Wo bí o ṣe le wọ orílẹ̀èdè Ghana láì gba 'Visa'

Àwòrán ìwé ìrìnnà

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gbogbo àwọn èèyàn nílẹ̀ Áfíríkà ló lè ṣàbẹ̀wò sí orílẹ̀-èdè Ghana báyìí láì nílò visa.

Ààrẹ to ń fi ipò sílẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Ghana, Nana Akufo-Addo ló kéde ọ̀rọ̀ náà láìpẹ́ yìí.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ ìdágbére rẹ̀ kẹyìn lọ́jọ́ Ẹtì, Akufo-Addo ní ètò náà ti bẹ̀rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí.

Ìrìnàjò láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn láì gba visa jẹ́ nǹkan táwọn èèyàn kan ti ń pè fún láti mú ìgboro bá ìṣọ̀kan ilẹ̀ Áfíríkà.

Ghana ni orílẹ̀-èdè karùn-ún nílẹ̀ Áfíríkà tí yóò pèsè irúfẹ́ àǹfàní yìí fáwọn orílẹ̀ èdè ilẹ̀ Afíríkà.

Rwanda, Seychelles, The Gambia àti Benin Republic ni wọ́n ti gbé irúfẹ́ ìgbésẹ̀ yìí ṣáájú.

Akufo-Addo sọ fún àwọn aṣòfin lọ́sẹ̀ to kọjá pé inú òun dùn láti buwọ́lu ìgbésẹ̀ náà kí òun tó gbé ìjọba kalẹ̀ lẹ́yìn ọdún mẹ́jọ lórí ipò.

Ghana ló wà ní ipò kẹta nínú àwọn orílẹ̀-èdè Africa tí gbígba visa rẹ̀ rọrùn lọ́dún tó kọjá.

Láti bíi ọdún díẹ̀ sẹ́yìn báyìí ni Ghana tí ń ṣe ìgbéga ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ibi tí àwọn arìnrìn-àjò le ṣe àbẹ̀wò sí ní ilẹ̀ Áfíríkà.