Ìjàmbá ọkọ̀ gbẹ̀mí èèyàn 71 tó ń bọ̀ láti ibi ayẹyẹ ìgbéyàwó

Oríṣun àwòrán, Sidama Regional Health Bureau
Kò dín ní èèyàn mọ́kànléláàádọ́rin tó pàdánù ẹ̀mí wọn ní ẹkùn gúúsù Ethiopia lẹ́yìn tí ọkọ̀ ńlá kan jábọ́ sínú odò.
Ọkọ̀ ńlá náà, gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ ìròyìn Reuters ṣe sọ, jábọ́ sínú odò lẹ́yìn tó tàsé afárá kan lásìkò tó ń rin ìrìnàjò gba ìpínlẹ̀ Sidama.
Wosenyeleh Simion, tó jẹ́ adarí ẹ̀ṣọ́ ojú pópó ní ẹkùn náà sọ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ ló jẹ́ àwọn tó ń bọ̀ láti ibi ayẹyẹ ìgbéyàwó kan.
Simion ṣàlàyé pé ìwadìí láti mọ ohun tó ṣokùnfà ìjàmbá náà ti bẹ̀rẹ̀ àmọ́ tó ní ọkọ̀ ọ̀hún kó ju èrò tó yẹ lọ, tó sì lè jẹ́ òun ló fa ìjàmbá náà.
Ìwádìí ní àwọn ọkùnrin méjìdínláàádọ́rin ni wọ́n ti jáde láyé, táwọn mẹ́ta sì jẹ́ obìnrin.
Àwòrán tí kò hàn dáadáa tí iléeṣẹ́ ètò ìlera fi sórí ayélujára ṣàfihàn báwọn èèyàn kan ṣé ń gbìyànjú láti yọ ọkọ̀ kúrò nínú odò lẹ́kun Bona.
Àwọn àwòrán míì ṣàfihàn àwọn òkú tí wọ́n tẹ́ sí ilẹ̀.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ló máa ń pàdánù ẹ̀mí wọn sọ́wọ́ ìjàmbá ọkọ̀ lọ́dọọdún ní Ethiopia látàrí eré àsápajúdé àti àìbọ̀wọ̀ fún òfin ètò ìrìnnà















