Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko gbé ìgbésẹ̀ ọ̀tun lórí ìdájọ́ tó tú Dokita Olaleye sílẹ̀ l'ẹ́wọ̀n gbére

Femi Olaleye

Oríṣun àwòrán, Dr Femi/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ijọba ipinlẹ Eko ti morile ile-ẹjọ to ga julọ ni Naijiria, lati da idajọ ile-ẹjọ kotẹmilọrun, to da dokita Femi Olaleye silẹ ninu ẹsun fifi ipa ba ibatan iyawo rẹ lopọ.

Ninu oṣu Kẹwaa, ọdun 2023 ni ile ẹjọ to n gbọ ẹsun ifipanilopọ, ju Dokita Olaleye si ẹwọn gberte lori ẹsun meji to nii ṣe pẹlu fifi ipa ba ọmọde lopọ.

Ṣugbọn nigba ti yoo fi di ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun 2024, ile-ẹjọ Kotẹmilọrun , ẹka ti ipinlẹ Eko, da Olaleye silẹ, pẹlu awijare pe awọn aṣisẹ kan wa ninu idajọ akọkọ.

Ile-ẹjọ Kotẹmilọrun ṣalaye pe awọn ẹri ti agbẹjọro to rojọ tako olujẹjọ ni "abawọn", ti ko si ṣe e ''gbẹkẹle''.

Lẹyin idajọ naa ni Dokita Olaleye kuro ni ọgba ẹwọn to wa lati bii ọdun kan.

Eyi si lo fa a ti awọn ajọ ajafẹtọ kan, fi kọ iwe si ijọba ipinlẹ Eko lati tako idajọ naa ni ile-ẹjọ to ga julọ ni Naijiria.

Igbesẹ yii ni ijọba ipinlẹ Eko gbe lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kejila.

Bawo ni awọn idajọ akọkọ ṣe lọ?

Inu oṣu kẹwaa, ọdun 2023 ni Onidajọ Rahman Oshodi ti ile ẹjọ to n gbọ ẹsun ifipabanilopọ nipinlẹ Eko ju Olaleye sẹwọn gbere, lori ẹsun wi pe o ba ọmọdebinrin, ọmọ ọdun mẹrindinlogun laṣepọ.

Ile-ẹjọ naa sọ pe awọn iwa ti Olaleye n hu lasiko ti wọn n gbọ ẹjọ rẹ lọwọ, ati pe ko ṣebi ẹni ti ọrọ naa ka lara, lo fa a ti wọn fi da ẹjọ ẹwọn gbere fun un.

Lẹyin idajọ naa ni Olaleye to jẹ alakoso agba ni ile iwosan oju ti ipinlẹ Eko, iyẹn Optimal Cancer Care Foundation pe ẹjọ kotẹmilọrun, to si jẹ ko di mimọ pe oun ko mọ nnkankan nipa ẹsun ti wọn fi kan oun.

Ẹri to wa lati ọdọ iyawo ati ọmọ ti wọn lo fipa ba laṣepọ ko papọ - Ile-ẹjọ

Ile-ẹjọ kotẹmilọrun sọ pe awọn ẹri ti ẹlẹri mẹfa to yọju sile ẹjọ lati tako Olaleye niwaju ile-ẹjọ ko papọ mọra wọn, bẹẹ si ni ko si ẹri kankan to fidi rẹ mulẹ wi pe lotitọ ni Olaleye fipa ba ọmọ ọhun laṣepọ.

Bakan naa ni ile-ẹjọ kotẹmilọrun tun bu ẹnu atẹ lu onidajọ to ju Olaleye sẹwọn gbere wi pe niṣe lo fi imọ-tara-ẹni ṣe idajọ naa, leyi to ni ko bojumu to.

Ile-ejọ fidi rẹ mulẹ pe iyawo Dokita Olaleye lo gba foonu ọkọ rẹ lati maa fi fi awọn ẹri kan ranṣẹ loriu imeeli, eyi ti wọn le lo lati fi tako ọkọ rẹ nile ẹjọ.

Gẹgẹ bi ile-ẹjọ ṣe ṣalaye, dokita naa ati iyawo rẹ ti wa nile ẹjọ tẹlẹ lati pinya, ati pe mimu obinrin naa wa sile ẹjọ lati wa duro gẹgẹ bi ẹlẹri ko ba ilana mu, nitori bo ṣe ni ifẹ si ẹjọ naa to tako ọkọ to fẹẹ kọ silẹ.

"Ko yẹ ki ile-ẹjọ kekere gba awọn ẹri ọmọ naa jẹ, nitori pe awọn ọrọ rẹ ko ba ara wọn mu."

Ile-ẹjọ kotẹmilọrun ni o ṣee ṣe ko jẹ pe nitori awọn ohun ti obinrin naa fẹẹ ri gba bii owo, dukia ati awọn ọmọ lo fa a, to fi duro lati tako ọkọ rẹ niwaju ile-ẹjọ.

"Niṣe lo yẹ ki wọn farabalẹ fun awọn ẹri obinrin naa, nitori pe o ni lati fura si," ile-ẹjọ ṣalaye.

Awọn ẹri fi han wi pe iyawo dokita naa lu ọmọdebinrin ọhun lalubami ni ọjọ meji ko to di pe wọn jẹri lati purọ mọ ọkunrin naa wi pe oun lo fipa ba a laṣepọ.

"Ohun ti mo ri sii ni pe ko yẹ ki ile-ẹjọ kekere naa gba awọn ẹri ọmọ naa jẹ, nitori pe awọn ọrọ rẹ ko ba ara wọn mu."

Ile-ẹjọ agba naa sọ pe aṣiṣẹ nla ni ile-ẹjọ kekere ọhun ṣe lati ran Dokita Olaleye lẹwọn nitori pe ẹri iyawo dokita ati ọmọkekere naa ko ba ara wọn mu.

Labẹ ofin, awọn ẹri ọmọ kekere gbọdọ ba ara wọn mu ko to di pe ile-ẹjọ lo o.

Bakan naa ni ile-ẹjọ tun sọ pe magomago wa laarin ẹjọ ti wọn gbe wa sile ẹjọ ati ohun ti iwe ayẹwo ọsibitu sọ.

Ọkọ mi ma ń fún mi lóògùn orun lálaalẹ́ kó tó fipá bá ọmọ tó ń gbé lọ́dọ̀ mi lòpọ̀

Lara awọn ẹri ti iyawo Dokita Olaleye, to ke gbajare sita lori ọrọ naa, jẹ nile ẹjọ ni pe alaalẹ ni ọkọ oun ma n fun oun ni oogun orun.

O ni ọtọ ni iṣẹ ti ọkọ oun ṣalaye pe awọn oogun mejeeji n ṣe, amọ ni kete ti oun ba ti sun, lo ma n yọ lọ si yaara ọmọdebinrin naa lati ba a ni ibalopọ.