Kí ló fa gbas-gbos láàárín Obasanjo àti NNPCL?

Olusegun Obasanjo àti ọ̀gá NNPCL Kolo Mele Kyari

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Láìpẹ́ yìí ni iléeṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ epo bẹntiróòlù ní Nàìjíríà kéde pé iléeṣẹ́ ìfọpo rọ̀bì ìlú Warri, ìpínlẹ̀ Delta ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ padà lẹ́yìn tó ti dẹnu kọlẹ̀ fún bí ọdún márùn-ún.

Iléeṣẹ́ ìfọpo Warri yìí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lẹ́yìn oṣù díẹ̀ tí iléeṣẹ́ ìfọpo ti Port Harcourt náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́

Àwọn àtúnṣe yìí, gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ NNPCL, Mele Kyari ṣe sọ fún BBC, yóò mú ìrọ̀rùn bá ẹ̀ka epo Nàìjíríà.

Kódà Ààrẹ Nàìjíríà, Bola Tinubu náà kan sáárá sí NNPCL fún àṣeyọrí wọn lórí àwọn iléeṣẹ́ náà.

Àmọ́ ọ̀rọ̀ iléeṣẹ́ náà dá awuyewuye sílẹ̀, tí àwọn kan ṣe ní àwọn kò gbàgbọ́ pé NNPCL le ṣe àwọn àṣeyọrí yìí.

Ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí ní Nàìjíríà, Olusegun Obasanjo nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tó ṣe pẹ̀lú Channels TV pé òun kò gbàgbọ́ nínú àṣeyọrí tí NNPCL ní àwọn ṣe.

Ọ̀rọ̀ yìí kò tẹ́ iléeṣẹ́ NNPCL lọ́rùn, èyí tó mú kí Kyari ní kí Obasanjo ṣe àbẹ̀wò sí iléeṣẹ́ náà láti fi ojú ara rẹ̀ rí nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀.

Kí ni Obasanjo sọ?

Olusegun Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Olusegun Obasanjo

Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà, Obasanjo sọ pé òun gbìyànjú láti ṣe àtúnṣe àwọn iléeṣẹ́ ìfọpo mẹ́ta- ti Kaduna, Port Harcourt àti Warri- lásìkò ìṣèjọba òun.

Ó ní òun sọ fún iléeṣẹ́ Shell láti gba àkóso àwọn iléeṣẹ́ ìfọpo ọ̀hún nígbà náà àmọ́ tí wọ́n kọ̀, pé àwọn kò lè ṣe àmójútó wọn.

Obasanjo ṣàlàyé pé àwọn alakoso Shell nígbà náà sọ fún òun pé iye epo táwọn iléeṣẹ́ náà ń fọ̀ kéré sí nǹkan tí àwọn le ṣe àmójútó lọ àti pé ìwà àjẹbánu tó wà lẹ́ka epo ní Nàìjíríà pọ̀ púpọ̀, tí àwọn kò sì fẹ́ lọ́wọ́ nínú rẹ̀.

Ó ṣàlàyé pé lẹ́yìn náà ni òun sọ fún Aliko Dangote láti gbé ìgbìmọ̀ kan dìde lórí àwọn ilé ìfọpo náà.

"Dangote ṣe èyí tí yóò máa jẹ́ àjọṣepọ̀ láàárín ìjọba àti ẹ̀ka aládàni, tí wọ́n sì san $750m láti fi máa ṣe àkóso àwọn iléeṣẹ́ náà.

"Ẹ̀wẹ̀, ẹni tó gba ipò Ààrẹ lẹ́yìn mi dá owó náà padà fún Dangote, pé NNPCL sọ pé àwọn le ṣe àkóso àwọn ilé ìfọpo náà.

"Mo gbọ́ pé bílíọ̀nù méjì dọ́là ni wọ́n ti ná sáwọn iléeṣẹ́ ìfọpo náà, tí kò sì ní ṣiṣẹ́."

Ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí náà parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé irọ́ lásán ni NNPCL ń pa.

Èsì NNPCL

Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ Obasanjo yìí ni NNPCL fi àtẹ̀jáde kan léde pé àwọn ń fẹ́ kí àárẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí náà wá ṣe àbẹ̀wò sí àwọn iléeṣẹ́ ìfọpo náà láti wo àwọn àtúnṣe tó ti wáyé níbẹ̀.

Àtẹ̀jáde kan tí agbenusọ NNPCL, Olufemi Soneye fi léde ní àwọn ń pe Obasanjo láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn láti máa pèsè ohun àmúṣagbára tó tó fáwọn aráàlú.

Soneye ní àwọn ti ṣetán láti gba gbogbo ìmọ̀ràn tó bá ní fún àwọn.

Àwòrán lásìkò tí wọ́n ń ṣí iléeṣẹ́ ìfọpo Warri

Oríṣun àwòrán, X/NNPCL

Obasanjo bu ẹnu àtẹ́ lu ìpè NNPCL

Ẹ̀wẹ̀, Obasanjo ní ìpè àbùkù ni NNPCL pé òun, pé ó tàbùkù irú èèyàn tí òun jẹ́ àti ipò òun.

Agbẹnusọ Obasanjo, Kehinde Akinyemi ní NNPCL kò fi ìwé pé òun tó sì ní kò tọ̀nà láti máa ránṣẹ́ pe Ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí lórí ayélujára.

Ó ní ìwà àbùkù gbá à ni àti pé Obasanjo kò ní fèsì sí wọn.