Obìnrin Naijiria mẹ́ta gba òmìnira kúrò l'ẹ́wọ̀n ní Saudi

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn alaṣẹ lorilẹede Saudi Arabia ti tu awọn obinrin mẹta to jẹ ọmọ orilẹede Naijiria silẹ kuro ni ahamọ fun ẹsun gbigbe oogun oloro.
Oṣu mẹwaa ni awọn obinrin mẹta yii lo lọgba ẹwọn ko to di pe wọn gba itusilẹ
Ileeṣẹ ijọba to n risi ọrọ ilẹ okeere lorilẹede Naijiria lo gbe ikede naa sita ninu atẹjade ti wọn fi sọwọ si awọn akọroyin lojo Aje.
Ọjọ karun un, oṣu kẹta lọdun 2024 ni ọwọ tẹ awọn obinrin yii niluu Medina lorilẹede Saudi Arabia.
Gẹgẹ bii atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ ijọba naa, Kimiebi Imomotimi Ebienfa fi lede, Hadiza Abba, Fatima Umate Malah ati Fatima Kanner Gamboi ni ọwọ tẹ ni papakọ ọkọ ofurufu Ọmọọba Mohammad Abdul Azeez to wa niluu Medinah.
Gamboi ni, awọn agbofinro mu awọn obinrin mẹta nitori pe wọn ti mu eeyan meji to jẹ ọmọ orilẹede Naijiria saaju pẹlu ogun oloro.
Nigba to n tẹwọgba awọn obinrin mẹta naa, aṣoju Naijiria lorilẹede Saudi Arabia, Muazam Nayaya ni awọn ti bẹrẹ si ni ṣeto bi awọn obinrin naa yoo se pada si orilẹede Naijiria lati darapọ pẹlu awọn mọlẹbi wọn.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post











