Kí ni pàtàkì iṣán níbi ọdún Ọmọ Olówu?

Lonii, ọjọ Karundinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2025 ni aṣekagba ayẹyẹ Ọdun Ọmọ Olowu niluu Abẹokuta, nipinlẹ Ogun n waye lẹyin ọsẹ kan tie to ayẹyẹ naa ti gberasọ.
Ọpọ awọn eeyan ni wọn ti n darapọ pẹlu awọn ọmọ bibi ilu Owu naa, lati ṣe ayẹyẹ ọdun naa.
Agbegbe ti wọn n pe ni Ori Omi to wa ni Ṣokori ni eto ayẹyẹ ọhun ti n waye.
Lara awọn eeyan pataki ti wọn ti peju sibi ayẹyẹ naa ni aṣoju ilẹ Naijiria silẹ Gẹẹsi lasiko iṣejọba ana, Sarafa Tunji Ishola ati awọn mii.
Ọdun Ọmọ Olowu jẹ ọkan pataki ninu awọn ọdun iṣẹmbaye ni ilu Owu to maa n waye lọdọọdun laaarin awọn ọmọ bibi ilu naa, nibi ti Oloye Olusegun Obasanjo to ti figba kan ri jẹ aarẹ Naijiria ti wa.
Wọn n lo ayẹyẹ yii lati ṣafihan aṣa, iṣẹṣe ati ipolongo ede Yoruba laaarin awọn ọmọ ilu Owu Abeokuta jakejado agbaye.


Gẹgẹ bo ṣe wa loju opo itakun ayelujara Owu Kingdom, idi ti wọn ṣe da ọdun Omo Olowu silẹ ni lati maa dupe fun Olodumare fun pipese ohun tawọn eeyan ilu naa nilo fun odidi ọdun kan.
Gbogbo awọn ọmọ bibi ilu Owu kaakiri agbaye lo maa n ko ara wọn jọ ni ọdọọdun lati ṣe ayẹyẹ naa.
Lara awọn ohun elo ti wọn fi maa n ṣayẹyẹ ọdun yii ni ẹla iṣu, ere oko ati iṣan.
Níbi ayẹyẹ ọdun yii ni wọn ti maa n fun Olowu ti ilu Owu ni iṣan ni ọdọọdun lati maa fi ka iye ọdun ti ọba naa lo lori ipo.
Gbogbo iṣan ti Olowu ba n gba ni ọdọọdun lo maa n fi si kọrọ kan ninu aafin, eyi si ni wọn maa ka lẹyin ti Olowu naa ba jade laye lati fi mọ iye ọdun to lo lori ipo.
Ti Olowu kan ba jẹ lonii, ti wọn si ṣe ọdun Omo Olowu ni ọjọ keji, to si gba iṣan nibi ayẹyẹ naa, o tumọ si pe Olowu naa ti lo ọdun kan lori ipo.
Bakan naa lo tun jẹ ọna lati fi wure fun Olowu pe yoo pẹ lori itẹ awọn babanla rẹ.

















