Àwa la ń wọ igbó lọ wá àwọn tí wọ́n bá jí gbé, àmọ́ ọlọ́pàá ló ń gba oríyìn fún iṣẹ́ wa – Alága ẹgbẹ́ ọdẹ nílẹ̀ Yorùbá

Àkọlé fídíò, Olórí ọdẹ fi ẹ̀[sn kan àwọn ọbalayé kan, Ó ní àwọn ló 'ṣ agbódegbà fún ajínigbé
Àwa la ń wọ igbó lọ wá àwọn tí wọ́n bá jí gbé, àmọ́ ọlọ́pàá ló ń gba oríyìn fún iṣẹ́ wa – Alága ẹgbẹ́ ọdẹ nílẹ̀ Yorùbá

Alaga ẹgbẹ ọdẹ ni ilẹ Yoruba, Alagba Isaiah Ogunyinka ti ṣalaye fun BBC pe ọrọ ijinigbe to n fi ojojumọ le kenka ko le ṣai rí bẹẹ nitori pe, ejo ọrọ naa n ni ọwọ ninu.

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC lori ọrọ ijinigbe ati ohun ti awọn ọdẹ n ṣe lati wawọ rẹ bolẹ, Alagba Ogunyinka ṣalaye pe lọpọ igba to jẹ wi pe awọn ọdẹ tabi agbẹ ba fi ọlọpaa mu awọn darandaran to n ja wọn lole loko, awọn ọbalaye kan ni wọn maa n gbẹyin lọ ree tu wọn silẹ ni ahamọ ọlọpaa.

O ni ọpọlọpọ awọn ọba ni wọn ti ra maluu si ọdọ awọn Fulani to n ba wọn tọju wọn ti wọn si n da awọn ẹran bẹẹ jẹ lọ ba nnkan oko arailu jẹ lọpọ igba, ti awọn ọba wọnyii ki i si i sọ nnkankan.

"Bí fulani ba n da maluu, yoo gbe ada dani si apa bayii, yoo si gbe ibọn si apa bayii; amọṣa ẹ jẹ ki ọmọ Yoruba maa rin lọ bayii ni titi ọlọpaa maa mu u."

"Ti wọn ba dẹ ji eeyan gbe bayii awa ni ẹ maa pe, awa ni a n wọ igbo. Ẹyin o le wọ inu igbo. Wọn a kan bọ wa lọwọ ni, iwe iroyina gbe, redio a sọ tẹlifiṣan naa a gbe, o tan niyẹn."

Olori ọdẹ ilẹ Yoruba naa ṣalaye siwaju pe awọn ọlọdẹ lawọn ọlọpaa maa n da sinu igbo lati lọ wa awọn ti wọn ba ji gbe. Bi wọn ba si ti ri wọn gbe sita lọwọ awọn ajinigbe lawọn ọlọpaa maa bẹrẹ si ni kede ara wọn pe awọn lo lọ gba awọn ti wọn ji gbe silẹ ninu igbekuna awọn to ji wọn gbe.

Ahesọ ọrọ lasan ni ohun ti olori ọdẹ naa sọ -Eselu ti ilu Iselu

Ọba Ebenezer Akintunde Akinyẹmi, Eselu ti ilu Iselu.

Oríṣun àwòrán, others

Amọ lori ọrọ to sọ nipa awọn ọba ati ipa ti wọn n ko ninu titu awọn afurasi darandaran to ba ba oko jẹ silẹ, Eselu ti ilu Iselu, Ọba Ebenezer Akintunde Akinyẹmi ni ko si ootọ nibẹ.

O ni ko si bi ọba ṣe le paṣẹ fun agbofinro lati fi ọdaran silẹ ayafi agbofinro ti ko ba mọ iṣẹ rẹ niṣẹ.

Balaye naa ni ahesọ ọrọ ni ẹsun naa "nitoripe ko si ẹni kankan to ju ofin lọ.