Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa èèkàn ogun Kiriji tí wọ́n fẹ́ fi Gómìnà Adeleke jẹ

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Lọwọlọwọ yii, igbesẹ lati fi gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke, jẹ oye èèkan ogun Kiriji (Icon of Kiriji war) ti bẹrẹ.

Gẹgẹ bi Ọjọgbọn Oluwasayo Ajiboye, Aṣiwaju onigbagbọ ilu Imesi-Ile, nipinlẹ Osun, ṣe ṣalaye fun BBC, o ni ẹnu gbogbo ilu Imesi- Ile kaakiri lo ti ko si i.

Bakan naa lo ni titi kan awọn ọmọ ilu Ibadan ti ogun Kiriji tori wọn waye, gbogbo wọn ni wọn fọwọ si i pe Gomina Adeleke ni ipo naa tọ si.

''Ọwa oye Imesi-Ile, Ọba Enoch Ademola Akinyemi, Ọyọyọ keji ti faṣẹ si i, awọn ni wọn ni ka maa wi.''

Ọjọgbọn Ajiboye lo ṣalaye bẹẹ.

Gomina Ademola Adeleke.

Oríṣun àwòrán, Governor Ademola Adeleke/X

Kí lo dè ti wọn fi fẹẹ yan gomina bii àmì ogun Kírìjì?

Nigba to n ṣalaye idi ti wọn ṣe fẹẹ yan Gomina Adeleke sipo naa, Ọjọgbọn Ajiboye sọ pe "Ọmọ Balogun ni gomina, o si n ṣiṣẹ rẹ nipinlẹ Osun, o n wu wa lori. Ọlọrun ko ni i jẹ ka ri ogun itajẹsilẹ mọ nilẹẹ Yoruba, ogun alaafia, isọdọkan, iṣerere, ko dara fun ẹru, ko dara f'ọmọ, ki gbogbo ilẹ Yoruba ṣe rere, iru ogun bẹẹ la fẹ ki ọmọ Balogun waa ja.

''Idi niyẹn ta a fi n pe e lati ba wa pe gbogbo ilẹ Yoruba papọ, ki asia alaafia jọ maa fẹ lọwọ wa.

''Ogun ti tan, ogun ìfẹ́ lo ku ta n ja. Awọn ilu Ibadan, Ede, Oke-Imesi, Ẹgba, ijẹbu to fi de ipinlẹ Edo, gbogbo wọn lọrọ yii kan lati darapọ mọ wa.

''Nigba ti ogun Kiriji ti pari, ayajọ ifẹ rẹ la n ṣe lọdọọdun ta a ba kora jọ. Ipinlẹ Osun si ni ogun naa ti pari patapata, eyi la ṣe fẹnuko lati tubọ gbe iṣẹ naa fun Gomina Adeleke, gẹgẹ bii àmì, ogbontarigi ati eekan ogun Kiriji, ti yoo so gbogbo wa pọ.''

Nígbà wo ni ìwúyè yóò wáyé?

Ọjọgbọn Ajiboye ṣalaye pe Gomina Adeleke funra rẹ ti mọ nipa igbesẹ yii.

O ni bi eto gbogbo ba ti pari, ti awọn agbaagba si fẹnuko, nigba naa ni wọn yoo kede bi iwuye yoo ṣe lọ.

Díẹ̀ nípa ogun Kírìjì

Aworan awọn akọni atijọ.

Oríṣun àwòrán, OLD NAIJA

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Tẹ o ba gbagbe, Ogun Kiriji ti ọpọ tun mọ si ogun Ekiti parapọ, jẹ ogun to waye laarin ilu Ibadan ati Ekiti pẹlu Ijesha.

Gẹgẹ bí Latosa ṣe ṣalaye, ogun Kiriji lo kẹyin gbogbo ogun nilẹ Yoruba, ati pe ogun naa lo pẹ julọ ninu gbogbo ogun to ṣẹlẹ nilẹ Yoruba

Ogun Kiriji bẹ silẹ nitori awọn ofin ati ilana didari awọn eeyan ti Ibadan gbe kalẹ nitori ipa to ko ninu ogun ilu Osogbo lọdun 1840 ati iṣẹgun rẹ ninu ogun Ijaye.

Iṣẹgun yii lo pokiki Ibadan gẹgẹ bí ilu akin ti yoo rọpo ijọba apaṣẹ-waa Oyo Ile to wo lulẹ.

Ibadan ti fi idi ijọba rẹ mulẹ kaakiri ilẹ Yoruba to fi de Ekiti ati Ijesha nigba anaa, ṣugbọn Ekiti ati Ijesha tako igbesẹ yii nitori wọn ko ri Ibadan gẹgẹ bi ilu alagbara ilẹ Yoruba.

Ohun to ṣe okunfa ogun Kiriji gan-an ni bi awọn aṣoju ilu Ibadan ṣe n huwa ọdaran lawọn ilu.

Itan sọ pe niṣe ni wọn n dunkoko mọ awọn ọdọ, koda wọn tun n fi ipa bawọn obinrin lo pọ.

Eleyi lo mu ki awọn eeyan Ekiti ati Ijesha ṣekupa ọpọ ninu wọn, ti ti wọn si doju ija kọ Ibadan.

Bayii lawọn ilu mi nilẹ Yoruba naa da si ogun ọhún.

1877 ni ogun Kiriji bẹrẹ, o si pari si 1893, niluu Imesi-ile, ipinlẹ Osun.