Èyí ni àwọn aburú tó wà nínú kí èèyàn máa han oorun

Oríṣun àwòrán, Getty image
Bi oorun ba wọra tan, mímí awọn ẹlomi-in maa n mu ariwo dani, eyi ni a n pe ni ki eeyan maa han oorun.
Ọpọ igba lo jẹ pe ẹni to n han'run ki i mọ, ṣugbọn ẹni ti wọn ba sun ti ni inira yoo ba, nigba ti ariwo ẹni to n han'run ko ba jẹ ko reti gbọrọ debi ti yoo le sun ni tirẹ.
"Bi emi atawọn mọlẹbi ati ọrẹ mi ba wa papọ, mo maa n fi bi ọkọ mi ṣe maa n han oorun ṣawada laaarin wọn. Ṣugbọn ninu mi lọhun-un, ohun to maa n ko ironu nla ba mi mi"
Obinrin kan, Arunika Selvam; ẹni ọdun marundinlaadọta to wa lati Singapore lo sọrọ yii nipa ọkọ to fẹ.
"Mo maa n sọ pe mo le ba ọkọ mi sọrọ lori ẹ la i mu ija wa, ti ko ni i binu si mi."
''Ṣugbọn ọpọ igba ni mi o ki n le sun, ti mo maa ji laaarin oru, oju mi yoo si wu fun aisun nigba tilẹ ba mọ".
Arunika lo ṣalaye bẹẹ fun BBC.
Obinrin naa fi kun un pe aile sun loru nitori oorun ti ọkọ oun maa n han, n ṣakoba fun iṣẹ oun pẹlu, nigba to jẹ oun ko sun loru, ọsan loorun naa yoo maa kun oun, eyi to le pa iṣẹ lara.
Ni ibẹrẹ ifẹ, awọn eeyan maa n foju fo o bi ololufẹ wọn ba n han'run, wọn yoo sọ pe nnkan kekere tawọn yoo ṣẹgun rẹ ni.
Ṣugbọn awọn onimọ nipa ilera ko yee ṣe ikilọ, pe ki wọn ro o daadaa, nitori olufẹ to n han oorun le pada di nnkan ti yoo ṣakoba fun ajọṣepọ, to si le fa ki ẹnikeji rẹ ma foju kan oorun nitori ariwo oorun ti ololufẹ rẹ n han.
Ki ni a n pe ni ki eemi duro ko si tun bẹrẹ pada nigba ti eeyan ba n sun lọwọ(sleep apnoea?)

Oríṣun àwòrán, Getty image
Bi eeyan ba n han'run to n pariwo gidi, o ni i ṣe pẹlu ohun ti a mọ si aisan kan ti wọn n pe ni 'Obstructive Sleep Apnoea' (OSA).
Eyi ni ipo kan ti eeyan maa n wa loju oorun, ti eemi rẹ yoo duro lojiji ti yoo si tun bẹrẹ pada, gẹgẹ bi awọn dokita ṣe ṣalaye.
Wọn ṣalaye pe aisan yii maa n jẹ ki ọna ọfun eeyan kere.
Ti eyi ba ṣẹlẹ, yoo di eemi to ja geere lọwọ.
Gẹgẹ bi Dokita Ramamurthy Sathyamurthy, onimọ nipa eemi eeyan nile ẹkọṣẹ iṣẹgun James Cook University, ni UK ṣe ṣalaye, o ni aimọye apẹẹrẹ ni OSA yii maa n mu wa.
O ni awọn mi-in mọ niwọn, awọn kan si wa to yẹ keeyan tori wọn ṣe akiyesi, nitori to ba pẹ, o maa n buru si i ni.
Bi eeyan ba waa n han'run ti ko si tọju rẹ, wọn ni o ṣee ṣe ko ṣe akoba fun ẹni to n han oorun naa ati ẹnikeji rẹ ti wọn jọ n sun.
Awọn ọna akoba naa yoo fara han nipa irisi wọn nigba ti wọn ko ba sun to, nipa ironu ati ibalopọ wọn.
Ki ni awọn apẹẹrẹ ki eemi maa se loju oorun?

