Ìdí tí mo fi bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò ọdún 22 láti tú Quran sí èdè Yorùbá – Daud Awwal

Àkọlé fídíò, Ìdí tí mo fi bẹ̀rẹ̀ ìrìàjò ọdún 22 láti tú Quran sí èdè Yorùbá – Daud Awwal
Ìdí tí mo fi bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò ọdún 22 láti tú Quran sí èdè Yorùbá – Daud Awwal

Ọmọwe Daud Awwal jẹ ọmọwe ọmọ orilẹede Naijiria to ṣẹṣẹ pari titu Kurani si ede Yoruba.

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, Ọmọwe Awwal ṣalaye pe ọdun mejilelogun lo gba oun lati tu Kurani si ede Yoruba nitori oun fẹ ko jẹ ẹkunrẹrẹ ti yoo mu ede Yoruba di atẹwọgba lagbaye, paapaajulọ lawujọ awọn onimọ nipa ẹsin.

O ṣalaye siwaju sii pe igbesẹ naa jẹ ipenija fun oun lati di awọn alafo to wa laarin aṣa, ede ati igbagbọ ẹda.

Aworan ogbifọ alafọwọkọ ti ọmọwe Awwal kọ sinu awọn iwe.

O ni lootọ oun mọ pe oun kọ ni ẹni akọkọ ti yoo tu kurani si ede Yoruba, ṣugbọn awọn kudiẹkudiẹ kan ti oun ri ninu awọn ti iṣaaju loun gbiyanju lati wa nnkan ṣe si ninu eyi, paapaa julọ ni ibamu pẹlu itẹsiwaju imọ ẹrọ ati sayẹnsi lode oni.