Yìnyín líle dá ìrìnàjò dúró ní UK, ìna ọba kú láwọn ibí kan

Oríṣun àwòrán, Reuters
O ti pe ọjọ mẹta bayii ti yinyin to lagbara ati ayipada oju ọjọ to n mu otutu gidi ti gbalẹ ni UK.
Koda, ina ọba ko si lawọn agbegbe kan mọ nigba ti ayipada oju ọjọ kọ lu opo agbara.
Iroyin sọ pe ko din ni ile mẹtalelọgọrun-un (113) ti wọn ko ni ina mọ lagbegbe Derby, aadoje (130) lagbegbe Postcode ti ko jinna si Super-Mare.
Ile mejilelọgọrin (82) ni ina wọn kú latari ayipada oju ọjọ yii ni Newport, mejidinlọgbọn (28) lo si faragba a ni Birmingham.
Bakan naa ni irinajo ko dẹrun fawọn to n wọ ọkọ ofurufu ati ọkọ oju irin lasiko yii rara.
Awọn papakọ ofurufu kan ni Manchester, Liverpool, John Lennon ati Birmingham, ti dawọ iṣẹ duro latari yinyin pupọ to bẹrẹ lati oru titi di asiko ti a n kọ iroyin yii.
Awọn agbegbe bii Glascarnoch, Scotland, Wales, Sussex, Surrey ati Kent n koju yinyin to n jabọ naa lọpọ yanturu.
Ẹka National Highways ni UK, sọ pe yinyin le maa jabọ si oju ọna ni odiwọn 25cm ni awọn apa ibi kan ni Ariwa England.
Bẹẹ ni otutu ọhun kari agbegbe gbogbo lorilẹede United Kingdom.

Oríṣun àwòrán, EPA


Oríṣun àwòrán, PA Media