Oríṣun àwòrán, Getty image
Nigba ti eeyan ba sun ni awọn apẹẹrẹ yii maa n foju han:
*Ki eeyan maa han oorun, ki ohun rẹ si maa lọ soke lala.
*Ki eemi maa duro ko si tun bẹrẹ pada.
*Ki eeyan maa ṣe bii ẹni ti eemi rẹ ti gunke tabi ko maa ṣe bii ẹni ti ko le mi daadaa loju oorun.
*Ki eeyan maa taji loore-koore lati oju oorun.
Loju ọsan, ẹni to ba n koju iṣoro yii yoo maa ni:
*Ẹfọri nigba ti wọn ba ji.
* Yoo rẹ wọn gan-an bii ẹni to ṣiṣẹ loju oorun ni nigba ti wọn ba ji.
*Wọn ki i tete le pe ara wọn bọ bi wọn ba ji saye.
*Wọn maa n gbagbe nnkan.
*Wọn yoo jọ ẹni to ni ibanujẹ ọkan, ara si le maa kan wọn.
*Ibalopọ yoo run si wọn.
Awọn ailera miran ti wọn tun le koju
ni aile mi daadaa. Eyi ri bẹẹ latari bi atẹgun to n gbe eemi jade (oxygen) ṣe n ja walẹ.
Awọn dokita sọ pe o le fa awọn ailera mi-in si agọ ara pẹlu.
Awọn iṣẹ iwadii kan sọ pe OSA le fa ki ọkan eeyan ṣiṣẹ gba ọna odi, wọn ni o le lekun ni ida ojilelọgọrun-un (140%).
Wọn lo le fa rọpa-rọsẹ ni ida ọgọta (60%), o si le fa aisan ọkan ni ida ogbọn (30%).
Eeyan le ma nifẹẹ ibalopọ mọ.
Dokita Sathyamurthy sọ pe ida aadọrun-un (90%) awọn tọkọtaya to n wa sọdọ oun lo jẹ pe bi ọkọ tabi iyawo wọn ṣe n han'run n daamu aye wọn.
O ni o le mu ki lọkọ-laya maa sun ni yara ọtọọtọ paapaa, eyi ti awọn oloyinbo n pe ni 'sleep divorce).
Ai sun papọ yii le pada di ohun ti yoo mu ipinya gangan wa lọjọ iwaju bo ṣe sọ.
Bawo lo ṣe fẹẹ gbe e kalẹ fun ololufẹ to n han'run?
Bo tilẹ jẹ pe Abilekọ Arunika Selvam n gbe ni Singapore, nibi ti ọrọ aje ti duro deede ti nnkan si daa, sibẹ, ko rọrun fun un lati ṣe ibusun mi-in ti yoo maa da sun.
" A ti fi yara igbalejo wa rẹnti ka le baa ri owo naa gbọ bukaata mi-in, nitori nnkan wọn pupọ lati ra ni Singapore yii."
Arunika to ti ṣegbeyawo lati ọdun mẹẹẹdogun sẹyin, to si bimọ ẹyọkan lo ṣalaye bẹẹ.
O ni ṣugbọn nigba ti oun ki i sun nitori ọkọ oun to n han'run, oun pe e jokoo, oun si ba a sọrọ nipa iṣoro to n ko oun si naa.
O ni ọkọ oun ko kọkọ feẹ lọ sile iwosan nitori iṣoro naa, o ni kinni kan ko ṣe oun, nitori ajẹbi ni keeyan maa han oorun jẹ nile awọn.
Ọkọ Arunka sọ fun un pe baba to bi oun ati baba-baba oun naa maa n han'run, nitori naa, ko sohun to buru nibẹ, alaafia ni keeyan maa han'run.
Igbagbọ awọn eeyan mi-in naa ree, wọn maa n sọ pe ọkunrin to ba to ọkunrin lo maa n han'run.
Ninu amọran rẹ, onimọ nipa iṣoro yii, Sara Nasserzadeh, sọ pe ti eeyan ba fẹẹ ba ololufẹ rẹ sọrọ nipa bo ṣe n han'run, o ṣe pataki lati mọ iru asiko ti eeyan yoo gbe e kalẹ.
"O le jẹ lẹyin ibalopọ, abi nigba ti ẹyin mejeeji n ba ara yin sọrọ ti ẹ si n ṣere''" Nasserzadeh lo ṣalaye bẹẹ.
O fi kun un pe ki i ṣe pe o dun mọ ẹni to n han'run naa lati maa ṣe bẹẹ.
O ni o maa ti n wọn loju bi eeyan ba sọ fun wọn nipa bi won ṣe n han'run to si n di ara yoku lọwọ.
Ewu to wa ninu ki eeyan maa han'run

Oríṣun àwòrán, Getty image
Gẹgẹ bi ẹgbẹ to n ri si ki eeyan maa han'run ni UK, iyẹn British Snoring and Sleep Apnoea Association, ṣe sọ, wọn ni o to miliọnu mẹẹẹdogun eeyan to n han'run ni UK.
Wọn fi kun un pe eyi n pa eeyan miliọnu lọna ọgbọn (30m) lara.
Wọn fi kun un pe iwadii fidi ẹ mulẹ, pe awọn ọkunrin lo n hanrun ju obinrin lọ.
Won ni ki eeyan maa han'run wa lara idi pataki ti igbeyawo fi n tuka ni UK, bo tilẹ jẹ pe o ṣoro lati fidi ẹri yii mulẹ.
Rita Gupta, lọọya mọlẹbi ni UK, ṣalaye pe ileeṣẹ oun ti ri oriṣiiriṣii ikọsilẹ, to si jẹ pe bi ololufẹ ṣe n han'run lo fa a.
"Mo ti gbọ ti ọpọ eeyan maa n sọ pe awọn ti n sun si yara ọtọ fun ọpọ ọdun tipẹ, nitori bi ololufẹ wọn ṣe n han'run, a si pada kọ ara wa silẹ." Rita Gupta lo ṣalaye bẹẹ.
O ni ai ka nnkan kun, ai gba itọju lori ailera yii lo n fa a ti ololufẹ fi n tori ẹ kọ ara wọn silẹ
Ohun ti o le ṣe nipa bi o ṣe n han'run

Oríṣun àwòrán, Getty image
Ọna abayọ si iṣoro yii wa labẹ awọn nnkan wọnyi:
Didin ara sisan ku.
Didẹkun siga mimu.
Didin ọti mimu ku.
Ṣugbọn fun ọpọ eeyan, irinṣẹ kan ti a mọ si 'CPAP' (Continuous positive airway pressure) lo ṣe pataki.
Irinṣẹ yii maa n fi eemi sinu iboju kan ti eeyan yoo wọ simu to ba fẹẹ sun, eeyan si le wọ ọ si ẹnu naa.
Dokita Ramamurthy Sathyamurthy ṣalaye pe o daa lati mu ẹmi ẹni to n han'run ni koko, ati ti ẹni ti wọn jọ n sun naa.
O gba wọn nimọran lati maa lọ si ọdọ dokita bo ṣe yẹ, fun amọran.
Eyi yoo ran ibaṣepọ lọkọlaya lọwọ, yoo si tun din owo ti wọn yoo maa na lori oogun ku, latari awọn aisan mi-in to le ti ara oorun hihan yii wa.''












