Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Ọdun ti ẹnikẹni ko ni gbagbe ni 2025 yoo jẹ
Ẹhn, ki lo ri o?
Asọtẹlẹ ti alufaa agba ijọ Redeemed, pasitọ Adebye ma sọ fọdun yii ma niyẹn
Oludasilẹ ijọ Living Faith Church, Winners Chapel, Biṣọọbu David Oyedepo naa sọ pe ọdun tawọn eeyan yoo gbe nnkan ọtun ṣe laye ni.
Awọn asọtẹlẹ yii ma dara gan o, ṣe awọn meji pere to sọ asọtẹlẹ niyẹn ni
Rara o, wọn pọ ju bẹẹ lọ, oju opo bbc.com/yoruba ni wa a ti ri ẹkunrẹrẹ
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ní orilẹ̀ èdè America, FBI ní iwadii ti bẹrẹ ni pẹrẹu lori afurasí tó sekúpa èèyàn mẹ́ẹ̀dógún ní New Orleans lọjọ́ ọdún tuntun
FBI ni igbagbọ wa pe ọmọkunrin naa kò dá iṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ̀ jẹ́, pe o dabi lọwọ kan igbeṣumọmi ninu
Ọjọ ọdun ni Shamsud-Din Jabbar to figba kan jẹ oṣiṣẹ ologun Amẹrika wa ọkọ wọ aarin ero nibi ti wọn ti n ṣayẹyẹ odun to si ṣina ibọn bolẹ fun wọn
Ọpọ eeyan lo farapa yatọ sawọn mẹẹdogun to jade laye
