Adájọ́ gbé ìdájọ́ kalẹ̀ lórí ẹ̀sùn 34 tí wọ́n fi kan Trump

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ile ẹjọ to n jokoo niluu New York ti da Aarẹ ti ilu sẹsẹ dibo yan ni orilẹede America, Donald Trump lare pe ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.
Ẹsun mẹrinlelọgbọn ni wọn ka si Trump lẹsẹ saaju idajọ ile ẹjọ.
Adajọ Juan Merchan lo gbe idajọ naa kalẹ lori ẹsun pe Trump san owo fun elere sinima ihoho kan.
Marchan sọ fun ile ẹjọ pe dida Trump lare nikan ni idajọ to wa ni ilana ofin.
O sọ fun Trump pe ,"Ki Ọlọrun wa pẹlu rẹ bi o ṣe fẹ bẹrẹ saa keji rẹ."
Idajọ yii tumọ si pe Trump ko ni koju ijiya kankan tabi ko san owo itanran.
Saaju ni ile ẹjọ wọgile ipe Trump pe ki igbẹjọ naa waye lati ma le jẹ ki Trump di aarẹ akọkọ ti yoo jẹjọ wọ ipo Aarẹ.
Adajọ Merchan ni igbẹjọ naa ko ni ran Trump lọ si ẹwọn.
Trump, ẹni to darapọ mọ igbẹjọ naa lati ori ayelujara lọtẹ yii, lo ti ma n wa si ile ẹjọ tẹlẹ lasiko igbẹjọ.
Nigba to n sọrọ nipa igbẹjọ naa, Trump ni igbẹjọ ọhun lo jẹ eyi to dojutini pupọ bo ti lẹ jẹ ile ẹjọ pada da a lare.















