Ọba alayé tí àwọn jàǹdùkú lù l'Osun, bó ṣe jẹ́ gan-an rèé

Aworan awọn eeyan ati aafin ti wọn bajẹ.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ni ọjọ Ẹti, ọjọ kẹta, oṣu Kin-in-ni ọdun 2025, lakoko ti awọn Musulumi n kirun Jimọ ni awọn ọdọ ti wọn ko niye, lu Ọba Yusuf Jelili Olaiya, Ajẹniju ti ilu Halleluyah, nipinlẹ Osun.

Ohun to fa idi ikọlu si ọba alaye naa gẹgẹ ba a ṣe gbọ ni pe, Ọba Ọlaiya fi ọkunrin kan, Ahmed Tijani, jẹ Imaamu Agba fun ilu Ajẹniju lọsẹ to kọja.

Tẹ o ba gbagbe, kete ti Olojudo ana, Ọba Aderẹmi Adedapọ, waja ni awọn ọmọbibi ilu naa ti fẹsun kan Timi Ẹdẹ, Ọba Munirudeen Lawal, pe o fẹẹ fi ẹnikan jọba lagbegbe kan to wa lori ilẹ Ido-Ọṣun.

Wọn kọ oniruuru iwe ifisun si ileeṣẹ ọlọpaa atijọba ipinlẹ Ọṣun naa, ṣugbọn lẹyin o rẹyin, ijọba fun Ọba Ọlaiya ni ọpa aṣẹ, wọn si sọ ọ di Ajẹniju ti Halleluyah, niluu Ẹdẹ, nipinlẹ Ọṣun.

Latigba naa ni ara ko ti rọ okun, ti ara ko rọ adiyẹ, ohun ti awọn ọmọ Ido Ọṣun n sọ ni pe, nigbawo ni ilu Ẹdẹ de abẹ ijọba ibilẹ Ẹgbẹdọrẹ.

Eyi ni o ṣe jẹ kayeefi fun awọn eeyan nigba ti wọn tun gbọ pe Ọba Ọlaiya tun fi ẹnikan jẹ Imaamu Agba.

Idi eyi ni wọn fi gbera lati fi ẹhonu han lasiko ti wọn fẹẹ kirun Jimọ, nigba naa ni awọn kan yari fun un ọba naa pe ori ilẹ Ido-Ọṣun ni Ajẹniju wa.

Ọrọ yii ni wọn n fa mọ ara wọn lọwọ ti wahala fi bẹ silẹ, wọn da gbogbo mọṣalaaṣi ru, wọn si fi iya jẹ Kabiyesi laafin rẹ naa.

Ọlọpaa Osun fidi iṣẹlẹ naa mulẹ

Bakan naa ni BBC News Yoruba, kan si agbenusọ fun gomina ipinlẹ Osun, Olawale Rasheed lori Isẹlẹ naa.

Olawale fidi Isẹlẹ naa mulẹ, o ni loootọ ni pe awọn ọdọ kan lati ilu Ido-Osun fiya jẹ Ọba Yusuf Jelili Olaiya lori bi o se fẹ kọ aafin sori ilẹ Ido-Osun.

O tẹsiwaju pe loootọ ni pe Ido-Osun lo ni ibi ti Ọba Yusuf Jelili Olaiya fẹẹ kọ aafin Halleluyah si.

O ni ọrọ naa ti de eti ijọba atawọn ọlọpaa, saaju ki ikọlu naa too waye.

O ni Gomina Adeleke ti pe ọga ọlọpaa Osun, wọn si ti ko awọn agbofinro si agbegbe naa ti iwadii yoo fi pari.

Alukoro ọlọpaa Osun, Yemisi Opalola ṣalaye pe iyalẹnu lo jẹ pe iru isẹlẹ yii sẹlẹ lasiko yii.

A gbọ pe ọwọ ọlọpaa ti tẹ mẹrin ninu awọn to ṣe ikọlu naa, ara Ọba Yusuf Jelili naa si n ti ya nile iwosan to wa.

Gbogbo akitiyan akọroyin lati gbọ ọrọ lẹnu Ọba Yusuf Jelili ko so eso rere, pẹlu bi awọn osisẹ ile iwosan naa ko ṣe fi aaye silẹ lati ri i.

Àwọn jàǹdùkú lu ọba alayé lálùbami l'Osun nítorí ọ̀rọ̀ oyè Imaam

Aworan awon janduku kan

Oríṣun àwòrán, others

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Niṣe lọrọ di bi o ko lẹ ki o yago lọna lọjọ Ẹti, ọjọ kẹta, oṣu Kinni, ọdun ti a wa yii nigba ti wọn sọ pe awọn tọọgi yabo mọṣalaṣi kan to wa lagbegbe Hallelujay, ijọba ibilẹ Egbodore nipinlẹ Osun, ti wọn si lu Ọba tuntun to ṣẹṣẹ jẹ lalubami.

Ko si nnkan meji ti wọn lo fa bawọn tọọgi ṣe lu ọba naa, Ọba Jelili Olaiya ti wọn ni ko pẹ to gba ade, bi ko ṣe bo ṣe lọ yan Imaamu agba fun mọṣalaṣi adugbo naa.

