Àwọn agbésùnmọ̀mi kọlu ibùdó agbára ikọ ọmọ ogun Benin, pa ọmọogun 28

Oríṣun àwòrán, AFP
Adanu nla lo ti koju awọn ọmọ ogun orilẹ ede Benin bayii, pẹlu bi ikọ agbesunmọmi kan ṣe kọlu ọkan lara ibudo agbara ologun wọn.
Ilẹ Niger ati Burkina Faso to jẹ alamuleti wọn ni wọn ni ikọlu naa ti rugbo wa, gẹgẹ bi awọn alaṣẹ ilu naa ṣe sọ.
Ọgagun Faizou Gomina, Olori ọmọ ogun Benin, ṣalaye pe awọn agbesunmọmi naa ti wọ ọkan lara awọn ibudo agbara Benin.
O ni alẹ Ọjọruu ni wọn kọlu ibẹ.
"Mẹwaa ti ṣe wa." Ọgagun Gomina lo sọ bẹẹ
Lasiko ti a kọ iroyin yii, ko ti i sẹni to mọ awọn to wa nidii ikọlu naa, ṣugbọn ọlọkan-o-jọkan ikọlu lo ti koju orilẹede Benin lẹnu ọjọ mẹta yii, paapaa lapa Ariwa ilu naa. Awọn agbebọn onijihaadi ni wọn n naka ikọlu naa si ju, wọn ni awon orileẹde to wa nitosi Benin ni wọn fi ṣe ibugbe, ti wọn n gbabẹ wọle si Benin lara.
'Ọmọ ogun 120 ni wọ́n pa ni Benin láàárín 2021 sí 2024'
Gẹgẹ bi ẹka ọtẹlẹmuyẹ kan ṣe ṣalaye fun iroyin AFP, ko din ni ọmọ ogun ọgọfa (120), ti wọn ku ninu ikọlu laaarin ọdun 2021 si 2024.
Loṣu to kọja, awọn agbebọn pa ṣọja mẹta, wọn si tun ṣe awọn ṣọja mẹrin mi-in leṣe nibi ti awọn ologun naa ti n ṣọ ọpa epo kan lagbegbe Ariwa-Ila Oorun ilu naa (North-East).
Bo tilẹ jẹ pe Ọgagun Gomina ko sọ onka awọn to kú ninu ikọlu Ọjọruu yii, ẹgbẹ alatako; The Democrats, sọ pe yoo to ṣọja ọgbọn (30) ti wọn pa ni Alibori. Ẹka iroyin Reuters lo ro eyi.
Bakan naa ni ẹnikan toun naa jẹ ẹṣọ alaabo, sọ fun ẹka iroyin AFP pe eeyan mejidinlọgbọn, (28) lo ku.
" A n tẹsiwaju ninu iṣẹ ifọlumọ ti a n ṣe, alatako ogoji lati mu balẹ," Bẹẹ ni ikọ ologun naa sọ.
Ọgagun Gomina ṣalaye pe ikọlu ọtẹ yii jẹ ọkan lara awọn to le ju.
O rọ awọn ileeṣẹ ologun lati fi kun agbara wọn bi wọn ba fẹẹ ṣẹgun awọn eeṣin-o-kọku wọnyi.
"Ẹ ji giri, ẹyin ọmọ ogun ati ẹyin ọgagun, ogun n bẹ niwajuu wa lati ja ka si ṣẹgun.
"Bẹẹ ni Ọgagun Gomina wi fawọn ologun Benin.
Ni 2022, o to ọmọ ogun ẹgbẹrun mẹta ti Benin ko mọra lati koju ogun awọn orilẹede alamuleti, ti wọn si fi tun ọja wọn san le dan-in-dan-in lapa lapa Ariwa.













