Àwọn dókítà bẹ́rẹ́ ìyanṣẹ́lódì ọlọ́jọ́ gbọọrọ ní Ondo

Aworan awọn Dokita

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ẹgbẹ awọn dokita nipinlẹ Ondo, ẹka ile iwosan Medical Sciences Teaching kede sita pe awọn ti bẹrẹ iyanṣẹlodi ọlọjọ gbọọrọ lori ihuwasi ijọba ipinlẹ naa si awọn dokita.

Ni Ọjọ Ajẹ, ọgbọnjọ, oṣu Kejila ọdun 2024, ẹgbẹ awọn dokita naa se iwọde, ti wọn si kede gbogbo ohun to n dun wọn lọkan.

Aarẹ ẹgbẹ naa, Dokita Olaogbe Kehinde ni iṣẹ pọ lọrun ọpọ awọn dokita, to si jẹ pe owo kekere ni ijọba n san.

O ni eyi ti fa ki ọpọ dokita kọwe fipo silẹ.

"Ọpọ awọn dokita ti kuro ni ile iwosan lai dagbere nitori bi wọn se n se si wa.

"Pẹlu bi a ṣe ti pariwo pe ki wọn se atunṣe si igbaye gbadun awọn dokita, awọn alakoso kọ lati tẹti si igbe wa,"

O mu ẹnu ba ibeere ẹgbẹ dokita, eyi to n pe fun atunṣe owo oṣu ati sisan owo oṣu tuntun fun awọn oṣiṣẹ.

"A n tọrọ aforijin fun ohun ti iyanṣẹlodi yii le fa si awọn alaisan ati gbogbo ilu ṣugbọn wọn ti ti wa sun ogiri"

Nigba ti oun naa sọrọ, Aarẹ tẹlẹ fun ẹgbẹ oṣiṣẹ nipinlẹ Ondo, Dokita John Matthew ni bi ijọba se n se awọn dokita ni ko ba ojumu, to si jẹ idi kan gboogi ti ọpọ awọn dokita fi n kọwe fi iṣẹ silẹ.

"Awọn dokita n kuro nipinlẹ Ondo nitori wọn ko san owo oṣu gidi bi ti awọn ipinlẹ yooku bi Ogun. Wọn n yọ owo wa ni ọna ti ko bojumu, owo ori na pọ ju agbara lọ.

"A ko ni pada si ẹnu iṣẹ ti ijọba ko ba se n ohun ti a fẹ.Ni asiko kan ko si ina mọnamọna ni ile iwosan naa, a ni lati sisẹ ninu okunkun.'

Dokita agba fun UNIMEDTH , Dokita Gbala Micheal pe fun suuru, to si fi da awọn dokita naa loju pe awọn olori ile iwosan naa yoo wa ojutu si iṣoro wọn.