Awuyewuye bí ètò ìdìbò sípò ààrẹ Ivory Coast ṣe gbérasọ

Lónìí, ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹwàá, ọdún 2025 ni àwọn èèyàn orílẹ̀ èdè Ivory Coast yóò máa yan ààrẹ tuntun.
Ààrẹ Alassane Ouattara, ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́rin ń díje fún sáà kẹrin.
Ó máa kojú àwọn olùdíje mẹ́rin míì tó fi mọ́ aya ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí, Simone Gbagbo, mínísítà tẹ́lẹ̀ rí kan, Henriette Adjoua àti oníṣòwò Jean-Louis Billon.
Ètò ìdìbò náà bẹ̀rẹ̀ sí ní fa awuyewuye lẹ́yìn tí àjọ elétò ìdìbò yọwọ́ àwọn èèkàn ìlú méjì – Ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí, Laurent Gbagbo àti olùdásílẹ̀ iléeṣé Suisse, Tidjane Thiam kúrò lára àwọn tó le díje dupò ààrẹ náà.
Bí wọ́n ṣe yọwọ́ Tidjane Thiam, tó jẹ́ olórí ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò tó pọ̀ jùlọ, kúrò àwọn tó lè dupò ààrẹ fẹ́sùn pé ó ń lo orílẹ̀ èdè méjì àti ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí, Laurent Gbagbo fẹ́sùn pé wọ́n ti da lẹ́jọ́ lórí ìwà ọ̀daràn kan rí, ló ti ń fa ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn ṣáájú ètò ìdìbò.
Àwọn olùwọ́de tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ni àwọn aláṣẹ nawọ́ gán, tí wọ́n sì fi àwọn àádọ́ta sí àhámọ́.
Thiam jùwe ètò ìdìbò náà bíi ètò ìwúyè fún ààrẹ Alassane Ouattara.
Òun àti Gbagbo kò buwọ́lu olùdíje míì ṣùgbọ́n tí wọ́n káwọn èèyàn má kópa níbi ètò ìdìbò náà.
Àwọn aláṣẹ ní àwọn èèyàn kò gbọdọ̀ ṣe ìwọ́de, tí wọ́n sì da àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò tó lé ní 40,000 sí ìgboro láti lè ri pé ètò ìdìbò náà lọ ní ìrọwọ́ rọsẹ̀.
Ìwà jàgídíjàgan máa ń wáyé lásìkò ètò ìdìbò ní Ivory Coast.
Níṣe ni ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ní Ivory Coast ń fojú sọ́nà fún iṣẹ́ àti ìgbáyégbádùn tó dára, wọ́n ń fẹ́ àyípadà àmọ́ won kò ní àǹfàní láti dìbò fún olùdíje púpọ̀.
Ní oṣù Kẹrin ni ilé ẹjọ́ dájọ́ pé Tidjane Thiam kò lè díje dupò ààrẹ orílẹ̀ èdè náà fẹ́sùn pé ó ti kéde pé òun kò jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Ivory Coast mọ́ lọ́dún 1987, tó sì gba ìwé ọmọ onílùú ilẹ̀ France.
Fún Laurent Gbagbo ni tirẹ̀, wọ́n ní kò lè díje nítorí pé wọ́n ti dájọ́ fún lọ́dún 2018 lórí ìwà ọ̀daràn kan.
Lọ́dún 2010, èèyàn tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ló pàdánù ẹ̀mí wọn níbi wàhálà tó bẹ́ sílẹ̀ ní Ivory Coast nígbà ti Gbagbo kọ̀ láti gbà pé òun pàdánù ibò sọ́wọ́ ààrẹ Ouattara.
Ṣùgbọ́n Ouattara, táwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ń pè ní "Ado" ṣì ní àwọn alátakò tó lágbára bíi ìyàwó Gbagbo tẹ́lẹ̀ rí àti ọ̀kan lára olówó orílẹ̀ èdè náà. Síbẹ̀, ẹnu àwọn alátakò kò kò, tí wọ́n sì pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ.
Ní báyìí, àwọn olùdíje mẹ́rin gbòógì ni Ouattara ń kojú báyìí:
- Simone Gbagbo, ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́rin tó jẹ́ aya tẹ́lẹ̀ rí fún Laurent Gbagbo
- Jean-Louis Billon, ẹni ọgọ́ta ọdún, tó jẹ́ mínísítà tẹ́lẹ̀ rí, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó lówó jùlọ ní orílẹ̀ èdè náà.
- Henriette Lagou Adjoua, ẹni ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rin, tó jẹ́ mínísítà tẹ́lẹ̀ rí, tó sì tún gbajúmọ̀ fún jíjà fún ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin.
- Ahoua Don Mello, ẹni ọdún mẹ́tàdínláàádọ́rin, tó jẹ́ mínísítà tẹ́lẹ̀ rí àti abẹ́ṣinkáwọ́ Gbagbo.
Ouattara rí àtìlẹyìn láti ẹkùn àríwá, ní àwọn ẹkùn tí wọ́n ti ń sọ èdè Dioula, tó sì ní òun máa ṣe ìfilọlẹ̀ ìpolongo ìbò òun ní ẹkùn ìwọ̀ oòrùn tó ti máa ń rí ìbò tẹ́lẹ̀.
Simone Gbagbo ń rí àtìlẹyìn láti ìwọ̀ oòrùn àti gúúsù ìwọ̀ oòrùn tó jẹ́ ibi tí ọkọ rẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí ti máa ń rí àtìlẹyìn.
Àwọn tó wà láwọn ìlú ńlá ni Billon ń retí ìbò láti ọ̀dọ̀ wọn àti ẹkùn ààrin gbùngùn, tó sì jẹ́jẹ̀ẹ́ láti mú àyípadà ńlá bá orílẹ̀ èdè náà.
Salifou Sanogo, ẹni ọdún mọ́kàndínlógún sọ pé òun ń ṣojú àwọn ọ̀dọ́ àti pé ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí òun máa kópa níbi ètò ìbò dídì.
Ó ní Ouattara ti dàgbà àti pé kò máa ṣe ohunkóhun fún àwọn, tí orílẹ̀ èdè náà sì nílò àyípadà.















