Ọkọ̀ agbépo kan tún gbiná, òkú tún sùn

Ibi iṣẹlẹ kan

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ko din ni eeyan marun-un to ku nibi ijamba ọkọ agbepo kan to ṣubu nijọba ibilẹ Agbor Ika, ipinlẹ Delta lọjọ Aiku.

Bi ọkọ agbepo naa ṣe ṣubu lo ti gbina lojiji, to si pa eeyan mẹrin, ẹnikan yooku ku nitori ipaya ijamba ọhun, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

Ijanu ọkọ agbepo naa ni wọn ṣalaye pe o deedee ja lori irin, ti wọn si ni awakọ naa gbiyanju lati wa ọna abayọ, ko ma fa a ijamba, ṣugbọn ti ko ṣee ṣe.

Ọkọ Toyota Corolla kan ti wọn gbe sẹgbẹ opopona ni wọn ni ọkọ agbepo ọhun lọ fori sọ, to si ṣubu lulẹ, ko to di pe o gbina.

Bi ina ọhun ṣe ṣẹyọ ni wọn sọ pe awọn to wa nibẹ sa asala fun ẹmi ara wọn, ko to di pe wọn ranṣẹ si awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana.

Ọkan lara awọn tiṣẹlẹ ọhun ṣoju wọn ṣalaye pe awakọ ọkọ agbepo naa ti n pariwo bo ṣe n bọ wi pe ijanu oun ti ja, ki awọn eeyan kuro lọna.

O ni ọpọ awọn eeyan ko kọkọ gbagbọ pẹlu ere ti ọkọ agbepo naa n ba lọ, afigba to kọlu mọto kan ti wọn gbe siwaju banki to wa nibẹ, to si ṣubu lulẹ.

Ẹni naa to kọ lati darukọ ara rẹ sọ pe obinrin kan to n kọja ni epo ti ọkọ agbepo naa ba, to si ku loju ẹsẹ pẹlu ipaya to mu, kii ṣe pe o fẹ lọ bu epo.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Isọda lọhun ni obinrin naa wa ki epo to fọnka too ba a, to si ṣubu lulẹ. Waya ina to ja lulẹ lo ba ọmọdekunrin, ọmọ ọdun metadinlọgbọn kan, toun naa pẹlu si ku."

O tẹsiwaju pe ileeṣẹ pannapanna to wa nitosi ko ni omi pupọ, idi ree ti wọn fi ranṣẹ pe awọn to wa ni Asaba, to si ni aṣọ ko bọmọye mọ knigba ti wọn yoo fi de lẹyin bii wakati meloo kan.

"Eeyan mẹrin ni ina epo naa pa, pẹlu ẹnikan ti waya ina to ja lulẹ pa, gbogbo wọn jẹ marun-un."

Arakunrin kan naa toun naa wa nibi iṣẹlẹ oun jẹ ko di mimọ pe oun lọ gba owo ni banki ni, ko to di pe oun bẹrẹ sii gbọ ariwo ina.

"Mo lọ si banki lati gba owo ni, lojiji ni mo bẹrẹ sii gbọ ariwo. Igba ti maa fi wo nnkan to ṣẹlẹ ni mo rii pe tirela agbepo lo ṣubu, disu ni tirela naa gbe.

"Bi mo ṣe jade, ni mo ri ina, ti mo si sare gba ẹyinkule banki naa lati sa asala fun ẹmi mi. Gbogbo eeyan lo bẹrẹ sii pariwo ina. A ṣaa gbiyanju lati pe awọn ileeṣẹ pannapanna.

"Ẹnikan to dun mi fun julọ ninu awọn to padanu ẹmi wọn ni ọmọbinrin kan ti ori ti ko yọ, ṣugbọn to tun pada lati gba foonu rẹ, ṣugbọn ti ina naa mu, to si jo o pa.

"Lotitọ lawọn ileeṣẹ pannapanna wa, wọn gbiyanju agbara wọn, ṣugbọn ẹpa ko boro mọ pẹlu awọn dukia to ti bajẹ, ti wọn si ti ṣofo."