Kí ni Ààrẹ Tinubu ń lọ ṣe ní Ghana pẹ̀lú ìrínàjò tó fẹ́ gùnlé lọ́jọ́ Ajé?

Aare Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Nigerian Presidential Palace.

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Oni ọjọ Aje, ọjọ kẹfa, oṣu Kin-in-ni ọdun 2025 ni Aarẹ Bola Tinubu yoo balẹ si orilẹede Ghana, fun iburawọle aarẹ tuntun, John Mhama ti wọn dibo yan.

Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ aarẹ fi sita ni wọn ti ṣalaye, pe ọjọ Keje, oṣu yii ni iburawọle aarẹ Ghana yoo waye.

Wọn fi kun un pe Tinubu n lọ sibi eto naa pẹlu ipe ti Aarẹ Mahama pe e, lẹyin ti olori ilẹ Ghana tuntun naa ṣabẹwo si i loṣu Kejila ọdun 2024.

''Ọrẹ ọdun gbọọrọ ni Tinubu ati Mahama, gẹgẹ bi Naijiria ati Ghana naa ṣe jẹ alajọṣe fun igba pipẹ wa''

Bẹẹ ni apa kan atẹjade naa ka.

Aarẹ Tinubu gẹgẹ bii olori ẹgbẹ ECOWAS, yoo darapọ mọ awọn olori ilẹ Africa yooku nibi ayẹyẹ iburawọle yii, bi atẹjade naa ṣe fidi ẹ mulẹ.

John Mahama ni aarẹ Ghana laaarin ọdun 2011 si 2017.

Tẹ o ba gabgbe, oṣu Kejila ọdun 2024 ni wọn tun dibo yan an pada lati waa di olori orilẹ ede Ghana lẹẹkan si i.