Pásítọ̀ Adeboye sọ̀rọ̀ lórí àwọn tó fi AI sọ́ọ́ di Alhaji lórí ayélujára Ó ní ọ̀pọ̀ àwọn olùpẹ̀gàn kò ní la ọdún 2025 já

Aworan Pasito Adeboye

Oríṣun àwòrán, x/@PastorEAAdeboye

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Oluṣọaguntan agba fun ijọ The Redeemed Christian Church of God, RCCG, Pasitọ Enoch Adeboye ti fesi si awọn kan to gbe aworan atọwọda imọẹrọ AI eyi to ṣe afihan agba iranṣẹ Ọlọrun naa gẹgẹ bi arinrinajo Hajj lọdun to kọja.

Pasitọ Adeboye ṣalaye lasiko to n ba awọn ọmọ ìjọ naa sọrọ nibi eto isin oloṣooṣu Holy Ghost service to waye laẹ ọjọ Ẹti mọjumọ ọjọ Abamẹta pe eyi tubọ tọka si asọtẹlẹ ti Ọlọrun fi han oun nipa ọdun 2025 ni pe ọpọlọpọ awọn olupẹgan ni yoo dide.

"O da mi loju pe ọpọlọpọ yin lo ri lori ayelujara bi awọn eeyan kan ṣe lo imọẹrọ AI lati gbe aworan kan to fi mi han gẹgẹ bi Alhaji jade."

Pasitọ Adeboye sọ pe ohun ti Ọlọrun sọ fun oun ni pe awọn olupẹgan yoo tubọ pọ sii lọdun 2025 ṣugbọn pupọ wọn ni ko ni la ọdun 2025 ja.

Amọṣa Adeboye ni bi o tilẹ jẹ wi pe ko dun mọ Ọlọrun ki ẹlẹsẹ ku bikoṣe ko ronupiwada, awọn eeyan naa ko le mu ọdun 2025 jẹ nitori pe "wọn ko fẹ yipada."

Nigba wo ni Aworan AI to ṣafihan Adeboye gẹgẹ bi Alhaji gbode?

Pasito Adeboye ninu aworan imoero AI to gbori ayelujara kan.

Oríṣun àwòrán, others

Ni oṣu kejila ọdun 2024 ni aworan kan gbode kan lori ayelujara.

Iwadii fihan pe eeyan kan ti orukọ rẹ n jẹ @Sarkideyforyou loju opo ayelujara X, iyẹn Twitter tẹlẹ lo gbe aworan yii jade eyi to ṣe afihan Pasitọ Adeboye to duro ni Kaabah ni ilu Mecca.

Eeyan to din diẹ ni miliọnu mẹrin lo ti wo aworan naa, igba ẹẹdẹgbẹjọ ni wọn ti pin aworan naa ka, ti awọn bii ẹgbẹsan si ti sọ ọrọ kan tabi omiran labẹ rẹ.