Ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́ṣì, ẹni ọdún méjìdínlógún tó bá ọmọdé lò pọ̀ ní Dubai bẹ̀rẹ̀ ẹ̀wọ̀n rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Detained in Dubai
Marcus Fakana, ọmọkunrin ẹni ọdun mejidinlogun kan ti i ṣe ọmọ ilẹ Gẹẹsi (Britain), ti bẹrẹ ẹwọn tile ẹjọ paṣẹ fun un bayii.
Ẹwọn ọdun kan ni kootu paṣẹ pe ko lọọ ṣe lori ẹsun pe o ba ọmọde lo pọ.
Ọmọbinrin ti ọjọ ori rẹ ko ju mẹtadinlogun lọ ni Marcus ba lo pọ lasiko to lọ fun isinmi ni Dubai, loṣu Kẹsan-an ọdun yii.
Iroyin sọ pe ọmọ ilẹ Britain ni ọmọdebinrin naa pẹlu, oun ati awọn obi rẹ naa lọ fun isinmi ni Dubai ni .
Ilu Tottenham, North London ni Marcus ti wa, ọgba ẹwọn AI, ni Dubai lo si balẹ si lati jiya ẹṣẹ naa.
Báwo ni àṣírí ṣe tú?
Lẹyin ti ajọṣepọ ikọkọ bẹrẹ laaarin Marcus Fakana ati ọmọbinrin naa, wọn ya fọto wọn si tun n fi atẹjiṣẹ ifẹ ranṣẹ sira wọn.
Wọnyi ni iya ọmọbinrin naa ri to si fi ọrọ naa to awọn agbofinro leti.
Gẹgẹ bi ofin ilẹ Dubai, iwa ọdaran ni lati ba ọmọbinrin ti ko ti i pe ọdun mejidinlogun ni ajọṣẹpọ.
Lẹyin ifisun iya ọmọbinrin ọhun ni awọn ọlọpaa lọọ mu Marcus ni otẹẹli to ti n gbafẹ.
Ṣaaju ni wọn ti kọkọ gba beeli rẹ loṣu Kẹsan-an naa, niluu Dubai.
Ẹgbẹ kan to fikalẹ si UK, fidi ẹ mulẹ pe funra Fakana lo fa ara rẹ kalẹ lati ṣe ẹwọn lọgba ẹwọn AI.
Àwọn ẹgbẹ̀ kan ń bá a bẹ̀bẹ̀ fún ìdáríjì
Ẹgbẹ alaanu kan to n ṣe atilẹyin fun ẹbi Fakana, ti bẹrẹ iyanju lati ri i pe ijọba UK dide si ọrọ yii.
Ohun ti wọn n beere fun ni aforiji, tabi ki wọn ba ọmọkunrin naa din idajọ ẹwọn ọdun kan naa ku.
Agbẹnusọ kan lati Downing sọ pe: " Olootu ijọba paapaa mọ pe adanwo nla gbaa ni ohun to ṣẹlẹ si ẹbi Fakana."
Ṣaaju ni wọn ti ṣalaye, pe ọlude ni awọn ọmọde meji naa lọọ ṣe ni Dubai pẹlu awọn obi wọn.
Wọn ni UK ti wọn ti wa, faaye gba ọmọ ọdun mẹrindinlogun (16) lati ni ajọṣepọ.
Eyi lo fa a ti wọn fi ṣe ohun ti wọn ṣe.
Bakan naa ni ẹgbẹ yii sọ pe Marcus ti sọrọ ọmọbinrin to pade naa fun awọn obi rẹ, ọmọbinrin naa ni ko sọ nile, to fi di wahala nigba ti iya rẹ pada mọ.
Ofin ilẹ Dubai ko faaye gba iru ibalopọ yii, ọmọde ni wọn ka ọmọ ti Marcus ba lo pọ si, bo tilẹ jẹ pe wọn bọwọ fun etọ ọmọniyan labẹ ofin.














