Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun ti rí ọmọ ọdún méje tí wọ́n jí gbé l'Ota nílùú Ayetoro

Oríṣun àwòrán, Others
Lẹyin ariwo to gbode, pe wọn ji ọmọ ọdun meje kan gbe niluu Ado-Odo Ota, ipinlẹ Ogun, ileeṣẹ ọlọpaa Ogun ti kede pe awọn ti ri ọmọ naa gba pada.
Gẹgẹ bi alaye SP Omolola Odutola, Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun, o ni ọjọ Aje, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kejila ọdun 2024 ni wọn ji ọmọ naa gbe.
Odutọla sọ pe Ọjọbọ ọsẹ naa ni awọn ajinigbe ọhun bẹrẹ si i beere owo lọwọ iya ọmọ naa.
Lẹyin igbiyanju ati iṣẹ ọtẹlẹmuyẹ, Odutọla fidi ẹ mulẹ ninu atẹjade to fi sita lọjọ Aiku, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kejila 2024, pe awọn ti ri ọmọde naa ni Ayetoro, ipinlẹ Ogun kan naa.
Báwo ni wọ́n ṣe rí ọmọ náà padà?

Oríṣun àwòrán, @SP Omolola Odutola Facebook
Gẹgẹ bi atẹjade ọlọpaa Ogun ṣe wi, ikọ to n ri si ijinigbe lo bẹrẹ igbesẹ to yọri si riri ọmọde naa gba pada.
'' Nipasẹ bi Kọmiṣanna ọlọpaa Ogun, CP Lanre Ogunlowo (PhD) ṣe ja iṣẹ naa kunra, ọmọdebinrin to sọnu ti di riri ni Ayetoro.
''Gbogbo awọn afurasi ti wọn lọwọ nibẹ ni ọwọ ọlọpaa ti ba,
CP Lanre Ogunlowo yoo ṣalaye lẹkun-un rẹrẹ nipa rẹ nibi ipade oniroyin ti yoo waye lọla''
Bẹẹ ni Omolola Odutola wi.
Ṣugbọn ipade oniroyin naa to yẹ ko waye lọjọ Aje, ọgbọnjọ, oṣu Kejila ko pada waye mọ.
Awọn ọlọpaa sun un siwaju di igba mi-in ni.
Kí ló ti ṣẹlẹ̀ ṣíwájú?
Ṣaaju ni iroyin kan ti kọkọ sọ pe olokoowo POS ni iya ọmọ ti wọn ji gbe yii, ati pe onibaara iya rẹ to sun ọn daadaa lo ji ọmọ ọhun gbe.
Iroyin ori ayelujara naa sọ pe ọkunrin to ji ọmọ gbe yii ti maa n gba owo lọwọ iya ọmọ naa tipẹ.
O maa n ra kaadi ipe pẹlu, bẹẹ lo maa n fun ọmọdebinrin naa lowo.
Lọjọ kẹtalelogun, oṣu Kejila ọdun 2024 yii lo tun wa bi iroyin naa ṣe wi, o ra ounjẹ funra rẹ ati fun ọmọbinrin ọhun.
Leyin eyi lo ni ki ọmọ lọọ ra omi inu ọra wa, o si tun lọọ pade rẹ lọna ko too mu omi naa de.
Nipasẹ bẹẹ ni wọn ni o fi gbe ọmọ sa lọ.
Tẹ o ba gbagbe, iṣẹlẹ yii kan naa ni Alukoro ọlọpaa Naijiria, Muyiwa Adejọbi, tori ẹ sọ pe awọn ti mu awọn ọlọpaa to beere owo ki wọn too le gbe igbesẹ lorii wiwa ọmọde naa.
Ẹgbẹrun lọna ogoji naira la gbọ pe awọn ọlọpaa beere lati fi ṣi faili ẹsun naa.
Bakan naa ni wọn tun ni iya ọmọ yoo san ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira ti wọn yoo fi wa nọmba ẹni to ji ọmo rẹ lọ.
Ṣugbọn Alukoro ọlọpaa Ogun sọ pe eyi ko ri bẹẹ.
Odutọla sọ pe ọlọpaa to fẹẹ bẹrẹ iṣẹ lori ẹjọ naa ni ko lo ilana iṣẹ ọlọpaa.
O ni ko fi iṣẹlẹ naa to DPO ibẹ leti lẹsẹkẹsẹ ni.
Ati pe ki araalu ma ṣe gba iroyin naa gbọ rara.














