Wọ́n ti búra fún John Mahama gẹ́gẹ́ bíi ààrẹ tuntun lórílẹ̀èdè Ghana

Wọn ti bura fun aarẹ tuntun lorilẹede Ghana, John Dramani Mahama ni Accra tii ṣe olu ilu Ghana .
Eto ibura naa waye ni gbagede Black Star Square lọjọ Iṣẹgun.
Mahama bori ibo aarẹ lorilẹede Ghana lasiko idibo to waye ni ọdun 2024.
Eto idibo naa pẹlu lo ṣina fun orilẹede naa lati lanfani obinrin akọkọ ti yoo di ipo igbakeji aarẹ mu lorilẹede naa.
Ọjọgbọn Jane Naana Opoku Agyemang naa bura gẹgẹ bi igbakeji aarẹ orilẹede Ghana lasiko ayẹyẹ naa.
Mahama ti fi igba kan ri jẹ aarẹ orilẹede Ghana laarin ọdun 2012 si 2017 ki aarẹ Nana Akufo-Addo tó n fipo silẹ bayii to gba ipo lọwọ rẹ.
Awọn olori orilẹede kaakiri agbaye wa nikalẹ

Oríṣun àwòrán, @aonanuga1956/X
Awọn olori orilẹede mọkalelogun, ninu eyi ti aarẹ orilẹede Naijiria, Bọla Tinubu to tun jẹ alaga ajọ iṣọkan orilẹede iwọ oorun Afirika lo wa nikalẹ nibi ayẹyẹ.
Mahama n bọ sori ipo aarẹ orilẹede Ghana lasiko ti orilẹede naa n la iṣoro ọrọ aje eyi ti ọpọ ti woye rẹ gẹgẹ bi eyi to buru ju ninu itan orilẹede naa.
Gbogbo awọn ireti wọnyi laraa n ko le Mahama lejika, amọṣa oun pẹlu ti ṣeleri lati doju kọ awọn iṣoro ọrọ aje naa.














