Ìjàmbá ilẹ̀ rírì gbẹ̀mí èèyàn 95 ní Tibet, ọ̀pọ̀lọpọ̀ míràn farapa

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ko din ni eeyan marundinlọgọrun to ti jade laye bayii nipasẹ ijamba ilẹ riri to waye ni lẹkun Tibet to wa labẹ iṣakoso orilẹede China
Iroyin tun fi kun un pe eeyan aadoje miran tun fara pa nipasẹ ilẹ riri naa to waye ni owurọ Ọjọ Iṣẹgun ni nnkan bi agogo mẹsan an Tibet.
Awọn orilẹede bii Nepal atawọn agbegbe kan ni India pẹlu gburo ọwọja ilẹ riri naa pẹlu.
Nnkan bi agogo mẹsan wọn ni iṣẹlẹ ọhun waye agbegbe ti wọn pe ni Shigatse, Tibet, ti wọn si ni ilẹ riru naa fẹ to iwọn meje le ni ookan (7.1), to si tun jin ni kilomita mẹta mẹwaa (10klm), gẹgẹ bi iwadii ti US Geological Survey ṣe.
Ipa iṣẹlẹ naa ni wọn tun ni imọlara rẹ niluu Nepal to sunmọ wọn ati awon apa kan lorileede India
Ilẹ riru wọpọ lawọn agbegbe naa, eyi to jẹ pe eto ayipada oju ọjọ lo maa n saba a fa.
Agbegbe Shigatse yii ni wọn ri gẹgẹ bii agbegbe to mọ julọ niluu Tibet. Oun si ni ibujokoo Panchen Lama, ọkan pataki ninu ẹsin Tibetan Buddhism, ti wọn ni aṣẹ inu ẹmi rẹ jẹ ekeji si ti Dalai Lama.
Ẹkun Tingri to wa ni aarin gbungbun ibi ti iṣẹlẹ ilẹ riru ti waye, jẹ agbegbe to gbajumọ daadaa fun awọn to n gun oke Mount Everest.
A gbọ pe awọn kan n gbiyanju lati lọ ṣe ayẹwo irin ajo afẹ si ori oke Mount Everest naa laarọ oni, ko to di pe ijamba naa waye, ti wọn si ti wọgile loju ẹsẹ, ọkan lara awọn akọroyin irin ajo afẹ sọ fawọn oniroyin.
O ni gbogbo agbegbe ti wọn fẹẹ ṣabẹwo naa si ni wọn ti ti pa.
Alejo mẹta ni wọn fẹẹ lọ fun ayẹwo irin ajo afẹ naa, ti wọn si ti ko wọn kuro nibẹ nitori aabo, wọn sọ bẹẹ.
Ileeṣẹ iroyin ilẹ China sọ pe ile ti ko din ni ẹgbẹrun kan lo ba ijamba ilẹ riru naa lọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Jiang Haikun, to jẹ oniṣẹ iwadii ijinlẹ nileeṣẹ China Earthquake Networks Center, sọ fun ileeṣẹ CCTV, pe o ṣee ṣe ki ilẹ riru miran tun ṣẹlẹ laipẹ, nitori pe eyi to ṣẹlẹ naa kere jọjọ.
Latigba ti Tibet ti wa lọdun 1950s, ni China ti bẹrẹ sii ṣakoso agbegbe naa, to fi mọ ileeṣẹ iroyin ati ẹrọ alatagba wọn.
Awọn ohun ti wọn gbe sori awọn ayelujara kaakiri ṣafihan gbogbo ibi ti ilẹ riru ọhun ti ṣọṣẹ, ati awọn ile to wo lulẹ.
Ọkan lara awọn to n gbe ni otẹẹli kan ni Shigatse sọ fun ileeṣẹ iroyin ilẹ China, Fengmian News pe ariwo naa ati ilẹ to mi, lo ji oun loju oorun.
O ni loju ẹsẹ loun ti mu awọ-sẹsẹ oun, toun si sare jare sita, nibi toun ti ri ọkọ baluu agberapa toun fo kaakiri.
"Niṣe lo dabi ẹni pe wọn gbe bẹẹdi mi soke," o sọ bẹẹ, to si tun fi kun ọrọ rẹ pe loju ẹsẹ loun ti mọ pe ilẹ riru lo ṣẹlẹ nitori pe iru iṣẹlẹ kekere bẹẹ ṣẹṣẹ ṣẹlẹ ni Tibet ni.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn ọmọ ogun oju ofurufu ilẹ China ti bẹrẹ iwadii lati wo gbogbo agbegbe ti ilẹ riru naa ṣọṣẹ.
Gbogbo ina mọnamọna ati omi lagbegbe naa ni wọn ti ge danu loju ẹsẹ, lai fi akoko ṣofo.
Aarẹ ilẹ China, Xi Jinping ti sọrọ, to si paṣẹ pe ki iwadii bẹrẹ lati mọ awọn to fara kaaṣa ati iranlọwọ fun awọn to farapa.
Jinping ni ki wọn ko gbogbo awọn ti iṣẹlẹ naa gba ile lori wọn lọ sibomiran.
Pẹlu bi ilẹ riru naa ṣe tan de Nepal to, ko sẹni to ku tabi farapa, awọn alakoso ni ẹkun Nepal Namche fidi rẹ mulẹ fun AFP.















