Bó ti wù kó rí, Olorì tẹ́lẹ̀, Naomi, Oriyomi Hamzat àtàwọn tó lọ́wọ́ nínú ètò tó ṣekúpa ọmọdé 35 yóò kojú òfin - Makinde

Aworan Oriyomi Hamzat, Olori Naomi ati Gomina Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Instagram/SeyiMakinde/Queen Naomi

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gomina Seyi Makinde ti ipinlẹ Oyo ti jẹ ko di mimọ pe ko si aniani, o ti di dandan ki awọn eeyan ti wọn fẹsun kan nipa iku awọn ọmọde marundinlogoji nibi iṣẹlẹ ikọluraẹni to waye nibi apejẹ opin ọdun ti olori Ooni Ile-Ife nigba kan, Naomi Ogunwusi, ṣe niluu Ibadan foju ba ile ẹjọ.

Makinde sọ eyi ni ọfiisi ijọba to wa ni olu-ilu ipinlẹ Oyo, Ibadan, lọjọ Aje, ọjọ kẹfa, oṣu Kini ọdun 2025.

Gomina ni ọpọ eeyan lo ti pe oun pe iru iṣẹlẹ to ṣekupa ọmọde marundinlogoji ti waye ni awọn ipinlẹ mii lorilẹede Naijiria, ti ijọba wọn ko si gbe igbesẹ kankan.

Ṣugbọn o jẹ ko di mimọ pe "ipinlẹ Oyo yatọ si awọn ipinlẹ yooku".

"A o ni ri iru iṣẹlẹ yii mọ nipinlẹ Oyo, awọn eeyan ti pe mi pe iru iṣẹlẹ yii waye ni ipinlẹ Anambra ati ilu Abuja, ti ko si si ẹnikẹni to lọ si ẹwọn ṣugbọn ipinlẹ Oyo ki i ṣe ipinlẹ Anambra.

"Ko si bi o ṣe le ni okiki to, idajọ ododo yoo waye. Awọn ẹka idajọ wa ni ibi, o wa lọwọ wọn.

"Ti wọn ba pinnu pe awọn fẹ gba beeli awọn eeyan yii ṣaaju ki idajọ to waye, n ko tako rara ṣugbọn wọn gbọdọ foju ba ile-ẹjọ."

Makinde ni ti gbogbo orilẹede Naijiria ba pinnu pe awọn ko ni tẹle ilana ti ofin la kalẹ, ipinlẹ Oyo yoo tẹle ofin.

Ki lo ti ṣẹlẹ saaju?

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo kede pe ọmọde marunlelọgbọn lo ku nibi iṣẹlẹ ikọluraẹni to waye lasiko ti apejẹ opin ọdun ti olori Ooni Ile-Ife nigba kan, Naomi Ogunwusi, ṣe niluu Ibadan.

Bakan naa ni ọmọde mẹfa ṣi wa nileewosan nitori wọn farapa kọja aala.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa, Osifeso Adewale fi sita ni ọsan Ọjọbọ, o ni awọn tun ti mu ẹni to ṣonigbọwọ eto naa, Wooli Naomi Silekunola.

Lara awọn ti agbẹnusọ ọlọpaa sọ pe awọn ti mu ni Fasasi Abdulahi (Ọga agba ile-ẹkọ Islamic High School, Ibadan), Genesis Christopher, Tanimowo Moruf, Anisolaja Olabode, Idowu Ibrahim, ati Abiola Oluwatimilehin.

SP Osifeso sọ pe awọn ti gbe iwadii lori iṣẹlẹ naa le ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n mojuto iwa ọdaran lọwọ fun iwadii to yẹ.