Àlàyé rèé lórí ṣhégè tí ojú àwọn àgbẹ̀ alálùbọ́sà ń rí pẹ̀lú ọ̀wọ́ngógó àlùbọ́sà tó gbòde

Aworan alubọsa ninu apo

Oríṣun àwòrán, Getty image

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ki i ṣe araalu to n ra alubọsa to ti wọn gogo bayii nikan lo n ke irora, bẹẹ naa ni awọn agbẹ to n gbin alubọsa ọhun ṣe n ka iye ofo to ṣe wọn.

Ẹgbẹ to tobi ju ninu awọn to n gbin alubọsa lorilẹede yii, (Nigerian Onion Farmers and Processors Association), ba BBC sọrọ lori bi alubọsa ṣe wọn ti ko si tun tobi pupọ lasiko yii.

Ninu alaye wọn ni wọn ti sọ pe ko din ni aadọjọ biliọnu naira (150b) ti awọn padanu bi alubọsa ṣe wọn naa.

Ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ alalubọsa ni Naijiria to ba BBC sọrọ, Ibrahim Danjuma, ṣalaye pe inu ibẹru bojo ni awọn agbẹ to n gbin alubọsa wa bayii.

Kí ló fa ìbẹ̀rù f'áwọn àgbẹ̀ alálùbọ́sà?

Aworan alubọsa

Oríṣun àwòrán, Getty image

''Ibẹru gba ọkan awa agbẹ ti a n gbin alubọsa bayii, ohun to si fa a ni pe awọn ẹya alubọsa ti ko daa ti a ra ti a si gbin lai mọ pe ko ni i yọ ọmọ ire fun wa.

''Ewe lasan lo yọ ṣagila lai si alubọsa nisalẹ rẹ.''

Bẹẹ ni Ibrahim Danjuma ṣalaye.

O fi kun un pe ipinlẹ Sokoto ati Kebbi ni orisun alubọsa ni Naijiria.

O ni ibẹ ni wọn ti maa n ko o lọ si orilẹ ede Burkina Faso, Mali, Ivory Coast ati Ghana.

Ibrahim sọ pe ṣugbọn bi eeyan ba de ipinlẹ Sokoto bayii, yoo ri awọn agbẹ to n ronu nitori gbese ti wọn jẹ lati ara alubọsa ti ko leso naa ni.

Agbẹ alalubọsa yii tẹsiwaju, pe lọdun mẹta sẹyin ni awọn ra oriṣi alubọsa kan lati France, lati gbin.

O ni o daa pupọ o si mu alubọsa gidi jade, ṣugbọn lẹyin ẹ, eyi ti wọn tun mu wa ko daa rara ni.

''Àpò àlùbọ́sà ko ju ẹgbẹrun lọna ọgun lọ tẹle, o ti di 200,000 bayii''

Nigba to n ṣalaye afikun to ba owo alubọsa, Ibrahim sọ pe ẹgbẹrun mẹẹẹdogun (15,000) si ogun ( 20,000) ni apo alubọsa kan tẹlẹ.

Ṣugbọn nigba ti wahala yii ti bẹrẹ lo ti di ẹgbẹrun lọna igba (200,000) bayii.

"Bi alubọsa ṣe wọn to yii, yoo ya awọn eeyan lẹnu bi yoo tun ṣe ri laaarin oṣu kan si mẹta.

" Ẹgbẹrun lọna igba naira (200,000) ni apo alubọsa kan bayii, ti ko ju meẹẹdogun si ẹgbẹrun lọna ogun lọ tẹlẹ. '' Danjuma lo ṣe afikun bẹẹ.

O ni ko din ni alubọsa 150b tawọn ti padanu bayii, to si jẹ pe lojumọ kan, alubọsa biliọnu meji ni wọn n pa owo rẹ ni Sokoto ati Kebbi.

'Àìmọ̀ ló kò wa sí gbèsè yìí'

Alaga ẹgbẹ awọn agbẹ alalubọsa ni Naijiria, Aliyu Maitasamu, ṣalaye fun BBC pe aimọ lo ko awọn si gbese.

Maitasamu sọ pe nigba ti awọn ko ni anfaani lati ri alubọsa gidi gbin ni awọn gba oriṣi kan lati Algeria.

O ni awọn ti kọkọ pe ijọba lati ra awọn lọwọ, nipa biba awọn orilẹede ilẹ okeere sọrọ, ki wọn pese eso alubọsa to yoo so eso rere pada.

Nigba ti ko bọ si i lo di pe awọn gba ti Algeria ti ko daa.

" Nigba ti ko ṣee ṣe, awọn kan mu eso buruku waa ba wa lati Algeria, eyi ti awọn agbẹ gbin."

"Ti a ba mọ pe gbese la maa jẹ lati ara eso naa ni, a o ba ti ma jẹ ki wọn ko o wọle si Naijiria rara"

O ni awọn padanu alubọsa toonu igba (200,000 tonnes of onions) ti owo rẹ 150 billion naira.

" A ti padanu ere oko asiko ẹẹrun yii na, ṣugbọn ijọba le ran wa lọwọ lati bẹrẹ ọgbin bayii fun asiko ojo."

Alaga awọn agbẹ alalubọsa ni Naijiria lo sọ bẹẹ.