Ọlọ́pàá ti mú Waris tó jí ewúrẹ́ fi ṣe ìkómọ ọmọ rẹ̀ l'Ogun

Oríṣun àwòrán, Getty image
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti fidi ẹ mulẹ, pe ọkunrin kan, Waris Akintoye, ti wa ni ahamọ bayii, lori ẹsun pe o ji obukọ ẹwurẹ lati fi ṣe ikomo ọmọ rẹ lagbegbe Ọdẹda.
CSP Omolola Odutola, Alukoro ọlọpaa Ogun lo kede iṣẹlẹ naa ninu atẹjade to fi sita lọjọ Satide, ọjọ kẹrin,oṣu Kin-in-ni ọdun 2025.
Odutọla ṣalaye pe Warris ati ẹnikeji rẹ, Ajayi Yusuf, ni wọn jọ ji ẹran obukọ ti owo rẹ to ẹgbẹrun lọna igba naira (200,000).
O ni wọn wọnu oko ibilẹ kan ti wọn ti n sin ewurẹ lọpọlọpọ, iyẹn lọjọ ọdun Keresimesi to kọja yii.
Ẹni to n sin awọn ẹran naa torukọ rẹ n jẹ Mark, ti ṣiṣẹ oko lọ lasiko ti awọn afurasi yii debẹ bi Odutọla ṣe wi.
Nigba ti Mark yoo fi pada de, Waris ati Ajayi ti gbe e lẹran lọ.
Báwo ni àṣírí ṣe tú?

Oríṣun àwòrán, Others
Gẹgẹ bi alaye ọlọpaa, lẹyin ti Mark bẹrẹ si i wa obukọ naa kaakiri adugbo ni awọn kan ta a lolobo nipa ewurẹ naa.
Wọn sọ fun elewurẹ pe Waris ati Ajayi lawọn ri ti wọn gbe ẹran kan gun ọkada, wọn si morile ọna Olodo, ti ko fi bẹẹ jinna si Ọdẹda.
Eyi ni awọn ọlọpaa ṣiṣẹ tọ, ti wọn fi lọọ mu Waris ati Ajayi lọjọ keji, oṣu Kin-in-ni ọdun 2025.
Nigba ti wọn n dahun ibeere awọn ọlọpaa, Odutọla sọ pe awọn afurasi mejeeji jẹwọ pe loootọ lawọn ji obukọ ẹran naa gbe.
O ni wọn ṣalaye bi wọn ṣe ji i gbe ati bi wọn ṣe pa a fun ikomọ ọmọbinrin ti Waris bi.
Ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kejila ọdun 2024 ni ikomọ ọhun ti wọn ṣe ni Olodo waye bi wọn ṣe wi.
" Awọn afurasi mejeeji ti wa ni ahamọ, bẹẹ ni iwadii n lọ lori ọrọ wọn ni ẹka to n ri si iwa ọdaran."
Bẹẹ ni Odutola wi. O ni wọn yoo foju ba kootu lẹyin iwadii naa.












