Ẹ ṣọ́ra o, ọtí ṣòro láti mu ní Nàìjíríà àtàwọn orílẹ̀èdè kan báyìí o,kẹ́míkà methanol ní wọ́n ń pò pọ̀ - UK ṣèkìlọ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ijọba UK to n ri si ọrọ ilẹ okeere ti fi Naijiria atawọn orilẹede meje mii sara awọn orilẹede to kilọ pe awọn eeyan ti n da kẹmika methanol pọ mọ ọti ti wọn n ta fun araalu.
Ecuador, Japan, Kenya, Mexico, Peru, Russia ati Uganda lawọn orilẹede meje mii ọhun.
Naijiria atawọn orilẹede meje yii ni ileeṣẹ ijọba UK to n ri sọrọ ilẹ okeere kilọ fawọn ọmọ Ilẹ Gẹẹsi to ba n rinrin ajo lọ silẹ okeere lati ṣọra tori iru ọti bayii.
Orilẹede Thailand, Cambodia, Indonesia, Turkey, Costa Rica, Laos, Vietam ati Fiji ni ileeṣẹ ijọba naa ti kọkọ ṣe ikilọ fawọn ọmọ UK le lori tẹlẹ.
Ikilọ yii ko ṣẹyin awọn iṣẹlẹ kan to ṣẹlẹ sawọn arinrinajo afẹ mẹfa kan ti wọn ku lọdun to kọja lorilẹede Laos.
Ileeṣẹ ijọba UK naa gbawọn ararinajo to n lọ silu okeere lati UK wi pe ki wọn ṣakiyesi awọn apẹẹrẹ ti ẹni to ba ti mu ọti ti wọn da kẹmika majele methanol pọ mọ bii ki oju eeyan maa ṣu tabi ki ọkan eeyan daru.
Awọn apẹẹrẹ mii ni pe iru ẹni to ba mu ọti yii le ṣaisan tabi ki o ku gan an.
Ki ni methanol, ba wo lo ṣe n ṣakoba fun ara?

Oríṣun àwòrán, Stringer / AFP via Getty Images
Ileeṣẹ to n ri si ọrọ ilẹ okeere ko sọ ẹkunrẹrẹ nnkan to ṣẹlẹ lawọn orilẹede mẹjọ naa to ni ṣe pẹlu kẹmika methanol.
Amọ, Morgan to ririnajo lọ si Japan laipẹ yii, ṣalaye pe iriri oun lawọn ile ọti nibẹ fi han pe ọpọ arinrinajo ni ko mọ ewu to wa ninu mimu ọti ti wọn da kẹmika methanol pọ mọ.
''Wọn maa n saba sọ pe 'wa a mu ọti diẹ pẹlu mi lọfẹẹ - tequila wa, vodka naa wa.
Iwọ naa maa gba si wọn lẹnu ni, o si lewu gan an.
Ọpọ awọn arinrinajo afẹ lo n mu ọti yii lai mọ ibi ti igo rẹ ti wa,'' Morgan lo sọ bẹẹ.
Loṣu to kọja ni awọn ẹbi awọn ọmọ ilẹ Gẹeṣi to ku atawọn to ti ṣeṣe latari ọti ti wọn da kẹmika methanol pọ mọ ti wọn mu nilẹ okeere ṣe ipade pọ pẹlu awọn aṣofin Ilẹ Gẹẹsi atawọn alẹnulọrọ lẹka ileeṣẹ to n ri si lilọ soke sodo.
Calum Macdonald lara iru awọn eeyan bẹẹ lẹyin to ṣaisan nitori kẹmika methanol ti wọn da mọ ọti to mu ni Laos eyi to jẹ ko padanu iriran rẹ.
Ọmọ ọdun mẹtalelogun naa lati Sunbury-on-Thames sọ pe ''o ṣe pataki fawọn eeyan lati mọ ewu to wa nibẹ.
Ka ni pe mo ti mọ nipa ewu to wa ninu mimu ọti ti wọn da kẹmika methanol pọ mọ tẹlẹ ni, n ko ba ti di ẹni ti ko riran bayii lonii.''
Ọgbẹni Hamish Flaconer to jẹ minisita ọrọ ilẹ okeere ṣalaye pe ''kẹmika methanol le pa eeyan.
O ṣoro lati mọ ọti ti wọn ba da kẹmika methanol pọ mọ, awọn apẹẹrẹ ti eeyan kọkọ maa n ri fara jọ ki ọti maa pa eeyan.
Ọwọ ti maa n bọ sori kawọn arinrinajo to mọ pe nnkan ti wọn n mu lewu fun agọ ara wọn.''















