Èèyàn mọ́kàndínlógún kú, ọwọ tẹ afurasí mẹ́fà níbi ìṣẹ̀lẹ̀ ìkọlù sílé Ààrẹ Chad

Ọkọ ogun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Àwọn aláṣẹ ní orílẹ̀èdè Chad ní èèyàn mọ́kàndínlógún ló jáde láyé, tó fi mọ́ ọmọ ogun ogun kan, táwọn mẹ́fà mìíràn sì farapa níbi ìkọlù sílé Ààrẹ ní olú ìlú orílẹ̀ èdè náà ní N'Djamena.

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ Ààrẹ, Abderaman Koulamallah nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí amóhùnmáwòrán ní èèyàn mẹ́rìnlélógún ló gbìyànjú láti yawọ ilé ìgbé Ààrẹ lọ́jọ́rú.

Koulamallah ní àwọn afurasí náà mú ọ̀bẹ àti idà dání tí wọ́n sì ṣèkọlù sáwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò tó wà ilé Ààrẹ.

Ó ní ẹ̀ṣọ́ ààbò mẹ́rin ni wọ́n gún, tí ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò náà sì ti jáde láyé, táwọn méjì míì sì wà ní ẹsẹ̀ kan ayé àti ọ̀run.

Ó ṣàlàyé pé àwọn afurasí náà ti rí ààyè wọ ilé Ààrẹ kí ọwọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò tó tẹ̀ wọ́n.

Koulamallah, tó tún jẹ́ Mínísítà fọ́rọ̀ ilẹ̀ òkèrè Chad, fi kun pé àwọn mẹ́fà ni ọwọ́ òfin ti tẹ̀ lórí ìkọlù ọ̀hún àmọ́ àwọn afurasí kọ̀ láti sọ ohunkóhun.

Ó ní ìwádìí ti ń lọ lọ́wọ́ àti pé ẹ̀ka tó ń rí sí ìpẹjọ́ máa tó ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ gangan láìpẹ́.

Bákan náà ló ní ìkọlù náà kìí ṣe ìgbéṣùmọ̀mí nítorí àwọn afurasí náà kò ní nǹkan ìjà ogun tó lágbára tó bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ yàtọ̀ sí ọ̀bẹ àti idà kékeré tí wọ́n dání.

Ó wá kan sáárá sáwọn ọmọ ogun fún bí wọ́n ṣe tètè ṣàmójútó ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Ìjọba kò ì tíì sọ ohunkóhun lórí ohun tó fa ìkọlù náà.

Àwọn afurasí Boko Haram ló ṣe ìkọlù sí ilé Ààrẹ - Ìjọba Chad sọ̀rọ̀

Agbẹnusọ fun ijọba Chad

Oríṣun àwòrán, facebook

Àwọn aláṣẹ ní orílẹ̀ èdè Chad ní iléeṣẹ́ ológun orílẹ̀ èdè náà lọ́jọ́rú ṣe ìdádúrò ìkọlù àwọn afurasí agbéṣùmọ̀mí Boko Haram sí N'Djamena àti iléeṣẹ́ Ààrẹ.

Gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ ìròyìn abẹ́lé, Tchad24 ṣe sọ, ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́rú ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọkọ̀ ológun ń mórílé iléeṣẹ́ Ààrẹ, tí ìró ìbọn sì ń dún lákọlákọ ní agbègbè iléeṣẹ́ Ààrẹ náà.

Agbẹnusọ ìjọba Chad, tó tún jẹ́ Mínísítà fọ́rọ̀ ilẹ̀ òkèrè, Abdel Rahmane Koulamallah sọ pé ìgbìyànjú àwọn afurasí agbéṣùmọ̀mí láti dá orílẹ̀ èdè náà rú ni àwọn ti ṣàmójútó rẹ̀.

Koulamallah nínú fídíò kan tó wà lórí ayélujára Facebook ní àwọn máa fi bí gbogbo nǹkan bá ṣe ń lọ tó aráàlú létí.