Asiko ti wọn n kirun jumaati lọwọ la gbọ pe awọn ọdọ agbegbe naa yawọ mọṣalaṣi pẹlu ẹgba, ti wọn si lu Ọba Olaiya pẹlu awọn to wa nibẹ nilukulu.

Inu oṣu Kẹjọ, ọdun to kọja la gbọ pe Timi tiluu Ede, Ọba Oba Munirudeen Lawal gbe ade le Ọba Yusuf Jelili Olaiya, Ademola akọkọ lori gẹgẹ bi Ajeniju tiluu Hallelujah, bo tilẹ jẹ wọn ni ko dun mọ awọn ara agbegbe Ido-Osun ninu.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ọsẹ to kọja ni wọn sọ pe Ọba Olaiya we lawaani oye Imaamu agba fun ẹnikan ti wọn pe ni Ahmad Tijjani, ẹni ti wọn lawọn eeyan ko gba tiẹ.

Ọrọ ipo Imaamu naa lo di wahala, ti wọn lawọn kan sọ pe awọn ko le gba ki Tijjani di olori ẹsin lagbegbe naa.

Latigba naa ni wọn lawọn kan ti ko ara wọn jọ, ti wọn si n duro de ọjọ ti wọn yoo kona iya fun Kabiyesi naa ati Imaamu to yan.

Wọn ni bo ṣe di agogo kan ọsan kọja, lawọn ọdọ kan lati Ido-Osun ko ara wọn jọ, ti wọn si yabo mọṣalaṣi to wa ninu aafin kabiyesi lasiko ti wọn n kirun lọwọ.

Alubami ni wọn lu kabiyesi naa, ati gbogbo awọn to wa ninu mọṣalaṣi lọjọ naa, ti wọn si n beere lọwọ kabiyesi nipa aṣẹ to ni lati yan Imaamu agba fawọn.

Ohun ti wọn lawọn kan n sọ ni pe kabiyesi ko laṣẹ lati yan Imaamu agba si agbegbe ti ọba miran n ṣakoso rẹ.

Yatọ si pe wọn lu Ọba Olaiya laludojubolẹ, wọn tun ba dukia ile rẹ jẹ.

Lara awọn ara agbegbe naa ni wọn ranṣẹ sawọn agbofinro, ti wọn si lawọn agbofinro naa lo gba kabiyesi silẹ lọwọ wọn.

Ọkan lara awọn to bawọn akọroyin sọrọ, ẹni to kọ lati darukọ ara rẹ ṣalaye pe awọn ọdọ naa ko fẹ ki Kabiyesi yan Imaamu agba fun wọn, nitori pe kii ṣe ọba naa lo n ṣakoso agbegbe ọhun.

Ẹni naa jẹ ko di mimọ pe iwọde ni awọn ọdọ naa ṣe lati fẹhonuhan wọn han, ṣugbọn to pada di iṣu-ata-yan-an-yan-an nigbẹyin.

Gomina Adeleke sọrọ

Gomina Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, Gov Ademola Adeleke/X

Gomina Ademola Adeleke tipinlẹ naa, nigba to n sọrọ, jẹ ko di mimọ pe oun yoo fi ọwọ ofin mu iṣẹlẹ naa, ati pe awọn ko le laju silẹ ki wọn maa tapa si ori ade.

Adeleke ninu atẹjade ti agbẹnusọ rẹ, Olawale Rasheed fi sita lo ti sọ pe oun ti paṣẹ fawọn agbofinro lati ṣewadii iṣẹlẹ naa, ati pe ọwọ gbọdọ tẹ gbogbo awọn to lọwọ si bi wọn ṣe lu ori ade lalubami, ti wọn si tun dana sun aafin rẹ.

Bakan naa ni gomina tun ṣe ikilọ fun Olojudo tiluu Ido-Osun, Oba Olayinka Oyetunde Ishola lati tọwọ ọmọ rẹ bọ aṣọ, ko si dẹkun lati maa lo awọn ọdọ nilokulo lati da ilu ru.

Siwaju sii ni Gomina Adeleke paṣẹ fun Kọmiṣanna to n ri seto ijọba ibilẹ ati oye jijẹ nipinlẹ naa, Ọnarebu Dosu Babatunde lati gbe igbesẹ bi yoo ṣe pẹtu sawọn ilu mejeeji naa ninu, ki wọn si wa ọna abayọ sohun to n fa aawọ laarin wọn.

"A ko ni faaye gba lilo iwa ipa lati maa fi yanju aawọ, ati pe gbogbo awọn tọwọ ba tẹ lori iṣẹlẹ yii yoo foju winna ofin." Adeleke sọ ninu atẹjade naa.

"Yatọ si awọn ileeṣẹ agbofinro, mo tun ti dari Kọmiṣanna feto ijọba ibilẹ ati oye jijẹ, Ọnarebu Dosu Babatunde lati gbe igbesẹ alaafia ti yoo pana aawọ naa, ni iranlọwọ pẹlu awọn ileeṣẹ eleto aabo.

"Agbegbe ti ohunkohun ko ba ti tẹ lọrun ni anfaani lati yọju si ileeṣẹ ijọba tọrọ naa ba kan lati fi to wọn leti fun alaafia lati jọba. A ko nii gba oniruuru iwa ipa laaye labẹ bo ti wu ko ri," Adeleke kadi ọrọ rẹ.