Èèyàn 15 kú, ọ̀pọ̀ farapa nínú ìkọlù tí Shamsud-Din Jabbar ṣe lọ́jọ́ ọdún tuntun l'America

Oríṣun àwòrán, FBI
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ní orilẹ̀ èdè America, FBI ní afurasí tó sekúpa èèyàn mẹ́ẹ̀dógún ní New Orleans ní ọjọ́ ọdún tuntun kò dá iṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ̀ jẹ́.
Shamsud-Din Jabbar, ẹni ọdún méjìlélógójì tó jẹ́ ọmọ America ló wa ọkọ̀ wọ àárín èrò ní òpópónà kan ní New Orleans, níbi tí ti bọ́ sílẹ̀ nínú ọkọ̀ náà, tó sì ṣíná ìbọn bolẹ̀.
Àwọn ọlọ́pàá ṣekúpa òun náà níbi ìkọlù tó ṣe sawọn èèyàn ọ̀hún.
FBI ní àwọn bá àsíá tó jẹ́ ti ikọ̀ agbéṣùmọ̀mí Islamic State nínú ọkọ̀ rẹ̀ àti àwọn àdó olóró méjì lágbègbè náà.
Òṣìṣẹ́ FBI kan, Alethea Duncan sọ pé àwọn kò gbàgbọ́ pé Jabbar dá iṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ̀ jẹ́ àti pé ojú ìwà ìgbéṣùmọ̀mí ni àwọn fi ń wo ìkọlù náà, tí àwọn sì ń ṣe ìwádìí rẹ̀ bíi ìgbéṣùmọ̀mí.
Ààrẹ America, Joe Biden ni àwọn olùwádìí ń ṣe ìwadìí boyá ìkọlù náà ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ìbúgbàmù ọkọ̀ tó wáyé níwájú ilé ìtura tí ààrẹ tí wan ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn ní orílẹ̀ èdè náà wà.
Biden ní ìkọlù náà bánilọ́kàn jẹ́, tó sì jẹ́jẹ̀ẹ́ àtìlẹyìn tó péye lorí ìkọlù ọ̀hún.

Ọ̀kan lára àwọn olùwádìí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, Dókítà Dwight McKenna sọ ní ìrọ̀lẹ́ Ọjọ́rú pé, àwọn tó ti bá ìkọlù náà ti wọ mẹ́ẹ̀ẹ̀dógún báyìí.
Ó ní ó máa gba àwọn ní ọjọ́ díẹ̀ láti fi ṣe àyẹ̀wò gbogbo àwọn òkú tó bá ìsẹ̀lẹ̀ náà lọ, pé lẹ́yìn náà ni àwọn yóò fi orúkọ wọn léde.
Lára àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn nínu ìkọlù ọ̀hún ni agbábọ́ọ̀lù tẹ́lẹ̀ rí fún Princeton University, Martin "Tiger" Bech gẹ́gẹ́ bí ilé-ẹ̀kọ́ naà ṣe sọ.
Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn míì ló tún farapa nínú ìkọlù náà.
Ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ọlọ́pàá New Orleans, Anne Kirkpatrick sọ pé Jabbar gbìyànjú láti fi ọkọ̀ rẹ̀ pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn níbi ìkọlù náà.
Wọ́n bá ìbọn gbọ̀ọ̀rọ̀ níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà, tí ìgbàgbọ́ sì wà pé ó yá ọkọ̀ tó lò láti fi ṣe ìkọlù yìí lórí áàpù kan ni.
Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn níbi tí wọ́n ti ń ṣayẹyẹ ọdún tuntun ní New Orleans French Quarter náà ṣàlàyé ohun tí ojú wọ́n rí.
Whit Davis sọ fún BBC pé ìkọlù náà bá àwọn lójijì, tí oníkálukú àwọn sì sáré àsálà fún ẹ̀mí àwọn.
Ta ni Shamsud-Din Jabbar?
Texas ni wọ́n bí Jabbar sí, tó sì ti fìgbà kan rí ṣiṣẹ́ pẹ̀lú iléeṣẹ́ ológun Amẹ́ríkà.
Gẹ́gẹ́ bí nǹkan tó wà lórí ìkànnì LinkedIn rẹ̀ èyí tí wọ́n ti parẹ́ báyìí, Jabbar ṣiṣẹ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ka ní iléeṣẹ́ ológun America, kó tó di pé ó kúrò nínú iṣẹ́ ológun.
America ran an lọ sí Afghanistan láàárín ọdún 2009 sí 2010.
Láàárín ọdún 2015 sí 2017 ló kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ Kọ̀mpútà ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga George State University.
Bákan náà ló ti ṣiṣẹ́ rí ní ẹ̀ka tó ń ri sí ọ̀rọ̀ ilé kíkọ àmọ́ tí ọjọ́ ti lọ lórí ìwé àṣẹ rẹ̀ tó ń lò láti ọdún 2021.
Ó ti ní àkọ́ọ́lẹ̀ ìwà ọ̀daràn rí èyí tó jẹ́ olè jíjà àti ṣíṣẹ̀ sófin ọkọ̀ wíwà.















