Kí ni ìdí tí Sultan Sokoto ṣe ń pè fún fífọwọ́ tó le mú àṣìlò ojú òpó ayélujára ní Nàìjíríà?

Aworan Sultan Sokoto ati Emir Borno

Oríṣun àwòrán, Channels Tv

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Sultan ti ilu Sokoto, Muhammad Sa'ad Abubakar ti rọ ijọba apapọ orilẹede Naijiria pe ki wọn gbe ofin kalẹ ti yoo ma mojuto ikanni ayelujara; pẹlu bi iroyin ẹlẹjẹ se n lọ kaakiri eyi to ni o jẹ ipenija nla fun alaafia ati iṣokan orilẹede Naijira.

Nigba to n sọrọ nibi ipade igbimọ awọn lọbalọba apa ariwa orilẹede Naijiria to waye ni Birnin Kebbi, Sultan Abubakar kọninu lori bi ayederu iroyin ṣe n lọ kaakiri orilẹede ayelujara, ti ọpọ awọn ọmọ Naijiria si ni lati tẹwọgba.

"Asiko ti to fun ijọba lati gbe ofin ti yoo ma mojuto ikanni ayelujara lorilẹede wa. Bi iroyin ayederu se n kan kaakiri ni a nilo lati mojuto," o ṣe kilọ.

"Mo koroju si awọn ọrọ kungbakungbe ti wọn sọ si awọn ileeṣẹ ologun nitori awọn ifasẹyin. Wọn n sa agbara wọn lati ri pe alaafia wa kaakiri orilẹede Naijiria," o sọ.

"Awọn ọrọ kungbakugbe ko ṣe iranlọwọ kankan, o n ko irẹwẹsi ọkan ba awọn to n fi aye wọn silẹ fun aabo wa."

Ninu ọrọ ikinikaabọ rẹ, igbakeji alaga igbimọ lọbalọba Ariwa ati Emir Borno, Abubakar Ibn Umar Garbai Elkanemi lo da wiwa ojutu si iṣoro eto aabo orilẹede Naijiria.

AWORAN

Oríṣun àwòrán, Channels TV

O tẹnumọ pe awọn lọbalọba ni iṣẹ lati ṣe lori eto aabo lorilẹede Naijiria.

O ni awọn lọbalọba ni afara to wa laaarin ijọba ati awọn eeyan ẹsẹkuku.

Awọn to wa nibi ipade naa ni Gomina Nasir Idris ti ipinlẹ Kebbi, minisita fun eto isuna ati igbasoke eto ọrọ aje, the Etsu Nupe, ati awọn lọbalọba kaakiri awọn apa ariwa orilẹede Naijiria.

Bẹẹ ba gbegbe, Ileeṣẹ ologun orilẹede Naijiria sọ pe irọ nla to jina si oootọ ni iroyin kan to sọ pe awọn ologun gbiyanju lati gba ijọba Aarẹ Bola Tinubu.

Iroyin ọhun lo ni ileeṣẹ ologun Naijiria wọgile eto yiyan bi ologun nibi ayẹyẹ ayajọ ominira ọdun karundinlaadọrin orilẹede Naijiria nitori awọn ọmogun kan to gbiyanju lati doju ijọba Tinubu bolẹ.

Iroyin naa tun sọ pe awọn ọmogun mẹrindinlogun ti ileeṣẹ ologun Naijiria ju si ahamọ ti wọn si n sọ tẹnu wọn lọwọ lọwọ ni ṣe pẹlu igbiyanju lati gbajọba alagbada to wa lode.