Kò ṣéé mà gbọ̀ọ́
Iyi nla lo jẹ fun Naijiria
Pe Pasitọ ati akọrin ẹmi nni, Nathanel Bassey, yoo ṣere nibi Iburawọle Aarẹ Donald Trump l'America logunjọ oṣu yii
Mo tiẹ gbọ pe Nathaniel nikan lọmọ Africa to wa ninu eto orin naa
Bo ṣe jẹ gan niyẹn
Ṣugbọn ta a ni Nathaniel Bassey yii gan-an?
Kan si BBC. COM/ YORUBA.
>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>>
Ero to n re Ghana, ẹ ba mi ki Aarẹ Tinubu o
Oni ọjọ Aje ni Tinubu n gbera lọ si Ghana, gẹgẹ bi ileeṣẹ aarẹ Naijiria ṣe fi sita
Aarẹ Tinubu n lọ fun eto ibura aarẹ tuntun lorilẹede Ghana, John Mahama.
Ti yoo waye lọjọ Iṣẹgun fun Mahama lati bọ sori aleefa lẹẹkeji.
Ẹkunrẹrẹ iroyin n bẹ loju opo wa
mmmmmmmmmmmmmmmmmmmmmmmmmmmmmmmmmmmmmmmmm
Hmmm, iku tun gbeṣe rẹ de
Ta a lo ku?
Gbajumọ alafẹ obinrin ati oniṣowo ilu Ẹgba, Abike Adebisi Edionsere tawọn eeyan mọ si Cash Madam ni o.
Ọjọ Aiku ana ni Cash Madam jade laye lẹni ọdun mọkandinlaadọrun
Ka itan igbesi aye Iya Suna tawọn olorin ki daadaa naa loju.


