Lẹ́yìn ìfipábánilòpọ̀ márùn-ún tó kojú, Iyabo Ojo ní òun kò ní í sinmi ogun pẹ̀lú àwọn afipábánilòpọ̀

Gbajumọ oṣere, Iyabo Ojo

Oríṣun àwòrán, Iyabo Ojo/Instgram

Àkọlé àwòrán, Oṣere ilẹ wa, Iyabo Ojo.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gbajumọ oṣere ilẹ wa, Iyabo Ojo, ti ni oun ko ni i sinmi ogun pẹlu ẹnikẹni to ba fipa ba obinrin lo pọ, koda ko jẹ ọmọ oun ọkunrin ni.

Iyabo Ojo tawọn eeyan tun mọ si Queen Mother, sọrọ yii lori eto kan ta a mọ si Talk to B, nibi to ti sọ pe ẹẹmarun-un ọtọọtọ ni awọn ọkunrin kan ti fipa ba oun lo pọ ri.

Oṣere naa sọ pe oun ko le tọrọ aforiji nipa jija fun awọn obinrin ti ọkunrin ba fipa ba ṣere ifẹ.

Bakan naa lo ṣalaye pe oun ko faaye gba iṣẹlẹ radarada bẹẹ rara ni.

O ni ni 2025 yii, 'carry go' pẹlu ogun ni fun awọn afipabanilopọ .

Ta a ni Iyabọ Ojo?

Iyabo Ojo

Oríṣun àwòrán, Iyabo Ojo/ Instagram

Àkọlé àwòrán, Iyabo Ojo

Ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kejila ọdun 1977 ni wọn bi Iyabo Ojo.

Ọdun 1998 ni Iyabo Ojo sọ pe oun bẹrẹ iṣẹ tiata, ti Foluke Daramola si jẹ ọrẹ oun akọkọ lagbo oṣere.

Gẹgẹ bo ṣe wi, ọdọ iya rẹ agba to jẹ apa kan Delta ati Igbo lo gbe titi.

Iyabo sọ pe oun ti pe ọmọ ọdun meje koun too da mama to bi oun gan-an mọ.

Iyabo Ojo bi ọmọ meji, Prisilia ati Festus. O pẹ to ti n da awọn ọmọ naa tọ lẹyin ipinya pẹlu baba wọn.

Bo tilẹ jẹ pe Iyabo Ojo ti n ṣe tiata tipẹ to si ti di gbajumọ, sibẹ, ipa to ko ninu ọrọ Baba Ijesa, oṣere ilẹ wa ti wọn fẹsun kan pe o ba ọmọde lo pọ lo tubọ gbe Iyabo Ojo saye si i.

Tẹ o ba gbagbe, Olanrewaju Omiyinka ti gbogbo eeyan mọ si Baba Ijesa, bẹrẹ si i jẹjọ ifipaba ọmọde lo pọ ni ọdun 2021.

Obinrin adẹrin-in-poṣonu tawọn eeyan mọ si Princess, lo fi ẹsun naa kan Baba Ijesa, nigba to ni ẹrọ ayaworan ya oṣere naa nibi to ti n ba ọmọdebinrin kan to n gbe lọdọ oun ṣe ere ti ko yẹ.

Ọrọ naa di ariwo, Iyabo Ojo si taku pe Baba Ijesa yoo jiya ẹṣẹ rẹ.

O ni oun ko kọ lati ta ile oun lati ri i pe oṣerekunrin naa ṣe ẹwọn labẹ ofin.

Iṣẹlẹ yii pada gbe Baba Ijesa de ẹwọn, nibi to ti n fi aṣọ penpe roko ọba lọwọ.