Àlùfáà yínbọn pa ọmọdékùnrin tó yin báńgà lásìkò ayẹyẹ ọdún tuntun

Oríṣun àwòrán, Others
Alufaa ile ijọsin agunda kan, Fada Joseph Enyinnaya ni wọn ti fẹsun kan pe o sina bolẹ fun awọn ọdọmọkunrin kan nitori wọn yin banger ni agbegbe ile ijọsin.
Iṣẹlẹ yii ti gba ẹmi eeyan kan, ti eeyan mi si farapa, to si wa ni ile iwosan lọwọ nigba to n gba itọju.
Iṣẹlẹ naa waye ni aṣalẹ ayẹyẹ ọdun tuntun ni alẹ ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kejila ọdun 2024 ni agbegbe Amaimo, ni ijọba ibilẹ Ikeduru nipinlẹ Imo.
Ọpọ awuyewuye ni iṣẹlẹ yii ti fa lori ayelujara.
Iroyin to tẹ ileeṣẹ BBC lọwọ ni pe Fada Joseph Eniyinnaya, to jẹ alufaa ijọ St Columbas niluu Amaimo sina bolẹ fun ọmọdekunrin lasiko to yin banger ni agbegbe ile ijọsin naa.
Iṣẹlẹ yii lo ya ọpọ awọn olugbe ilu naa lẹnu, to si ba wọn lojiji.
Awọn eeyan to ba BBC sọrọ ni awọn gbọ nipa iṣẹlẹ lasiko ti wọn n mura lati lọ ile ijọsin fun idupẹ ọdun tuntun ni alẹ ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kejila ọdun 2024.
Yatọ si ọmọ to padanu ẹmi rẹ, eeyan mi tun farapa lasiko ikọlu naa, to si wa ni ile iwosan nibi to ti n gba itọju lọwọ.
Baba oloogbe, Arakunrin Godwin ba BBC sọrọ, "Mo wa ni ile nigba ti mo gbọ iroyin pe wọn ti yinbọn fun ọmọ mi.
"Iyawo mi lo suure lọ si ileeṣẹ ọlọpaa lati lọ fi iṣẹlẹ naa to wọn leti."

Oríṣun àwòrán, Others
Ki ni ileeṣẹ ọlọpaa sọ?
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Imo ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, ti wọn si jẹ ko di mimọ mimọ pe iwadi ti bẹrẹ ni lori iṣẹlẹ naa.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Imo, Henry Okoye lo saọ eyi di mimọ.
"A ti bẹrẹ iwadii lati ṣawari ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ yii.
"A o ma fi to yin leti bi iwadii wa se n lọ."















