Àwọn gbankọgbì àsọtẹ́lẹ̀ táwọn pásítọ̀ sọ nípa ọdún 2025

Oríṣun àwòrán, Oyedepo, Eze, Olukoya ati Adeboye
Ni ibẹrẹ ọdun tuntun, onikaluku lo ma n wa ọna lati gbadura , tabi wure pe ki ọdun tuntun dun, ko si dara fun wọn, tabi ṣe alakalẹ afojusun awọn nnkan ti wọn fẹ ko sẹlẹ si wọn.
Eyi ko yọ awọn ọmọlẹyin Kristi silẹ, paapaa ni ilẹ Africa, pẹlu bi wọn ṣe ma n fojusọna fun awọn asọtẹlẹ nipa dun tuntun lati ẹnu awọn olori ẹsin ati pasitọ wọn.
Awọn asọtẹlẹ yii lo ma n jade ni aṣalẹ ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kejila, lasiko ti iṣọ-oru irekọja si ọjọ kini ọdun tuntun ba n waye.
Bo tilẹ jẹ pe awọn alaṣẹ ti kilọ pe pẹlẹ-pẹlẹ ni ki awọn ojiṣẹ Ọlọrun maa fi sọ awọn asọtẹlẹ naa, sibẹ wọn ko dawọ duro.
Awọn asọtẹlẹ nipa ọdun 2025 ti jade, paapaa lati ẹnu awọn ilumọọka ojiṣẹ Ọlọrun. Diẹ lara wọn la ṣe akojọpọ rẹ ninu iroyin yii:
Pasitọ Enoch Adeboye

Oríṣun àwòrán, Others
Alufa Agba ijọ Redeemed Christian Church of God, RCCG, sọ ni olu ijọ naa to wa ni ipinlẹ Ogun lasiko isin opin ọdun pe, ọdun ti yoo ni apẹrẹ ni dun 2025 jẹ, eyi ti ẹnikẹni ko ni i gbagbe.
O ni ọjọ Ẹti ni oun yoo to sọ awọn asọtẹlẹ nipa awujọ agbaye, ati pe oun yoo ṣọra ṣe nipa sisọ asọtẹlẹ nipa Naijiria. "Ninu awọn asọtẹlẹ fun agbaye ni Naijiria yoo ti mu tiẹ."
Biṣọọbu David Oyedepo

Oríṣun àwòrán, Living Faith Church
Oludasilẹ ile ijọsin Living Faith Church, ti ọpọ tun mọ si Winners Chapel, Biṣọọbu David Oyedepo, naa sọ asọtẹlẹ fun awọn ọmọ ijọ rẹ ni orumọju ọdun tuntun.
Nile ijọsin rẹ to wa ni Ota, nipinlẹ Ogun, ni Oyedepo ti sọ pe ọdun "ibẹrẹ ọtun, ati ọdun ti awọn eeyan yoo ṣe amuka nnkan ọtun laye wọn", ni ọdun 2025 jẹ.
O ni ko si wooli kankan to ni agbara lati mu ki nnkan ti Ọlọrun sọ, ko wa si imuṣẹ. "Igbagbọ onikaluku ni yoo sọ boya yoo ṣẹ tabi bẹẹ kọ."
Pasitọ Daniel Olukoya

Oríṣun àwòrán, MFM
Pasitọ Daniel Olukoya, oludasilẹ ati alamojuto agba fun ijọ Mountain of Fire and Miracle, sọ lasiko iṣọ-oru irekọja sinu ọdun tuntun pe, ọdun iṣẹgun ti ko ṣe e gbe pamọ ni 2025 yoo jẹ.
"Ọdun idasi, imupadabọsipo, itusilẹ ti ko ni onka, ati igbedide awọn adari ti yoo mu ayipada wa, ni ọdun 2025.
"Ọdun ti ailegbadura lewu pupọ ni, to si tun jẹ ọdun ti a nilo adura lati fi koju iji ọrọ aje ati wahala l'agbo oṣelu.
"Lọdun yii, a nilo adura lati gbogun ti awọn iṣẹlẹ bii omiyale ati awọn ajalu loriṣiriṣi, to fi mọ awọn aisan tuntun."
Jerry Eze

Oríṣun àwòrán, Jerry Eze
Pasitọ agba fun ileeṣẹ iranṣẹ Streams of Joy, Jerry Eze, sọ tẹlẹ sinu aye awọn ọmọ ijọ rẹ pe, gbogbo oun to n pa wọn lẹkun ni yoo di ajọyọ lọdun 2025.
"Ọdun iyanu ojoojumọ, ati eyi ti awọn eeyan naa yoo gba imisi, igbega lawujọ agbaye, ni ọdun tuntun yoo jẹ."
Pasitọ W.F Kumuyi

Oríṣun àwòrán, W.F Kumuyi
Alamojuto Agba fun ijọ Deeper Christian Life Ministry, Pasitọ William Kumuyi, naa sọ asọtẹlẹ nipa ọdun tuntun fun awọn ọmọ ijọ rẹ.
O ni, "ọdun aluyọ, ọdun to kun fun ire ni ọdun 2025 jẹ, ninu eyi ti ọta ko nii le sọ bi irinajo aye rẹ yoo ṣe ri."












