si ijọba ipinlẹ kan yala boya adaṣe tabi ifọwọsowọpọ to ni ẹtọ labẹ ofin lati ṣagbekalẹ ileeṣẹ eleto aabo ni Naijiria tabi lagbegbe rẹ."
Ni gbogbo asiko yii, ko si ile kan to le sun oorun asundọkan, nitori bi awọn agbebọn ṣe n kọlu ile ijọsin, ni wọn n ṣe ikọlu si ile-ẹkọ - bi wọn ṣe n ji ọba gbe, naa ni wọn tun n pa ọba nipakupa, ti wọn si tun n fipa ba awọn obinrin laṣepọ.
Ṣaaju asiko ti Malami sọrọ naa jade, Gomina Akeredolu ṣalaye pe "ireti awọn ni pe ki ileeṣẹ eleto aabo tawọn ṣagbekalẹ rẹ lati ṣiṣẹ papọ pẹlu ileeṣẹ eleto aabo tijọba apapọ.
"Kii ṣe erongba wa ni lati da ileeṣẹ eleto aabo ti yoo tako tijọba apapọ silẹ, bi ko ṣe lati fọwọsowọpọ pẹlu wọn," Akeredolu ṣalaye.
Bakan naa, Gomina ipinlẹ Ekiti, to tun jẹ alaga igbimọ ẹgbẹ gomina nilẹ Yoruba, Kayode Fayemi naa jẹ ko di mimọ pe awọn ko ṣagbekalẹ ileeṣẹ ọlọpaa ẹkun, tabi wi pe awọn n wa ni ikanju lati da ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ silẹ.
Awọn gomina ṣe ifilọlẹ ileeṣẹ Amọtẹkun nipinlẹ wọn
Ipinlẹ Ondo lo kọkọ ṣe ifilọlẹ ileeṣẹ eleto aabo Amọtẹkun, lẹyin ti wọn ṣe ifilọlẹ ninu oṣu Kinni, ọdun 2020.
Ọjọ kọkanla, oṣu Kẹjọ ni Gomina Akeredolu bura fun gbogbo awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa nipinlẹ Ondo.
Ipinlẹ Osun lo tun ṣe ifilọlẹ naa ṣikeji, iyẹn lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun naa.
Inu oṣu Kẹwaa ni ipinlẹ Ekiti ṣe ifilọlẹ ti wọn, nigba ti ipinlẹ Oyo ṣe ifilọlẹ ninu oṣu Kọkanla, ọdun naa.
Awuyewuye lọ daadaa ko to di pe Sẹnetọ Ibikunle Amosun to jẹ gomina ipinlẹ Ogun nigba naa ṣe ifilọlẹ ileeṣẹ eleto Amọtẹkun naa. Inu oṣu kẹrin, ọdun 2021 lo bura fun awọn alakoso ati awọn oṣiṣẹ naa.
Ikọ Amotẹkun n gbiyanju ṣugbọn wọnb le ṣe ju bẹ lọ- Onimọ nipa aabo
Opeyemi Awesu, onimọ nipa eto aabo ba BBC Yoruba sọrọ lori Amoktekun ati awọn ibi ti kudiẹkudiẹ ti wa.
Awesu ni idamarundinladọta ninu ida ọgọrun unh ni oun le fun ikọ Amọtẹkun lẹyin ọdun mẹwa ti wọn ṣe idasilẹ wọn.
"Fun emi, n ko ro pe wọn sẹsẹ iwuri ti a fẹ ati ti reti lọwọ wọn. Pẹlu o se ti jẹ pe awọn naa ni sumọ araalu to, o ni awọn ibi kan ati awọn nnkan ti wọn ko le se.
"O sese ko jẹ ẹru lo n ba wọn, ti ba ni ki n fun ni ida, ma fun wọn ni ida marundinladọta."
Awese ni o sese ko ki awọn ikọ Amọtekun tun lọ fun imọ nipa ọtẹlẹmuyẹ.Pẹlu bi a se n ri wọn kaakiri, awọn janduku si yapa.
"Mi o gbe ni awọn ilu bi Oke Oun, ṣugbọn ibi ti mo wa, ikọ Amọtẹkun tun ni lilo lati saa apa wọn si"
Diẹ lara awọn iṣẹ ti wọn ṣe
Gbara ti awọn gomina ti ṣe ifilọlẹ naa lawọn Amọtẹkun ti bẹrẹ iṣẹ wọn lẹkunrẹrẹ, ti wọn si ṣiṣẹ takuntakun lati koju iṣoro to n koju eto aabo.
Ọrọ wahala to n ṣẹlẹ laarin awọn Fulani darandaran ati awọn agbẹ ni wọn kọkọ gbajumọ, ti wọn si ko ipa ribiribi lati rii pe wahala naa dinku.
Lẹyin eyi, ni wọn tun bẹrẹ lati maa gbogun ti awọn agbebọn ti wọn n wọnu aafin lati lọ maa ṣe ikọlu sawọn ọba alade, awọn Baale ilu, to fi mọ araalu.















