Cash Madam, ogbóǹtarìgì oníṣòwò tí Ebenezer Obey kọrin kì ti jáde láyé

Aworan Cash Madam

Oríṣun àwòrán, others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ogbontarigi oniṣowo ati aṣaralẹṣọ nni, Arabinrin Khadijah Adebisi Edionseri ti ọpọ awọn eeyan kaakiri agbaye mọ si Cash Madam ti jade laye lẹni ọdun mọkandinlaadọdun-un.

Ọmọwe Adebayo Adebowale to jẹ ọkan lara awọn ọmọ mama naa lo kede iku rẹ ninu atẹjade to fi sita lọjọ Aiku to kọja, iyẹn ọjọ karun-un, oṣu Kinni, ọdun 2025.

Adebowale sọ pe iku maa wọn kii ṣe oku ọfọ, bi ko ṣe eyi ti awọn yoo maa fi dupẹ lọwọ Allah fun igbe aye to peregede ti mama naa gbe ko too ku.

Ọkan lara awọn oloye nla nipinle Ogun ni Cash Madam ko too ku, oun si ni Iya Sunnah ilu Ẹgba, Yewa ati ipinlẹ Ogun lapapọ.

Nigba to n kede, Adebowale sọ pe "Pẹlu ẹmi imoore si Allah fun igbe aye rere to gbe, a n kede ipapoda mama wa, mama-mama, mama-mama-mama, Ọmọọbabinrin Kadijat Abike Adebisi Edionseri (née Elegbede), ẹni to pada sọdọ Adẹda rẹ lọjọ karun-un, oṣu Kinni, ọdun 2025 lẹni ọdun mọkandinlaadọrun, lẹyin aisan rampẹ," Ọmọwe Adedayo sọ ninu atẹjade to fi sita.

"A ko le gbagbe rẹ titi lai, ṣe ti ẹrin, ikonimọra ati bo ṣe gbajumọ la fẹẹ sọ ni, tabi ti ọyaya rẹ, to fi mọ itọni ati ẹkọ iwa ọmọluabi ti wọn fi kọ wa.

"Eto isinku nilana musulumi yoo waye lọjọ Aje, ọjọ kẹfa, oṣi Kinni, ọdun 2025 ni ile rẹ to wa ni GRA, Abeokuta. Ki Allah dariji awọn aiṣedeede rẹ, ko si ba wa tẹ ẹ si afẹfẹ rere, ko si tun fun wa ni okun lasiko yii," Adebowale kọ ọ.

Odu ni Cash Madam, kii ṣaimọ foloko nigba aye rẹ, ẹni to jẹ gbajugbaja ninu ka ṣe ẹṣọ ara, koda titi to fi jade laye.

Bo ṣe gbajumọ daadaa nipinlẹ Ogun to fi ṣebugbe, bẹẹ naa lo gbajumọ kaakiri Naijiria ati awọn agbegbe kan lagbaye.

Gomina Abiodun kẹdun iku Cash Madam

Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiodun ti ṣapejuwe iku oloogbe naa gẹgẹ bi adanu nla fun gbogbo ipinlẹ naa, ati orileede Naijiria lapapọ.

Abiodun ni ipa rere ni mama naa ti n fi lelẹ bọ lati ọdun to ti pẹ sẹyin, to si tun jẹ ẹlẹyinju aanu titi dọjọ iku.

Ninu atẹjade ibanikẹdun ti Ọnarebu Kayọde Akinmade to jẹ oludamọran pataki fun gomina fi sita, o ni oniṣowo to yanranti, to si laamilaaka ni oloogbe naa.

"Lorukọ emi ati gbogbo ọmọ ipinlẹ Ogun, mo n ba idile Alaaja Oloye Adebisi Edionseri kẹdun. Adanu nla ni ipapoda naa jẹ, ṣugbọn ipa to ko lagboole okoowo ṣiṣẹ ati gbajumọ lawujọ yoo tubọ maa wa ni iranti ti ko ṣee gbagbe," Abiodun sọ bẹẹ.

"Aye ọpọ awọn eeyan ni mama naa da si, to si fi ipa rere lelẹ fun awọn iran to n bọ lọjọ iwaju."

Taani Edionseri?

Yatọ si pe oloogbe naa jẹ gbajugbaja nidi ka ṣe ara lẹṣọ, arẹwa, ka gbafẹ, bẹẹ lo tun n ṣe iranwọ fun tọmọde-tagba ko too ku.

