Kí ni ìdí tí àwọn mọ ìjọ Celestial ṣe máa ń kórajọpọ̀ létí òkun lorílẹ̀èdè Benin Republic?
Gẹgẹ bi iṣe wọn lọdọọdun, awọn ọmọ ijọ mimọ CCC Sẹlẹ peju pesẹ sibi adura eti okun ti ọdun 2024 leti okun Seme Podji lorilẹede Benin Republic.
Aisun ọjọ Keresimesi ọjọ kẹrinlelogun oṣu Kejila ọdun 2024 ni eto naa gberasọ.
Eto yii tẹsiwaju ni ọjọ kẹẹdọgbọn to jẹ ọjọ ọdun Keresimesi gan an.
Ọpọlọpọ awọn aṣoju ijọ CCC kaakiri agbaye lo wa nibi eto akanṣe adura tọdun 2024 yii pẹlu oniruuru ẹri lati ẹnu awọn ọmọ ijọ to wa nibi eto naa.

Lati ọjọ kẹrinlelogun si ọjọ kẹẹdọgbọn ni ero ti pọ niluu Cotonou ati Seme Kpodji to si dabi ẹni pe wọn fẹ goke Arafat nibẹ nitori eto akanṣe adura eti okun yii ti ọdun 2024 yii.
Ki lohun to wa ni ipilẹ ikorajọpọ yii gan?
Gẹgẹbi ohun ti awọn aṣiwaju ijọ naa sọ fun BBC, Ẹniọwọ Patrice Lachimi ṣalaye pe oludasilẹ ijọ naa, Ẹniọwọ Samuel Oshofa, lo fi ofin le ilẹ wi pe ki gbogbo ọmọ ijọ CCC lagbaaye maa wa si eti okun Seme fun adura ọlọdọọdun yii.

Ẹniọwọ Lachimi ṣalaye pe wọn le oludasilẹ ijọ CCC kuro ni Naijiria nigba to fẹ da ijọ silẹ nibẹ.
O ni lẹyin naa ni Oshofa mori le orilẹede Benin Republic nibi to tẹdo si to si ti da ijọ CCC silẹ.

Ẹniọwọ Lachimi ko ṣai mẹnuba ibi ti wọn sin oludasilẹ ijọ CCC si niluu Imeko.
Ninu ọrọ tiẹ, ọkan lara awọn ojiṣẹ Ọlọrun ijọ Sẹlẹ to wa nibi eto naa, Ogougbayi Daniel sọ pe o ti to ọdun mẹẹdogun ti oun ti n wa sibi akanṣe adura naa.
O ni ''ko si ẹni to n wa sibi eto akanṣe adura yii ti ko ni ẹri, to ba fi gbogbo ọkan rẹ wa Ọlọrun.
Ẹni to ba wa Ọlọrun Oshofa wa sibi eto lotitọ ati lododo yoo ri iyatọ ninu irinajo rẹ.

Ọpọ eeyan ni wọn maa n ko oriṣiiriṣii nnkan wa lati ṣe idupẹ lẹyin ti wọn ba ri idahun si adura wọn tan.
Lati gbogbo agbalaaye lawọn eeyan maa ti n wa ibi wa gba adura,'' Pasitọ Ogougbayi lo sọ bẹẹ.

O ni lọdọọdun loun maa n wa pẹlu iyawo atawọn ọmọ oun tori eto akanṣe adura naa ṣe pataki.
Ojiṣẹ Ọlọrun Ogougbayi wa rọ gbogbo ọmọ ijọ Mimọ CCC lati maa wa fun eto akanṣe adura ọlọdọọdun yii tori anfaani to wa ninu rẹ pọ.





