'Gwo-Gwo-Gwo, Go warm eba' àti àwọn àṣà míì tó milẹ̀ lọ́dún 2024

Oríṣun àwòrán, Taooma/Facebook/Brain Jotter/Facebook/Farooq Oreagba/Instagram
Ọdun 2024 jẹ ọdun kan t'awọn ọmọ Naijiria da awọn aṣa kan eyi to di ohun tawọn eeyan n sọ nipa rẹ kaakiri lawujọ ati lori ayelujara.
Diẹ ninu awọn aṣa yii da lori nnkan bii ounjẹ jijẹ, omiran ninu wọn da lori orin tawọn olorin kan gbe jade lọdun 2024.
Ati ọmọde ati agba lo ti n da awọn aṣa yii lati ìbẹrẹ ọdun 2024 to n kogba wọle lọ yii to fi di akoko yii.
Wọnyii ni awọn aṣa mẹfa to gbaju gbaja lọdun 2024:
Gwo Gwo Gwo
Gwo Gwo Gwo jẹ ọkan lara awọn aṣa to rinlẹ lorilẹede Naijiria lọdun 2024.
Ninu orin akọrin ẹya Igbo kan eyi t'awọn eeyan nifẹẹ si ni aṣa Gwo Gwo Gwo ti jade.
Baba agbalagba lo ti kọ orin yii tipẹ.
Amọ, adẹrinpoṣonu Brain Jotter ni o lo orin naa ninu sikiiti rẹ kan to gbe jade.
Bayii ni awọn eeyan ṣe tẹwọgba orin naa ti o si di aṣa.
Ẹsẹ ijo ni Gwo Gwo Gwo yii tumọ si ninu orin ọhun to di aṣa fáwọn eeyan.
'Steeze'
Aṣa mii to tun gbode lọdun 2024 ni eyi ti wọn n pe ni 'steeze.'
Aṣa 'steeze' tumọ si imura ati irinisi eeyan lawujọ.
Adẹrinpoṣonu Taooma wa lara awọn to jẹ ki aṣa naa di itẹwọgba lọdọ awọn araalu.
Aṣa yii tun gbode lasiko ajọdun Ojude Oba niluu Ijebu-Ode.
Ọkunrin kan to wo asọ oke ti o si gun ẹṣin nibi ajodun naa jẹ ki ọpọ maa daṣa naa pẹlu imura ọkunrin naa.
'I'm a chosen'
Aṣa I'm a chosen naa wa lara awọn aṣa to rinlẹ lọdun 2024.
Aṣa 'I'm a chosen' jẹyọ lati ijọ Ọlọrun kan ti wọn n pe orúkọ rẹ ni 'The Lord's Chosen Church'.
Lati ẹnu ọpọ awọn ọmọ ijọ yii l'awọn eeyan ti kọ aṣa 'I'm a chosen' ti wọn si bẹrẹ si ni gba a bi ẹni n gba igba ọtí.
'I'm a chosen' túmọ si 'temi yatọ, ti nnkan ba n ṣẹlẹ si gbogbo eeyan, ko le ṣẹlẹ semi,' ati bẹẹ bẹẹ lọ.
'E don cast'
'E don cast' tun ni aṣa miran tawọn eeyan tun gba tiẹ lọdun 2024.
Aṣa yii jade ninu orin ti olorin takasufe n ni, Burna Boy, gbe jade eyi to pe akọle rẹ ni 'Last Last.
Ìtumọ aṣa yii ni pe ọwọ ti bọ sori tabi asiri ti tu.
Awọn eeyan tun maa n lo aṣa yii lati ṣapejuwe bi ilu ṣe ri.
'Stop playing'
Aṣa 'dey play' ni a maa n gbọ tẹlẹ, amọ, 'stop playing' ni aṣa tuntun to tun gbode lọdun 2024.
Aṣa 'stop playing' tumọ si pe ko saye fun awada tabi ere.
Ohun ti ẹni to ba da aṣa yii n sọ ni pe ko saye ere ṣíṣe.
'Go warm eba'
'Go warm eba' tun ni aṣa mii tawọn eeyan lo daadaa lọdun 2024.
Aṣa yii jẹ kan t'awọn fi maa n ṣe awada tabi ṣere.
Ti enikan ba da iru aṣa yii si ẹlòmíràn, ohun to tumọ si ni pe ki ẹni naa lọ semẹdọ tabi ko fara balẹ.
Aṣa yii tun tumọ si pe ki onikaluku gbaju mọ ọrọ ara rẹ.















