Olubadan Ladoja kọminú lórí iléeṣẹ́ tó ń kógbáwọlé nílùú Ibadan, wo àwọn àwọn èèkàn tó gbé kalẹ̀ láti ṣàtúnṣe ọrọ̀ ajé rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Palace Media/@OloyeSomorin
Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Rashidi Adewolu Ladoja, ti ṣe ifilọlẹ igbimo olokowo kan ti yoo ṣe itaniji ọrọ-aje ilu Ibadan.
Ni aafin rẹ to wa ni Oke Aremo ni ifilọlẹ naa ti waye l'Ọjọbọ ọjọ kẹtalelogun oṣu Kẹwaa yii niluu Ibadan.
Iyalaje Iyalode to ti jẹ minisita fun igba meji ri ni Naijiria, Oloye Onikepo Akande ati olori awọn oṣiṣẹ ni Naijiria tẹlẹ ri, Ọjọgbọn Dapo Afolabi, ni Ọba Ladoja yan gẹgẹ bii alaga igbimọ naa.
Awọn mii ti wọn jẹ ọmo igbimọ naa ni Ọga agba ile ifowopamọ First Bank tẹlẹ, Oloye Adelodun Olaiya, Ọmọwe Kazeem Adedutan, Bada Olubadan, Oloye Dotun Sanusi ati Agbaoye Kola Karim.
Awọn ọmọ igbimọ mii tun ni Aregbe Omo Balogun, Oloye Taofeek Adegboyega Adegoke ati Oloye Tajudeen Aremu to jẹ olori awọn oṣiṣẹ nipinlẹ Oyo tẹlẹ ri.
Oloye Aremu ni Ọba Ladoja yan gẹgẹ bi akọwe igbimọ naa.
Awọn ọmọ igbimọ mii ni aarẹ ajọ LCCI to n ri si kata-kara ati okowo nipinlẹ Eko tẹlẹ, Alhaji Remi Bello, Agbaakin Atayese ilẹ Ibadan, Oloye Yomi Idowu, Oloye Owolabi Oladejo ati alaga igbimọ alaṣẹ ajọ awọn ogbontarigi akọṣẹmọṣẹ oṣiṣẹ ile ifowopamọ, CIBN, tẹlẹ, Ọmọwe Bayo Olugbemi.
''Nnkan tawọn eeyan n beere ni pe nibo ni ileeṣẹ Leyland atawọn ileeṣẹ mii wa?''
Nigba to n ṣe ifilọlẹ naa, Ọba Ladoja ni awọn ọmọ Ibadan fẹ ki ogo to ti wa nilẹ Ibadan nigba kan ri ti ọrọ-aje ilu naa fẹsẹ mulẹ daadaa pada.
Ladoja ni ''nnkan ti awọn eeyan n beere ni pe nibo ni ileeṣẹ Leyland wa?
Nibo nile iṣẹ Exide Battery wa?
Ileeṣẹ Wire and Cable, Isoglass, ati Ferodo n kọ?
Lati igba tawọn afọbajẹ ti buwọlu iyansipo mi loṣu Keje to kọja ni a ti n gbiyanju lati ṣewadii ohun to mu kawọn ileeṣẹ yii kogba sile niluu Ibadan.
Ba wo ni a ṣe le dawọn pada ti ọpọ ọdọ yoo fi ri iṣẹ ṣe nibẹ?''
Olubadan ni gbogbo awọn ọmọ igbimọ toun yan ni wọn jẹ adari ileeṣẹ nla nla ati gbajugbaja oniṣowo pẹlu iriri ti yoo ṣe iranwọ fun ilu Ibadan.
Akọwe igbimọ naa, Oloye Aremu, to sọrọ lorukọ gbogo ọmọ igbimọ ṣeleri lati fi tọkan tọkan ṣiṣẹ ti kabiyesi gbe le wọn lọwọ.
Oloye Aremu ni igbimọ naa ko ni ja Olubadan atawọn ọmọ ilu Ibadan kulẹ.















