Èyi ni àwọn ìjínigbé méje tó milẹ̀ tìtì lọ́dún 2024

Oríṣun àwòrán, @Adamu_Asiya_X
Ijinigbe ki i ṣe nnkan ajoji lorilẹede Naijiria mọ, ọkan lara awọn iṣoro eto aabo to n koju orilẹede yii fun igba pipẹ ni.
Laipẹ yii ni ajọ to n ṣe akọsilẹ onka, Nigerian Bureau of Statistics (NBS), fi onka iye awọn eeyan ti wọn ji gbe ni Naijiria ni 2024 sita, wọn ni o le ni miliọnu meji eeyan ti wọn ji gbe ni 2024 nikan.
Apa Ariwa-Iwọ-Oorun Naijiria (North-West) ni wọn ni ijinigbe ọhun pọ si ju, eeyan to le ni miliọnu kan ni NBS sọ pe wọn ji gbe nibẹ nikan.
Eyi to tẹle e ni Guusu-Ila-Oorun (South-East), nibi ti wọn ti ji eeyan to le ni 110,000 gbe lọ.
Meje ninu awọn iṣẹlẹ ijinigbe to gbalẹ kan ni 2024 ni BBC ṣe agbekalẹ rẹ yii, bi ọdun naa ṣe n lọ sopin.
Akẹ́kọ̀ọ́ 280 láti ilé-ẹ̀kọ́ Kuriga, Kaduna
Ni ọjọ keje, oṣu Kẹta 2024 ni iroyin gbode, pe awọn ajinigbe yabo ileewe kan niluu Kuriga, nijọba ibile Chikun, ipinlẹ Kaduna, wọn si ji akẹkọọ 280 lọ, iyẹn ọọdunrun-din -ni ogun.
Nigba ti awọn alaṣẹ kede ijinigbe naa, wọn ni awọn ti ri 137 gba pada ninu awọn ọmọ naa.
Olukọ kan to wa ninu awọn ti wọn ji gbe naa ku si akata awọn ajinigbe yii, awọn akẹkọọ yooku si lo ọjọ mẹtadinlogun ni ahamọ, ki wọn too fi wọn silẹ, nigba ti ọjọ ti awọn ajingbe da fun wọn lati sanwo itusilẹ wọn ku ọjọ diẹ ko pe.
Bi wọn ṣe ji awọn akẹkọọ yii gbe tun mu ọpọ eeyan ranti awọn ọmọbinrin akẹkọọbinrin Chibok, nipinlẹ Borno ti Boko Haram ko wọgbo lọ ni 2014.
Emir ilu Gobir:
Ọkan lara awọn ijinigbe to gba omije loju ẹni ni 2024 ti Emir ilu Gobir, nipinlẹ Katsina, iyẹn Emir Gatawa isa Bawa.
Ọjọ kẹta ti wọn ji ọba naa gbe ni awọn ajinigbe fi fidio kan sita, nibi ti Kabiyesi naa ti n bẹbẹ, pe ki wọn tete ba oun san owo itusilẹ fun wọn, ki wọn le yọnda oun.
Ṣugbọn nigba ti Emir Gatawa yoo fi lo ọjọ marundinlọgbọn ni akata awọn ajinigbe yii, iroyin iku rẹ ni a gbọ.
Iku ọba si akata ajinigbe si tun fi han pe iṣoro ai si aabo n koju Naijiria gan-an.
Wọ́n jí ìyá olórin Rarara gbé:
Loṣu Kẹfa, awọn agbebọn ji iya gbajugbaja olorin ilẹ Hausa kan, Dauda Kahutu Rarara, gbe.
Iya naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Hajiya Hauwa'u Adamu, ni wọn ji gbe nipinlẹ Katsina. Iya agba naa lo ọsẹ mẹta lahamọ ki wọn too tu u silẹ.

Oríṣun àwòrán, Dauda Kahutu/IG
Wọ́n jí ọmọ ìyá kan náà mẹ́fà gbé àti bàbá wọn.

Oríṣun àwòrán, @Adamu_Asiya_X
Ọjọ keji ti 2024 bẹrẹ ni awọn ajinigbe ṣabẹwo si awọn mọlébi kan, ni Bwari, niluu Abuja.
Wọn ji ọmọbinrin kan, Nabeelah ati awọn aburo rẹ mẹrin pẹlu baba wọn gbe lọ.
Iroyin sọ pe wọn pada fi baba silẹ, wọn ni ko lọọ wa owo itusilẹ awọn ọmọbinrin rẹ wa.
Ṣugbọn awọn agbebọn to ji wọn gbe yinbọn pa Nabeela, ki owo itanran too de ọdọ wọn.
Nnkan bii ọsẹ meji lẹyin igba naa ni awọn ẹṣọ alaabo kede pe awọn ti gba awọn ọmọ yooku kuro lakata awọn to ji wọn gbe.
Wọ́n jí ìyàwó àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́tàléláàdọ́ta (53) gbé ní Katsina:
Loṣu keji ọdun 2024, awọn agbebọn kọlu awọn eeyan to n bọ lati ode iyawo, wọn si ji mẹtalelaadọta gbe lọ lara awọn ọrẹ iyawo, ati iyawo funra rẹ naa.
Awọn ọlọpaa ṣalaye pe ibọn ni wọn da bole fun awọn eeyan naa, nijọba ibilẹ Sabuwa, ipinlẹ Katsina.
Ọsẹ keji ti wọn ji wọn gbe ni awọn ajinigbe naa fi fidio kan sita, ti wọn wọ aṣọ ṣọja, ti wọn si gbe ibọn dani,
Ninu fidio naa ni awọn obinrin to wọ hijaabu wa, awọn meji ninu wọn gbe ọmọ lọwọ.
Iyawo paapaa ti wọ aṣọ ologun, bẹẹ ni wọn gbe ibọn kọ ọ lọrun.
Ṣugbọn ijọba ipinlẹ Katsina koro oju si fidio naa, wọn ni awọn ọta lo fi ṣe ibajẹ awọn, ko le baa da bii pe awọn ko ṣiṣẹ to.
Aawọn ṣoja pada ri awọn ti wọn ji gbe naa gba pada, wọn si fa wọn le ijọba ipinlẹ Katsina lọwọ.
Wọ́n jí àádọta èèyàn gbé ní Maradun, Zamfara
Oru ni awọn agbebọn ya wọlu, wọn si ṣina ibọn bolẹ nibẹrẹ oṣu Kejila, wọn gbe eeyan ti ko din ni adọta wọgbo lọ.
Gẹgẹ bawọn araalu Maradun, nipinlẹ Zamfara ṣe ṣalaye fun BBC nigba naa, wọn ni o to eeyan marundinlọgọta ti wọn gbe wọgbo lọ.
Awọn ọmọde ati awọn obinrin ni wọn pọju ti wọn gbe lọ bi wọn ṣe sọ.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ìṣègùn òyìnbó:
Ninu oṣu Kẹjọ, iroyin gbode pe wọn ti ji ogun (20) akẹkọọ to n kọsẹ iṣegun oyinbo gbe nipinlẹ Benue, lasiko ti wọn n lọ sibi eto kan.
Lẹyin ti wọn lo ọjọ diẹ lakata awọn ajinigbe, wọn ri ominira gba lati ọwọ ikọ ẹṣọ alabo kan.