Kii ṣe ahesọ tabi asọdun wi pe lati ọdun 70s ni mama naa ti ni owo tabua.

Oyinbo kan ti ọkọ oloogbe naa n ba ṣiṣẹ lọdun naa lọhun lo sọ Cash Madam di olowo rẹpẹtẹ.

Ni ọdun 2023 ti mama naa ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun mejidinlaadọrun, ọpọ eeyan lo wa nibẹ ti wọn n sọ gbogbo daadaa ti mama naa ti ṣe.

Titi to fi darugbo ni Oloogbe Edionseri fi n lọ ode ariya, to si maa n na owo loju agbo

Ogbotarigi olorin Juju nni, Oloye Ebenezer Obey Fabiyi lo fun mama naa ni inagijẹ Cash Madam ti gbogbo aye fi n pe e titi di oni

Bawo lo ṣe bẹrẹ to fi di olokiki?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọkọ oloogbe, Ganiyu Adebowale lo n ṣiṣẹ pẹlu Oyinbo kan to n jẹ John Holt lọdun 60s, nigba toun n ṣe okoowo keekeeke nigba naa.

John Holt yii lo beere lọwọ oloogbe pe oun ni iṣẹ kan fun un, ati pe ṣe o le maa ba wọn ta awọn ọja kan. Loju ẹsẹ ni mama yii sọ pe oun le maa ta wọn.

Oyinbo naa ko ọja diẹ fun Arabinrin Edionseri, to si ko o lọ sinu ọja Ogunpa to wa ni Ibadan lati ta wọn, ko pẹ rara to fi ta awọn ọja naa tan, to si da owo pada fun Holt.

Bo ṣe dẹni to n ra ọja naa ree, to si n ta wọn.

Ninu ifọrọwerọ ti Oloogbe Edionseri ṣe pẹlu akọroyin kan ninu oṣu Kinni, ọdun 2023, mama naa sọ pe nigba ti John Holt ri boun ṣe n ṣe daadaa, o ṣalaye fun ileeṣẹ UAC, ti wọn si pe e sibi ipade.

Ibi ipade naa ni wọn ti sọ ọ di onibara wọn.

Lẹyin eyi ni ileeṣẹ G.B. Olivant tun ranṣẹ pe oloogbe lati wa a di alagbata fun ileeṣẹ wọn.

Oloogbe sọ ninu ifọrọwerọ ọhun pe ileeṣẹ CFAO nilẹ Faranse tun ranṣẹ pe oun lati di alagbata, toun si n ṣe daadaa, ko to di pe wọn da oun pada siluu Ibadan.

Ile ifowopamọ Barclays to ti wa di Union Bank bayii lo maa n gbe owo ọja to ba ti ta lọ, apo ṣaka nla si lo ma fi n gbe owo lọ sibẹ nigba naa. Bayii lo ṣe di olowo rẹpẹtẹ, to si tun n ṣaanu.

Ọdun mẹrindinlogun sẹyin ni mama naa fi iṣẹ okoowo ṣiṣe silẹ, iyẹn nigba ti gbogbo ọmọ rẹ naa ti da duro, ti wọn si n ṣe daadaa laaye ti wọn wa.

Nibo ni orukọ 'Cash Madam' ti wa?

Awọn mẹta ọtọọtọ ni wọn fun Oloye Adebisi Edioseri ni oye nigba naa, awọn naa ni John Ojomo, agbẹjọro to pada di Olowo tilu Owo nigba naa; ẹnikeji ni Jide Fagboyegun toun naa jẹ agba oniṣowo niluu Owo, ati Fagbenro, ẹni to fẹ ọkan lara awọn ọmọ Ọba Lipede.

Awọn wọnyi ni wọn fun un ni orukọ 'Cash Woman'. Ile ifowopamọ ni wọn ti maa n pade, to si maa n ya wọn lẹnu nigbakugba to ba ti gbe owo wa si banki. Yara kan ni wọn maa n fun un lati fi ka owo rẹ.

Kasẹẹti orin ti Baba Lẹgba kọkọ ṣe fun un, lo ti pe e ni 'Adebisi Cash Woman'. Igba to ya ni Ebenezer Obey ṣe orin tiẹ, to si pe e ni 'Cash Madam', orukọ to mọ ọn lori titi di asiko yii.