Àṣìta ìbọn ọlọ́pàá rán ọ̀dọ́mọbìnrin lọ sí ọ̀run ọ̀sán gangan l'Ekiti

Awọn ọlọpaa to duro

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ ọlọpaa kan to ṣeeṣi yinbọn pa ọdọmọbinrin kan, Ifeoluwa Adekalu niluu Ado-Ekiti l'Ọjọbọ, to kọja, to si ti wa lahamọ.

Ifeoluwa ni wọn sọ pe ibọn ba niwaju ita ṣọọbu kan to wa ni adojukọ agọ ọlọpaa, lasiko to n kọja lọ, to si ṣe bẹẹ ku loju ẹsẹ.

Bo tilẹ jẹ pe a ko tii le fidi rẹ mulẹ lẹkunrẹrẹ, awọn iroyin kan sọ pe asiko ti Ifeoluwa n bọ lati ibi to ti lọ san owo ile to ṣẹṣẹ gba ni ibọn ti ba a niwaju ita ṣọọbu ọhun, to si gbabẹ sọrun alakeji.

Awọn iroyin mii tun sọ pe ọlọpaa naa lọ si tẹsan ọhun, iyẹn ti ẹkun Oke-Ila lati ṣabẹwo si ọrẹ rẹ kan to ṣẹṣẹ gba igbega lẹnu iṣẹ ni.

Wọn ni idunnu wi pe ọrẹ rẹ naa ti wọn jọ n ṣiṣẹ ọlọpaa ti gba igbega lo mu ko fa ibọn rẹ yọ lati yin in soke, lai mọ pe ibọn ọhun yoo ṣeeṣi paayan.

Ẹnikan naa ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju rẹ ṣalaye pe asiko ti Ifeoluwa n bọ silẹ lati ori ọkada to gun de iwaju teṣan naa ni ibọn ba a, ati pe inu teṣan naa lo n lọ.

Wọn ni awọn to wa nibẹ sare gbe e digbadigba lọ si ile iwosan kan to wa nitosi lati doola ẹmi rẹ, ṣugbọn ti aṣọ ko bọmọyẹ mọ.

Ọga ọlọpaa ipinlẹ naa, Adewale Adeniran nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun awọn akọroyin jẹ ko di mimọ pe ọwọ ti tẹ ọlọpaa to ṣeeṣi yinbọn naa, to si ti wa lahamọ.

Adeniran sọ pe ọlọpaa ọhun yoo koju ifọrọwanilẹnuwo ni ibamu pẹlu ofin to de iṣẹ ọlọpaa.