Gbogbo ọ̀nà tó lọ sí iléeṣẹ́ Ààrẹ ni wọ́n dí pa, tí wọ́n sì kó ọ̀pọ̀ àwọn ọkọ̀ ológun sí ojú ọ̀nà èyí tó ń fa inú fu, àyà fu láàárín àwọn olùgbé agbègbè iléeṣẹ́ Ààrẹ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọ̀kan lára àwọn aráàlú ìlú tó bá BBC sọ̀rọ̀ ní èrò ikú ni fún ikọ̀ agbéṣùmọ̀mí kankan láti gbèrò láti ṣe ìkọlù sí iléeṣẹ́ Ààrẹ.

"Gẹ́gẹ́ bí olùgbé N'Djamena, mi ò bẹ̀rù rárá nítorí àwọn ọmọ ogun wa dúró ire. Gẹ́gẹ́ bí àwọn fídíò tí a rí, wọ́n pa díẹ̀ lára àwọn tó ṣe ìkọlù náà, táwọn mìíràn sì wà ní àhámọ́. Lóòótọ́ ni pé ó ń kọwá lóminú nítorí a ò mọ bí àwọn agbéṣùmọ̀mí náà ṣe ti pọ̀ nínú ìlú sí àti bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́."

Olùgbé mìíràn di ẹ̀bi ìṣẹ̀lẹ̀ náà rú France, bó ṣe ní bí Ààrẹ Emmanuel Macron ṣe ń tako àwọn Ààrẹ tó ń yà pẹ̀lú France lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta lágbára díẹ̀.

"Macron ní àwọn olórí orílẹ̀ èdè Áfíríkà gbàgbé láti dúpẹ́ lọ́wọ́ France fún ipa tó kó láti gbógun ti ìgbéṣùmọ̀mí."

Ọ̀pọ̀ àwọn olùgbé ló wà nínú ilé lásìkò tí ìró ìbọn náà ń dún ní agbègbè ilé Ààrẹ, tí ọ̀pọ̀ sì ń rò ó pé bóyá ìdìtẹ̀gbàjọba ló fẹ́ wáyé níbẹ̀.

Àwọn fídíò tó gba orí ayélujára ṣàfihàn òkú àwọn ènìyàn èyí tí wọ́n fura sí pé wọ́n jẹ́ ọmọ ikọ̀ agbéṣùmọ̀mí.

Ṣáájú nix àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ France tí iye wọn tó àádọ́rin kúrò ní N'Djamena ní ìbámu pẹ̀lú kíkó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kúrò ní Chad.

Àwọn orílẹ̀ èdè mẹ́ta mìíràn táwọn ọmọ ogun ń darí rẹ̀, Burkina Faso, Mali àti Niger ti ní káwọn ọmọ France kúrò ní ilẹ̀ àwọn.

Bákan náà ni Ivory Coast àti Senegal ní kí France kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kúrò ní orílẹ̀ èdè àwọn.

Ìró ìbọn sọ lákọlákọ nítòsí ilé ààrẹ lórílẹ̀èdè Chad

Iro ibọn sọ lakọlakọ nitosi il;eeṣẹ aarẹ orilẹede Chad to wa ni N'Djamena tii ṣe olu ilu orilẹede naa.

Awọneeyan to sun mọ ijọba orilẹede naa sọ pe iro ibọn naa waye nigba ti awọn ọmọ ogun orilẹẹede naa doju ija kọ awọn afurasi agbesunmọmi kan ti wọn fẹ wọ ile ijọba naa.

Iro ibọn ati ina naa waye fun ọpọlọpọ iṣẹju eyi to fa ikayasoke fun awọn eeyan to n gbe nitosi ibẹ.

Awọn ọkọ ogun loniranran lawọn eeyan ri ni awọn agbegbe to wa nibẹ. Gbogbo opopona to wọ agbegbe ile ijọba naa ni wọn ti pa.

Agbẹnusọ kan fun ijọba orilẹede Chad ṣalaye pewọn ti pa ina rogbodiyan naa amọ ko tii fi bẹẹ si imọlẹ pupọ lori awọn to wa ni idi iṣẹlẹ naa.

Ni ọjọ Iṣẹgun ni aarẹ orilẹede Chad, Mahamat Idris Deby Itno gba alejo minisita fun ọrọ ilẹ okeere lati orilẹede China lalejo,

Igbesẹ yii n waye pẹlu bi orilẹede China ṣe n ja okun ajọṣepọ pẹlu France.