Ìdí tí ìjọba Naijiria fi kìlọ̀ pé kí aráàlú má lọ sí orílèèdè Australia rèé

Aworan baalu Australia

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ajọ to n ri si ọrọ nipa oke okun lorilẹede Naijiria ti gba awọn araalu to n gbero lati lọ si orilẹede Australia ni imọran pe ki wọn dawọ duro nitori eto aabo to mẹhẹ ni awọn apa ibi kan ni ilu naa.

Ninu atẹjade ti ẹka ijọba to n risi oke okun fi lede, wọn ni ọpọ awọn arin irinajo ati awọn olugbe ti wọn wa ni Austrilia ni wọn koju ọpọ abuku ẹlẹyamẹya ati ija ẹṣin lasiko yii.

"Iṣẹlẹ to waye ni aipẹ yii lo da lori ija ẹṣin, ti ọpọ si n na ika abuku si awọn ẹlẹsin Jew ati Islam

"Iwa ni alekun ti ba, ti a si ni lati pe akiyesi awọn ọmọ Naijiria."

Ẹka ijọba to n risi ọrọ oke okun ni otitọ ni pe Orilẹede Australia jẹ orilẹede kan ti wọn ni ọpọ ẹya ṣugbọn iṣẹlẹ nipa ija ẹṣin ti waye ni awọn apa ibi kan.

"Ninu oṣu kejila ọdun 2024, wọn dana sun ọkọ ayọkẹlẹ kan, ti wọn si fa rogbodiyan.

"A n rọ awọn Naijiria lati se pẹlẹ, ki wọn si se ọrọ yii ni oju ni alankan fi n sọri.

"Bakan naa ni a n rọ awọn ọmọ Naijiria to wa ni bẹ, ti wọn ba koju eyikeyi ikọlu, ki wọn suure fi to ọfisi High Commission Naijiria leti ."

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post