Àwọn olólùfẹ Oriyomi Hamzat sọ̀rọ̀ láti UK àti Canada

Oriyomi Hamzat

Oríṣun àwòrán, Oriyomi Hamzat/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awọn ọmọ ẹgbẹ alatilẹyin gbajugbaja sọrọsọrọ ilẹ Ibadan nni, Oriyomi Hamzat ti rawọ ẹbẹ sijọba Naijiria lori iṣẹlẹ to gbe e de ọgba ẹwọn ninu oṣu Kejila, ọdun to kọja.

Awọn ọmọ ẹgbẹ naa ti wọn pe ara wọn ni Oriyomi Hamzat USA & Canada Fam ninu atẹjade ti wọn fi ranṣẹ lọjọ kẹrin, oṣu Kinni, ọdun 2025 ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe digbi lawọn wa lẹyin ọkunrin naa.

Oriyomi Hamzat pẹlu Olori Naomi Ogunseyi to jẹ olori ana laafin Ọọni Ile-Ifẹ ati Ọgbẹni Fasasi Abdullah toun jẹ ọga ile-ẹkọ girama ti Islam ni wọn n jẹjọ lori ẹsun to nii ṣe pẹlu iku awọn ọmọde marundinlogoji to ṣẹlẹ n'Ibadan lọjọ kejidinlogun, oṣu Kejila, ọdun 2024.

Ninu atẹjade ọhun ni wọn ti ba gbogbo mọlẹbi to padanu awọn ọmọ wọn lọjọ naa kẹdun, bẹẹ ni wọn tun gbadura ilera to peye fawọn to ṣi n gba itọju lọwọ nile iwosan.

"Adanu nla to ni ipa ni iṣẹlẹ naa jẹ fun wa; a gba a ladura pe Ọlọrun ninu aanu rẹ yoo tẹ awọn to padanu ẹmi wọn naa si afẹfẹ rere," atẹjade ọhun sọ bẹẹ.

"Ọlọrun yoo fun awọn mọlẹbi to padanu awọn eeyan wọn lọkan lati gbagbe. Bẹẹ la n fẹ ki ilera pipe jẹ ti awọn to ṣi n gba itọju lọwọ nileewosan.

"A fẹẹ fi idupẹ wa han si gbogbo eeyan fun ifẹ ti ẹ ni ati awọn adura yin fun Alaaji Oriyomi Hamzat, eyi ti ẹ ṣe laipẹ yii nibi iwọde alaafia ti ẹ ṣe lati le jẹ ki wọn tu Alaaji Oriyomi Hamzat ati awọn yooku to wa lahamọ silẹ.

"Awa ọmọ ẹgbẹ Oriyomi Hamzat USA and Canada fam ti n woye bi nnkan ṣe n lọ lori iṣẹlẹ to n kọni lominu naa, bẹẹ la si fẹ ki awọn alakoso mọ pe awa naa mọ idi to ṣe ṣe pataki lati gbe igbesẹ to yẹ.

"Sibẹsibẹ, a wa n rawọ ẹbẹ si awọn alakoso tọrọ naa kan lati fi oju aanu wo ẹjọ naa to nii ṣe pẹlu Alaaji Oriyomi Hamzat, Wolii Silekunola Naomi ati Ọgbẹni Fasasi Abdullah nigba ti iwadii kikun ba n lọ.

"Awa gẹgẹ bi ẹka kan ninu ọmọ ẹgbẹ Oriyomi Hamzat fam nigbagbọ pe ọkunrin n fẹ rere fun awọn eeyan ni, ohun to si ṣẹlẹ kii ṣe eyi ti wọn mọn-ọn-mọ ṣe. O jẹ ẹnikan to n ja fun ẹtọ awọn ọmọde ati awọn alaini lawujọ wa," atẹjade ọhun ṣalaye.

Lafikun, wọn wa rawọ ẹbẹ si gbogbo awọn ololufẹ agba sọrọsọrọ naa lati duro ṣinṣin, ki wọn si maa gbadura fun itusilẹ rẹ pẹlu awọn yooku ti wọn jọ n jẹjọ lọwọ.

Ki lo ṣẹlẹ sẹyin

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Onidajọ Olabisi Ogunkanmi ti ile-ẹjọ Majisireeti to wa ni Iyaganku nilu Ibadan, ipinlẹ Oyo lo paṣẹ pe ki wọn fi Olori Ọọni Ile-Ifẹ tẹlẹ, Naomi Silekunola, Oriyomi Hamzat to jẹ alakoso agba fun ileeṣẹ redio kan nilu Ibadan pamọ si atimọle lọgba ẹwọn.

Adajọ naa tun sọ pe ki ọga agba nileẹkọ girama ti Islamic High School to wa lagbegbe Bashorun, Ibadan naa tẹle wọn lọ.

Ọgba ẹwọn Agodi to wa nipinlẹ Ọyọ ni adajọ naa sọ pe ki awọn afurasi naa ti lọ maa gbatẹgun titi di igba ti wọn yoo fi tun gbọ ẹjọ wọn.

O kere tan, ọmọde marunlelọgbọn lo ku, ti ọpọ si farapa, nibi apejẹ ti olori Ooni Ile-Ife tẹlẹ, Naomi Ogunwusi, ṣe niluu Ibadan.

Ọjọru, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kejila, ọdun 2024, ni eto naa yẹ ko waye, amọ gbogbo rẹ foriṣanpọn nitori ohun to ṣẹlẹ

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ fun BBC Yoruba pe ko tii pẹ ti eto bẹrẹ, ti awọn eeyan fi bẹrẹ si ni tẹ ara wọn.

Igba akọkọ kọ ree ti Olori Naomi Silekunola Ogunwusi ṣe eto apejẹ naa.

Ọdọọdun lo maa n ṣe e labẹ ajọ ẹlẹyinju aanu rẹ to pe ni, Women in Need of Guidance and Support (WINGS).